Benue Protest: Àwọn olọ́kadà ti gba àwọn ìyàwó wa tán nítorí a kò lówó lọ́wọ́- Àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì ni Benue

Oríṣun àwòrán, others
Àwọn òṣìṣẹ́ fẹyinti kan ni ipinlẹ Benue ti gúnlè ìwọ́de lòdì sí bí ìjọba ipinlẹ naa ṣe kọ lati san awọn owo oṣu àti ajẹmọnu wọn fún nnkan bíi ọdún mẹta.
Wọn bẹrẹ ifẹhonuhan náà láti agbegbe Ken Ville Park, ni High Level, wọn sì lọ káàkiri ìlú ti wọn sì ni kọ onírúurú orin.
Alaga ẹgbẹ àwọn òṣìṣẹ́ fẹyinti náà, Akosu Ugba sọ fún àwọn akọroyin pé àwọn n ṣe ìwọ́de náà láti bere ẹtọ awọn lọwọ ìjọba, ati pe ki awọn aráàlú lè mọ ohun ti wọn n dojukọ.
- Àwọn adari ẹgbẹ́ òṣèlú PDP bẹ̀rẹ̀ ṣèpàdé lórí ọjọ́ ọ̀la ẹgbẹ́ náà
- Tọkọ-taya kú lẹ́yìn tí wọ́n jẹun tán ní Ọjọ́ Àyájọ́ Ọ̀mìnira Nàíjíríà
- Ọjọ́ iwájú ní kí o wò, má fi gbèsè owóyàá bá ọjọ́ ọlá àwa ọmọ Nàìjíríà jẹ́-ẹgbẹ́ MAN
- Òní ni Ààrẹ yóò kéde ètò ìṣúná ọdún 2022
- Àpẹ́rẹ́ àìsàn tó ń fa àrùn jẹjẹrẹ pọ̀ lára àwọn obinrin tó wà ní ìlú Ibadan - Ìwádìí fìhàn
Ọ ni "A fẹ kí gbogbo àgbáyé mọ pé ebi n pa wa, ìyá si n jẹ wá."

Oríṣun àwòrán, others
Alaga ni: "Ohun tó n ṣẹlẹ sí wa jẹ ifiyajẹni lọna àìtọ́ nitori a kò tíì gba owo oṣù lati nnkan bíi ọdún mẹta o le."
Arakunrin naa tẹsiwaju pe "Awọn ọmọ wa ko le lọ ile ẹkọ mọ nitori a kò rí owo san, awọn ọlọkada sí ti gba awọn ìyàwó wa nitori a ko lowo lọwọ."

Oríṣun àwòrán, others
Gẹgẹ bíi ohun tó sọ, púpọ nínú wọn ló dubulẹ àìsàn ṣugbọn ti kò ri owó láti tọju ara rẹ.
- Ọwọ ọlọ́pàá tẹ afurasí ajínigbé tó máa n dibọn bí dírẹ́bà láti jí àwọn arìnrìnàjò gbé
- Kéére o! Ojú òpó WhatsApp kò ní ṣiṣẹ́ mọ́ lórí àwọn ẹ̀rọ ìléwọ́ yìí láti Nov 1
- Bí ẹnu rẹ bá ń rùn, ọ̀nà márùn-ún tí o lè gbà láti ṣẹ́gun ẹnu rírùn àti ìṣòrò eyín
- Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin yan ẹ̀ní tó tí bẹ̀rẹ̀ iléẹ̀kọ́ kí wọ́n tó bíi sáyé gẹ̀gẹ̀ bí ọmọ ìgbìmọ̀ Àjọ EFCC
- Iléẹjọ́ ti ṣetán lórí ẹjọ́ Omolọla ọlọ́pàá obìnrin tí wọ́n lé lẹ́nu iṣẹ́ nítorí pé o gboyún
- Ìdí rè é. tí ọmọ tí kò bá tí pé 18 kò ṣe lè lo ''SIM Card'' mọ́ ní Naijiria...
Ọ fi kun pe nnkan bíi ẹẹdẹgbẹta lara wọn lo ti kú láì rí ẹtọ wọn gbà lọwọ ìjọba.
Lẹyìn náà ló rawọ ẹbẹ sí ìjọba láti boju aanu wo awọn ki wọn ma ba a ku sinu iṣẹ.















