What to do after Sex: Wo àwọn ohun mẹ́jọ́ tí àwọn olólùfẹ́ gbọ̀dọ̀ ṣe lẹ́yìn ìbálòpọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ololufẹ nigba miran ma n ṣe awọn aṣiṣe kan lasiko ati lẹyin ibalopọ pẹlu ara wọn, eleyii to le e fa aisan si ara awọn mejeeji.
Akojọpọ ohun to yẹ ki wọn ṣe ni yii lati koju aarun to le jẹyọ lẹyin ibalopọ.
Awọn ohun mẹjọ ti o pọn dandan lati ṣe ni yii lẹyin ibalopọ;
- Àrà méèrírí! Ọkùnrin tí kò ríran kan rèé tó ń lọ ẹ̀rọ ata
- ‘Ò dà bí àlá bí mọ ṣe da ìlúmọ̀ọ́ka nítorí bí a ṣe ń gbé òkú jó ní Ghana’
- Alífábẹ́ẹ́tì Ohùn Oduduwa di ìtẹ́wọ́gbà ni Ajaṣẹ
- Àsìkò wo ló yẹ kí obìnrin bẹ̀rẹ̀ ìbálòpọ̀ padà lẹ́yìn ìbìmọ láìséwu?
- Ojú wa rí tó lásìkò tì a wà ní àhámọ́ ajínigbé, koríko la jẹ fún ọjọ́ 52
Tun ibi tẹ ẹ lo ṣe;
Ohun akọkọ ti awọn ololufẹ gbọdọ ṣe ni wẹrẹ ti wọn ba ba ara wọn lọpọ ni lati tun ara wọn ṣe.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Wọn gbọdọ ri pe ori ibusun ti wọn lo wa ni mimọ, ki wọn tun ohun gbogbo ti wọn ba lọ ṣe, ki wọn si da pada si ibi to yẹ ki o wa.
Lọpọ igba yoo ti rẹ awọn mejeeji ti wọn si fẹ sun bẹẹ, amọ ko tọna nitori agbegbe ati ibusun gbọdọ wa ni imọtoto.
Ẹ fọ ọwọ yin lẹyin ibalopọ;
O ṣe pataki ki eniyan wa ni imọtoto paapaa lẹyin ibalopọ nitori ọwọ ṣe pataki ati ohun ti ẹ ba fi ṣe lasiko ibalopọ.
Awọn miran a tilẹ dide ni kiakia lati lọ fi ọwọ naa jẹun lai fọ, eyi ko dara to.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Tiraka lati lọ gbọnṣẹ tabi tọ itọ lẹyin ibalopọ;
Lilọ si ile igbọnṣẹ lati lọ ṣe ẹyọ tabi gbọnṣẹ lẹyin ibalopọ yoo ṣe iranwọ fun awọn mejeeji nitori gbogbo awọn idọti ara ni yoo gbọn jade kurọ ninu ara.
Nitori naa ẹ gbiyanju lati ma a ṣe eyi ni orekọọre.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹ jijọ wẹpọ ni baluwẹ;
Bio tilẹ jẹpe awọn obinrin miran ko fẹran ati ma a wẹ papọ lẹyin ibalọpọ nitori pe ki nkan ọmọkunrin ma tun dide pada lẹyin ti wọn ti ṣẹtan.
Amọ ohun ti o dara ni lati jọ wẹ papọ ninu baluwẹ ki ifẹ naa le tun gbooro si.
Eleyii ti ma n mu ki igbọraẹniye laarin lọkọ-laya gbẹru si nitori wọn ko ni korira ara wọn ti wọn ba n wẹ papọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Omi mimu se pataki lẹyin ibalopọ:
Ẹ tiraka lati mu omi lẹyin ibalopọ, ẹ ma kan dide ni kiakia tabi ki ẹ sun lọ, ẹ nilo ati mu omi.
Bakan naa ni ko ni lera fun awọn ololufẹ lati tọ, ki omi naa le yọ gbogbo idọti to ba wa ninu ara kuro.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹ jẹun papọ lẹyin ibalopọ;
Ohun miran ti awọn ololufẹ gbọdọ ṣe lẹyin ibalopọ ni lati jẹ ounjẹ.
Nigba miran ibalopọ ma n jẹ ki eniyan ma ni agbara, amọ ti ẹ ba jẹun lẹyin ibalopọ, yoo fun awọn mejeeji ni ọkun ati agbara ti wọn nilo.
Ẹ sun orun ayọ lẹyin ibalopọ;
Ẹ ri pe ẹ sinmi tabi sun lẹyin ibalopọ ki ẹ le ni agbara pada nitori kii ṣe iṣẹ kekere ni ibalopọ.
Nitori naa eniyan gbọdọ sinmi ki wọn to bẹrẹ iṣẹ miran.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹ ṣe ayẹwọ kokoro ibalopo, HIV
O dara ki eniyan ṣe ayẹwo ara loore-koore nitori arun ti o le e lọ eniyan di alaigbara ni arun bii HIV.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nitori naa lẹyin ibalopọ, ẹ ṣe ayẹwọ ara yin gẹgẹ bi ololufẹ.
Bakan naa ni ki ẹ ṣọra fun ibalopọ pẹlu ẹni to ba ni ololufẹ pupọ nitori apinka arun naa.
















