Zamfara policemen gunned down: Àwọn ọlọ́pàá méje míràn fi ara pá níbí ìkọlù náà lọ́jọ́ Aiku ní Zamfara

Oríṣun àwòrán, Others
Àwọn agbébọn ti pa ọlọ́pàá mẹ́tàlá ní Zamfara- Gomina Zamfara
Emi awọn agbofinro mẹtala lo ba ikólu awọn agbebọn naa rin ti ọpọ ọlọpaa si fara pa yanayana ni Zamfara.
Ijoba Naijiria ti fidié mulẹ pe ẹmi agbofinro mẹtala lo sọnu nibi ikọlu awọn agbebọn to waye ni ariwa iwo oorun ipinle Zamfara ni ariwa Naijiria loke Oya.
- Ohun márùn ún tó mú ìgbé ayé le fọ́mọ Nàìjíríà lójoojúmọ́
- Agbébọn já bàálù ológun bọ́, orí kó Abayomi Dairo, awakọ̀ bàálù náà yọ
- Ààrẹ Ògbóni sọ òkò ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí Gani Adams torí bó ṣe tàbùkù Ọba Ogboni tó ṣe ìwọ́de Yorùbá Nation
- Ẹ̀yin ọmọ Nàíjíríà, mó rí ìlàkàkà yín, ẹ ṣe sùúrù nítórí ìyá yìí yóò dópìn - Ààrẹ Buhari
- Ilé ẹjọ Májísírèètì Yaba nípinlẹ Eko ti gba béèlì àwọn olùwọde Yoruba Nations 49 tí wọn wa ní àhámọ
Ojo Aiku ni wọn ni awọn agbebọn naa kọlu awọn olopaa nibẹ.
Koda, iroyin naa ni awọn ọlọpaa meje miran fi ara pa yanayana.
Won ni eyi sẹlẹ leyin ọjọ kan ti awọn agbebọn ji eniyan aadọta gbe ni awọn abule kan ni Zamfara.
Gomina ipinlẹ Zamfara, Ogbeni Bello Matawalle so ninu atẹjade pe: Awọn agbebọn naa ti dẹ panpẹ silẹ de awọn agbofinro naa ni loju ọna abule kan ni ijọba ibilẹ Bungudu.
Awọn agbofinro ni Zamfara salaye pe ipe ijaya kan ni awọn ọlọpaa ti isẹlẹ yii sẹlẹ si gba.

Oríṣun àwòrán, Others
Ti wọn si gbiyanju lati lọ se iranwọ sibẹ ki awọn agbebọn to kọlu wọ́n.
Lọsẹ to kọja ni wọn pa ogagun agba ologun kan ni Abuja.
Lojó kan naa ni wọn tun pa ọmọ ogun mẹrin nibomii ni Naijiria.
Eto aabo Naijiria lo n ko ọpọ lominu bayii.













