Sex swingers: Kò sóhun tó burú níbẹ̀ kí èmi àti ìyá mi jọ maa pín ọkọ mi lóríi bẹ́ẹ̀dì - Madi Brooks

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Tinubu ló ní kí n dọ́kẹ́ bí bẹ́ẹ̀ kọ́, mo mọ èsì tó yẹ kí ń fún Lai Muhammed - Gómìnà Kwara
Gómìnà Kwara ti pada sọ̀rọ̀ lóríi aáwọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Lai Mohammed, ǹkan ki síbẹ̀
Arabinrin kan ti ṣafihan pe oun ati iya to bi oun lọmọ lawọn jọ n ni ibalopọ pẹlu ọkọ oun eyi ti si da wahala silẹ lori ayelujara.
Madi Brooks sọ eyi ni gbangba lori fọnran TikTok kan ti oun ati ọkọ rẹ ti jọ n ṣe eto lori ayelujara.
O ni bi ara oun ko ba si lọna, inu oun maa n dun ki iya oun ba oun ọkọ rẹ lajọṣepọ.
Idi eyi si ni wipe ati Madi ati iya rẹ ati ọkọ rẹ jijọ jẹ onpasiparọ ibalopọ gẹgẹ bo ṣe sọọ (Swingers).
O tumọ si pe awọn mẹtẹẹta jọ wa ninu ibadọrẹ to ṣi silẹ (Open relationship) fun anfani lati pin ololufẹ ara ẹni lo.
Amọṣa kii ṣe gbogbo ẹni to wa ninu ibadọrẹ to ṣi ni o tun jẹ onipasiparọ fun ibalopọ.
To ba jẹ ibadọrẹ to ṣi silẹ ni, awọn ololufẹ maa n forikori pa ẹnu pọ pe awọn le maa fẹ ara awọn wọn si tun le maa ri ẹlomiran, wọn le jọ ṣee papọ tabi lọtọọtọ.
Amọ ni ti ṣiṣe pasiparọ, o jẹ irufẹ ibalopọ ti awọn aṣẹwo maa n ṣe ti awọn ti ko tii lọkọ tabi laya yoo maa kopa ninu orisiri pinpin ibalopọ.
Ninu fidio naa ndi Madi ti sọrọ pe: "emi ati mama mi jijọ jẹ onipasiparọ ibalopọ mọ bi:.
Njẹ ẹ mọ idi? "Toripe bi ara temi ko ba wa lọna, mo kan maa n gba ki o ba iya mi lajọṣepọ
"Mo gba ọkọ mi laye lati fun wọ ni iye ọjọ ti wọn yoo jọ wa pọ ninu ọsẹ kan
Koda, pabanbari tun wa ni pe kii ṣe iya rẹ nikan lo n ba ṣe pasiparọ iyawo tirẹ, o tun gba aburo rẹ laye lẹẹkọọkan lati ba ọkọ rẹ ṣere.
O ni: Ṣe o fẹ́ mọ bi mo ṣe ma n da inu ọkọ mi dun? Mo maa n jẹ ko ba aburo mi kekere ṣere".
Lati igba ti o ti sọ ọ̀rọ̀ yii ni fidio rẹ ti jade to si gba ori ayelujara kan to bẹẹ to ti le ni miliọnu mẹjọ eeyan to ti woo tawọn eeyan si n bu ẹnu atẹ luu.
Eeyan kan ni "eleyii gangan ti to ni "TikTok odidi ọdun kan, eyi ti mo wo to".
"Bawo ni ọrọ naa ṣe bẹrẹ? Ẹlomiran bere
Ẹlomiran lori TikTok ni "emi o mọ bi eeyan ṣe le maa pin ara wọn loo amọṣa igbe aye tiẹ niyẹn".

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ki lo yẹ koo mọ nipa "Swinging sexual practise"?
Swinging tumọ si ki eeyan maa ṣe pasiparọ iyawo, ọkọ tabi ololufẹ.
Irufẹ ibalopọ eyi ti awọn apọn tabi awọn to ti di alarede tabi awọn to kan n fẹ ara wọn n ṣe tọkan tọkan ti wọn gba ara wọn gbọ naa ni awọn wọnyii n ba ara wọn pin fun igbadun ara wọn.
Oniruuru ni idi ti awọn to n ṣe ibadrẹ oni pasiparọ ololufẹ fi n ṣee.
Awọn to n ṣe pasiparọ yii ti ṣapejuwe eredi rẹ pe lati lee mu wọn jingiri sii ninu ibalopọ to muna doko ni wọn fi n ṣe bẹẹ.
Eeyan kan ṣalaye pe awọn "Swingers" o ki n ṣe eeyan to n wa ibalopọ pupọ kiri, laarin ara wọn naa ni.
Saynt ni dipo bẹẹ, awọn "Swingers" maa n diidi wa ibalopọ pẹlu eeyan diẹ ti wọn ko si ni maa yan awọn ololufẹ wọn jẹ.














