Zamfara Kidnap: Koríko láwọn tí orí kó yọ lọ́wọ́ ajínigbe jẹ fún ọjọ́ tí wọ́n fí wà ní àhámọ́

Oríṣun àwòrán, Zamfara State Police
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Zamfara ti doola ẹmi awọn eeyan mẹtadinlaadọwa lati ọwọ awọn ajinigbe.
Ọjọ mejilelaadọta ni wọn lo ni akasọ awọn alaburu yi ki ori to ko wọn yọ.
Alukoro ọlọpaa Mohammed Shehu to kede itusilẹ wọn sọ pe awọn ti ko awọn eeyan wọnyi le awọn alaṣẹ ipinlẹ lọwọ.
- Ipò tó le gidi ní Oloye Sunday Igboho wà báyìí lóòtọ́ tó sì nílò kó lọ sí Germany - Salami
- Agbébọn yìnbọn pa akẹ́gbẹ́ rẹ́ lásìkò ìjínígbé tí wọ́n kójú Àmọ̀tẹ́kùn
- Ẹ wo Ajá tó ń gbọ́ òórùn àìsàn ibà, ẹja tí a kò gbọdọ̀ pa àti ọọ̀nì tó ń gbọ́ àdúrà ní Ìbàdàn
- Kí ni òṣèré Chiwetalu Agu ṣe tí àwọn ológun gbé e jàǹtò? Ẹṣẹ tí wọn kà síi lọrùn rèé
- Àwọn olọ́kadà ti gba àwọn ìyàwó wa tán nítorí a kò lówó lọ́wọ́- Àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì ni Benue
Ko sọ pato boya wọn san owo idoola amọ o ni nigba tawọn agbofinro n para inu igbo Tsibiri lawọn ri awọn eeyan wọn yi.
Ninu aworan ti o gba ori ayelujara kan, niṣe ni awọn ti wọn doola yi dabi ẹni ti ebi n pa ti ko si ni alaafia to.
Ọkan ninu awọn to moribọ yi to ba ileeṣẹ iwe iroyin Naijiria Punch sọrọ ni oju awọn ri to lasiko tawọn fi wa ni ahamọ.
Arabinrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Iklima Murtala sọ pe awọn janduku to ji awọn gbe ko fun awọn lounjẹ jẹ.
''Nigba ti wọn gbe wa de ibi ti wọn ko wa si, lẹyin ọjọ diẹ ti wọn fi fun wa lounjẹ niṣe ni wọn kọ lati fun wa lounjẹ lẹyin igba naa''
'A ko ri nkankan ṣe ju pe ki a wa koriko to ba ṣe jẹ lagbegbe naa ki a si maa jẹ ki ẹmi ma ba bọ mọwa lọwọ''
O ṣalaye pe eeyan mẹtadinlogun lebi lu pa ninu awọn ti wọn ji gbe.Koda o ni eeyan meji mii ku nigba ti wọn gbe awọn pada de Gusau.
Laipẹ yi ni awọn alaṣẹ ni ipinlẹ Zamfara ati Kaduna ti oju opo ikansiraẹni lori foonu lọna ati koju ipenija awọn ajinigbe ati janduku.
Ijọba ni ababọ igbesẹ yi ni awọn eeyan ti awọn ribi doola yi to fi mọ awọn ajinigbe mii ti ọwọ awọn ti tẹ.
- Àpẹ́rẹ́ àìsàn tó ń fa àrùn jẹjẹrẹ pọ̀ lára àwọn obinrin tó wà ní ìlú Ibadan - Ìwádìí fìhàn
- Ọjọ́ iwájú ní kí o wò, má fi gbèsè owóyàá bá ọjọ́ ọlá àwa ọmọ Nàìjíríà jẹ́-ẹgbẹ́ MAN
- Tọkọ-taya kú lẹ́yìn tí wọ́n jẹun tán ní Ọjọ́ Àyájọ́ Ọ̀mìnira Nàíjíríà
- Àwọn adari ẹgbẹ́ òṣèlú PDP bẹ̀rẹ̀ ṣèpàdé lórí ọjọ́ ọ̀la ẹgbẹ́ náà
- Àjọ WHO gbé abẹ́rẹ́ àjẹsára àìsàn ibà jáde fún ilẹ̀ Afrika
- Wo kókó mẹ́ta nípa àbá ìsúná ₦16.39trn fún ọdún 2022 tí Buhari gbé lọ sílé aṣòfin
















