2023 presidency: À ò ni gbárùkù tì gbogbo ẹ̀yin gómìnà ìhà Gúúsù tó bá tako kíkẹ́ràn jẹ̀ - Miyetti Allah

Oríṣun àwòrán, Miyetti Allah Kautal Hore
Ọkan ninu awọn adari awọn darandaran ni Naijiria Miyetti Allah Kautal Hore ni awọn ko ni gbaruku ti gómìnà ìhà gúúsù kankan tó bá duro lodi si kiko ẹran jẹ ni itagbangba.
Agbẹnusọ ẹgbẹ naa Saleh Alhassan lo sọ eyi lọjọ Isegun fun ikọ iroyin Punch.
Saaju ni iroyin sọ pe awọn gomina iha guusu, mẹtadinlogun lo ti lodi si ikẹranjẹ ni itagbnagba , ti wọn si fẹsun kan pe, o n koba eto abo ni agbagbe awọn, nitori na wọn fofin dee.
- Nkechi Blessing sọ̀rọ̀ nípa ikú ìyá rẹ̀, ó tún tú àṣírí kàbìtì nípa ìhùwàsí ara rẹ̀ táyé kò mọ̀
- Gbogbo ẹ̀yín tí ẹ bá ní dola ninú ''account'' yín sí Naijiria, inú ewu le wà - Reno Omokri
- Ẹ yé kóra jọ pọ̀ láti d'ẹ́rù ba ni pé ọwọ́ Yorùbá ni Ààrẹ 2023 gbọ́dọ̀ bọ́ sí- Shekarau
- Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ẹ̀yà kan wà ní Africa, tó jẹ́ akọ́sẹ́mọsẹ́ nípa sí sọ nkan ọmọkùnrin di nla ní ìlànà ìbílẹ̀?
- Iná ìjọba gbé àwọn olújọ́sìn nínú ṣọ́ọ̀ṣì lásìkò ìsìn ní Ọjọ́ Ìsinmi, ẹ̀mí mẹ́rìn lọ si!
- Kìí ṣe pé ìjọba ń fi ọwọ́ jẹ́jẹ́ mú àwọn jàndùkú o - Lai Mohammed
Ọpọ awọn gomina iha guusu to fi mọ Ondo, Oyo, Osun, Ekiti, Abia Eko, Bayelsa, Rivers, Akwa-Ibom, Enugu ati laipẹ yii Ogun ati Delta ti wọn si buwọlu fifi opin si idaranjẹ.
Ẹgbẹ Miyetti llah naa, lasiko to sọrọ lori ibuwolu abadofin to fi ofinde ikẹranjẹ yii ni iha Guusu, o sakawe rẹ gẹgẹ i igbimọ ti o ssi ni ọwọ oselu ninu. bakan naa lo fi kun pe, awọn yoo gbe awọn gomina ọhun lọ ile ẹjọ.
Alhassan fẹsun kan pe, Ipinu awọn gomina lati fikuluku pẹlu awọn gomina mọkandinlogun to ku ni iha Arewa lati gbe ipo aarẹ lọ si iha guusdu ti fori sanpọ itori igbesẹ wọn lori ikẹranjẹ ti wọn tako.
Bi eto idibo ọdun 2023 ṣe n sunmọ, ọpọ awọn oloṣelu lo ti n ṣe ipade ti ipetepero oselu si n lọ.
Awọn gomina mẹtadinlogun iha Guusu ti pe ipade lẹẹmeji lọdun yii ti wọn si n pe fun ki ipo aarẹ lọ si iha Guusu.
Bakan naa ni awọn gomina mọkandinlogun ni iha Arewa naa ṣe ipade ni ọsẹ to kọja lati tako nnkan ti awọn ti guusu sọ
Wọn fi kun pe, ẹni to ba ni ibo to pọju lọ ni yoo wọle ninu idibo apapọ ọdun 2023.
Sugbọn lasiko ti agbẹnusọ Miyetti Allah n ba Punch sọrọ lonii lo sọ pe ẹgbẹ naa ko ni gbaruku ti gomina kankan to ba tako ikẹranjẹ ni gbangba ti o si tun tako ki ijọba apapọ maa gba owo ori (VAT)
- Iná ìjọba gbé àwọn olújọ́sìn nínú ṣọ́ọ̀ṣì lásìkò ìsìn ní Ọjọ́ Ìsinmi, ẹ̀mí mẹ́rìn lọ si!
- Òjò alágbára rọ̀ ní Ikare-Akoko, ilé àádọ́jọ bá a lọ, èèyàn kan tún kú
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun wó iléẹ̀kọ́ Nazareth High School, Imeko tó wó pa ọmọ orùkan
- Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ẹ̀yà kan wà ní Africa, tó jẹ́ akọ́sẹ́mọsẹ́ nípa sí sọ nkan ọmọkùnrin di nla ní ìlànà ìbílẹ̀?
- Ẹ̀yin ọmọ Yoruba ẹ darapọ̀ mọ́ wa látí tako ìjọba Naijiria lórí àtìmọ́lé Nnamdi Kanu - IPOB
- À ò ni gbárùkù tì gbogbo ẹ̀yin gómìnà ìhà Gúúsù tó bá tako kíkẹ́ràn jẹ̀ - Miyetti Allah



















