US Woman Marries Pink Colour: Obìrin kan ti ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú àwọ̀ "Pink" ní Las Vegas

Kitten Kay Sera

Oríṣun àwòrán, kittenkaysera

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Arabinrin kan ti o jẹ ọmọ California, Kitten Kay Sera, ti ṣe igbeyawo pẹlu awọ pinki, iyẹn pupa fẹẹrẹfẹ, ni Ilu Las Vegas.Igbeyawo yii lo waye ni ọjọ akọkọ ninu ọdun 2022, lẹyin ti o ti ba awọ pinki dọrẹ fun ogoji ọdun.Ijọ "A Little White Wedding Chapel" ni wọn ti ṣe igbeyawo naa.

Aṣọ, irun, ati ẹṣọ ara Sera ni ojẹ awọ pinki bẹẹ naani awọn alejo nibi igbeyawo ọun wọ aṣọ pinki.Sera wi pe oun ni ọpọlọpọ nkan ti ojẹ alawọ pinki lati ṣakawe ifẹ ti oun ni fun awọ naa.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

O ṣalaye pe aba ati ṣe igbeyawo aramanda yii wa lẹyin ti ọmọ kan gba oun ni iyanju pe ki oun fẹ awọ naa latari ifẹ ti oun ni si.Sera fikun ọrọ rẹ pe botilẹjẹpe iwa ti oun wu jẹ kayefi, o dara ki eniyan maa ṣe oun ti o ba fẹran.

Àkọlé fídíò, Ọmọ ọdún mẹ́ta ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ní lu ìlù, kí n tó di onílù Yinka Ayefele