Suspected Kidnappers: Ọwọ ọlọ́pàá tẹ afurasí ajínigbé tó máa n dibọn bí dírẹ́bà láti jí àwọn arìnrìnàjò gbé

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police
Ileeṣẹ ọlọpaa lorileede Naijiria sọ pe ọwọ awọn ti tẹ awọn afurasi ajinigbe ogun to n da omi alaafia ilu ru lagbegbe iwọ oorun ariwa Naijiria.
Alukoro ọlọpaa Sunday Mba to fi ọrọ yi sita ninu atẹjade kan sọ pe awọn ti ọwọ tẹ jẹ ọmọ ikọ ajinigbe meji ọtọọtọ to n ji awọn eeyan gbe loju ọna marosẹ.
Mba sọ pe ibọn atamatase mọkanla ati ado oloro aṣekupani mọkanla lawọn ri gba lọwọ awọn afurasi yi.
- Obìnrin tó bá ń gbé bùkátà kò ní ọkọ kódà kó wà nílé ọkọ - Kemi Afolabi
- Ẹ gbà wá! Boko Haram ti gba ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ ìlú tán ní ìpínlẹ̀ Niger tí kò jínà sí Abuja
- Ìyàwó adarí òṣìṣẹ́ nípìnlẹ̀ Ondo tí wọ́n jígbé gba òmìnira lọ́wọ́ ajínigbé
- Ọpẹ́ o! Àwọn ologun dóòlà akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́fà lọ́wọ́ àwọn ajínigbé ní Kaduna
- Ajínigbe sún gbàgbé láwọn 15 nínú àwọn 156 tí wọ́n jí gbé ní Tegina bá sálọ
- À ò ni gbárùkù tì gbogbo ẹ̀yin gómìnà ìhà Gúúsù tó bá tako kíkẹ́ràn jẹ̀ - Miyetti Allah
- Facebook ń ṣàkóbá fún ọpọlọ ọmọdé ó sì ń káàrẹ̀ bá ìjọba àwaarawa, àṣírí tú! - Òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ Facebook
Gẹgẹ bi atẹjade to fi sita ti ṣe sọ, ogunagbongbo inu awọn afurasi yi a maa dibọn bi awakọ lati le fi ji awọn eeyan to ba wọ ọkọ rẹ gbe.
Wọn ni bo ba ti gbe awọn ero tan, yoo ta awọn akẹgbẹ rẹ lolobo ti wọn yoo si da awọn eeyan naa lọna.
Bi wọn ṣe n gba owo lọwọ awọn ti wọn ji gbe, bẹẹ naa ni wọn a tun maa pa awọn mi ninu awọn to ba ko si wọn lọwọ.

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police
Yatọ si awọn ajinigbe wọn yi, alukoro ọlọpaa sọ pe awọn tu mu ikọ awn to n ji ọkọ gbe ti wọn a si tun maa ṣe fayawọ ọkọ.
- Àṣírí ọ̀rọ̀ àti dúkìá ìkọ̀kọ̀ ẹbí aarẹ Uhuru Kenyatta tú
- Kàyééfì! Ẹ wó ìyàwó tó ṣán ọkọ rẹ̀ mọ́lẹ̀ tó sí fí àdá bẹ orí rẹ̀!
- Ṣé o ti gbọ́ nípa ìlú tí ara sísan ti jẹ́ dandan fún àwọn ọmọbìnrin?
- Àwọn agbègbè ní ìpínlẹ̀ Eko rè é tí kò ní gbádùn iná ọ̀ba fún ọ̀sẹ̀ mẹ́jọ...
- Èkó àti Rivers nìkan kọ, wo àwọn ìpínlẹ̀ Gúúsù-Gúúsù mi tó ṣetán láti lọ sílé ẹjọ́ gíga jùlọ lórí VAT
- À ò ni gbárùkù tì gbogbo ẹ̀yin gómìnà ìhà Gúúsù tó bá tako kíkẹ́ràn jẹ̀ - Miyetti Allah
Ọkọ mẹẹdogun ni wọn ri gba pada lọwọ wọn ti a si gbọ pe wọn a maa gbe ọkọ ti wọn ba jigbe lọ si orileede Niger lati lọ ta a nibẹ.













