Mauritannia: Ṣé o ti gbọ́ nípa ìlú tí ara sísan ti jẹ́ dandan fún àwọn ọmọbìnrin?

Ara sisan

Oríṣun àwòrán, others

Wo oko ọlọ́ràá níbi tí wọ́n ti n fi ipá fún àwọn ọmọbìnrin ní oúnjẹ nítorí ìgbéyàwó.

Oúnjẹ ẹnikan, eewọ ẹlomiran ni. Ìdálùú si ni iṣelu.

Ni Mauritania, dandan ni fun awọn ọmọbinrin lati sanra.

Koda, odinwọn eroja 'calories' to ma n wa ninu oúnjẹ ọlọra, ti ìwọ̀n rẹ to ẹgbẹrun mẹrindinlogun ni wọn n fi tipátipá fun wọn jẹ ni ojoojumọ.

Ni orilẹ-ede yii, obìnrin ti ko ba sanra, kii ṣe arẹwà.

Orilẹ-ede ẹlẹ́sìn Islam ni Mauritania. Oun si ni orilẹ-ede kọkanla ti akọsilẹ sọ pe o tobi julọ ni Afrika.

Àkọlé fídíò, Adepoju Abdulsalamm ẹni ọdun 18 tó n fi kẹ̀kẹ́ dára fi kiri ẹja tó fi n tà wàràwàrà

Idi ti wọn si fi n se bẹẹ ni pe ki wọn o le mura àwọn ọmọbìnrin naa silẹ fun igbeyawo.

Wọn ma n ko awọn ọmọbinrin naa pamọ si ibùdó kan ti wọn n pe ni 'fat farms', eyi ti a le tumọ si "Oko ọlọra".

Àkọlé fídíò, Ebun Oloyede Olaiya Igwe sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí lásìkò àìsàn kídìnrín tó yọ ọ́ lẹ́nu

Pẹlu lílù ni wọn fi ma n fun awọn ọmọbinrin naa ni oúnjẹ ọlọra lati jẹ.

Ara sisan jẹ nkan ẹwà ni orilẹ-ede naa. Laarin ọmọ ọdun mejila si mẹrinla si ni awọn ọmọbinrin wọn ma n lọ sile ọkọ, nitori bi wọn ṣe tobi.

Awọn ọmọbinrin naa kii ṣe iṣẹ kankan ju oúnjẹ jíjẹ ati oorun sísùn.

Bi obìnrin ba si ṣe sanra to ni yoo sọ bo ṣe ṣe pataki to ni oókan àyà ọkọ rẹ.

Àkọlé fídíò, Àwọn ọkùnrin tó wà nínú ayé wa gbúdọ̀ bọ̀wọ̀ fún wa - Adarí FIN

Nitori naa si ni wọn ṣe tete ma n fi agidi fun awọn ọmọbinrin wọn ni oúnjẹ ọlọra jẹ, ko le se rùmú-rùmú to lati tete lọ sile ọkọ.

Awọn obinrin to jẹ agbalagba si lo ma n dari eto naa, to si jẹ pe wọn ma n fi iya jẹ ọmọbìnrin to ba kọ lati jẹun tabi mu nkan ti wọn ba gbe fun.

Lara iya ti wọn fi n jẹ wọn ni fifi igi gun wọn ni ìka ẹsẹ̀ titi wọn o fi jẹun.

Awọn nkan ti wọn n fun wọn jẹ naa lo ma n ṣe atọna bi awọn ọmọbinrin naa ṣe tete n balaga.

Àkọlé fídíò, Ọ̀ṣọ́ Aṣọ Òkè ti kọjá lílo ìlẹ̀kẹ̀ níkan

Igbagbọ awọn ọkunrin Mauritania ni pe obìnrin to sanra jẹ oju ni gbese ju eyi ti ko sanra lọ.

Lọdun 2008, ijọba alagbada lorilẹ-ede naa gbiyanju lati sofin jíjẹ oúnjẹ asaraloore, àmọ́ iditẹgbajọba lọdun 2008 mu ki igbiyanju naa ja si ofo.

Awọn oloṣelu ko si fi opin si awọn oko ọlọra naa.

Àkọlé fídíò, Awo Stage Play: Wo eré, ijó àti orin tó ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ nípa ayé Awolowo àti aya rẹ̀