Niger Boko Haram: Ẹ gbà wá! Boko Haram ti gba ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ ìlú tán ní ìpínlẹ̀ Niger tí kò jínà sí Abuja

Oríṣun àwòrán, AFP/Boko Haram
Iroyin lati ipinlẹ Niger ti safihan bi ikọ agbesunmọmi Boko Haram ṣe gba ọpọlọpọ ilu to wa ni ipinlẹ naa.
Eleyii ti wa da ipaya si ara awọn eniyan, nibi ti ikọ Boko Haram ti n fun awọn araalu ni owo ti wọn si n gba wọn si ikọ wọn gẹgẹ bi oṣiṣẹ wọn.
Iroyin abẹlẹ ni awọn agbebọn naa ṣekọlu si awọn ilu kereje ni ijọba ibilẹ Shiroro, ti wn si n waasu fun awọn eniyan.
- Kàyééfì! Ẹ wó ìyàwó tó ṣán ọkọ rẹ̀ mọ́lẹ̀ tó sí fí àdá bẹ orí rẹ̀!
- Ẹ yé kóra jọ pọ̀ láti d'ẹ́rù ba ni pé ọwọ́ Yorùbá ni Ààrẹ 2023 gbọ́dọ̀ bọ́ sí- Shekarau
- Ṣé Facebook, Instagram, WhatsApp ti yín náà ti dẹnukọlẹ̀? Ìdí tó fi ṣẹ́lẹ̀ rèé...
- Wo ewu tó wà nínú fífi ọṣẹ ìfọyín àti omi gbígbóná ṣe ìtọ́jú okùn tó so olúbi pọ̀ mọ́ ìyá ọmọ
Ara agbegbe ibẹ kan sọ fun BBC pe ikọ Boko Haram ma n ko awọn eniyan jọ lati ṣe iwaasu fun wọn ti wọn si n fun awọn eniyan ni owo ni ilu Kurebe ati Kwaki.
Eleyii n ṣẹlẹ lẹyin oṣu mẹfa ti gomina ipinlẹ Niger, Abubakar Sani Bello kilọ pe Boko Haram ti gbe asia wọn si ijọba ibilẹ meji ni ipinlẹ naa, ti wọn si ti gba iṣakoso ibẹ.
Bakan naa ni Alaga ijọba ibilẹ Shiroro ati kọmiṣọnna fun eto iroyin ni nipinlẹ Niger ni lootọ ni ikọ Boko Haram ti gbakoso awọn agbegbe kan ni ipinlẹ naa.
Chukuba ninu ọrọ rẹ sọ fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe ikọ Boko Haram ti gba isakoso ilu kereje mẹjọ ninu marundinlọgbọn to wa ni agbegbe naa.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
''Ọpọlọpọ ọmọ ẹgbẹ Boko Haram lo pọ si ijọba ibilẹ Shiroro, ti wọn si ti gba ẹẹdẹgbẹta ilu kereje to wa ni ijọba ibilẹ Shiroro.
Bakan naa ni awọn araalu to ba BBC sọrọ ni ikọ Boko Haram yii tun ti gba awọn ilu miran bii Mashekari, Lukafe, Kusaka, Sabon Gida ati Kwaki Chukuba, ti wọn si n ṣe onidajọ awọn eniyan agbegbe naa.''
''Awọn Boko Haram wọ awọn ilu wọn yii, ti wọn si pe awọn eniyan si ita, wọn n ṣe iwaasu fun wọn, ti wọn si n ṣe idajọ wọn.''
''O fikun un pe awọn ajijagbara yii gba awọn agbegbe yii lẹyin ti awọn ẹṣọ alaabo fi agbegbe naa silẹ.''
- Ebun Oloyede Olaiya Igwe sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí lásìkò àìsàn kídìnrín tó yọ ọ́ lẹ́nu
- Àṣírí ọ̀rọ̀ àti dúkìá ìkọ̀kọ̀ ẹbí aarẹ Uhuru Kenyatta tú
- Ẹ̀yin ọmọ Yoruba ẹ darapọ̀ mọ́ wa látí tako ìjọba Naijiria lórí àtìmọ́lé Nnamdi Kanu - IPOB
- Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ẹ̀yà kan wà ní Africa, tó jẹ́ akọ́sẹ́mọsẹ́ nípa sí sọ nkan ọmọkùnrin di nla ní ìlànà ìbílẹ̀?
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun wó iléẹ̀kọ́ Nazareth High School, Imeko tó wó pa ọmọ orùkan
Amọ ijọba ipinlẹ Niger ni ijọba ati ẹṣọ alaabo ti n ṣiṣẹ papọ lati ri pe ikọ Boko Haram ko tẹ si waju lati gba awọn agbegbe miran mọ eleyii ti wọn ti gba pada.
O ti le ni ọdun mejila bayii ti ikọ ọmọogun Naijiria ti n koju ikọ Boko Haram to ti ṣọṣẹ lorilẹede naa ati agbegbe Lake Chad lẹyin iku adari wọn, Abubakar Shekau.
Laipẹ yii ik Boko Haram to le ni ẹgbẹrun mẹjọ jọwọ ara wọn fun ileeṣẹ ọmọogun Naijiria, amọ eleyii ko i tii jẹ ki idojukọ ipenija eto aabo to mẹhẹ naa ni iyanju.












