Yoruba film: Obìnrin tó bá ń gbé bùkátà kò l'ọ́kọ kódà kó wà nílé ọkọ - Kemi Afolabi

Oríṣun àwòrán, Kemi Afolabi
Gbajugbaja oṣere fiimu Yoruba, Kemi Afolabi ti bọ soju opo ayelujara lati sọ ero tirẹ nipa awọn obinrin to maa n gbe bukata ninu ile.
Loju opo Instagram rẹ ẹka to n jẹ Instagram Story ni Kemi ti kẹnu bọ ọrọ yii ni ọjọ melo kan sẹyin tawọn eeyan si fesi rẹpẹtẹ lori ọrọ to sọ.
Gbajugaja oṣere naa jẹ ko di mimọ pe ẹnikẹni to jẹ obinrin to ba n gbe bukata jẹ alailọkọ.
Bukata owo nina ninu ibaṣepọ ti di eyi ti wọn n gba bii ẹni n gba igba ọti lori ayelujara fun igba diẹ bayii.
Kemi ni "obinrin k'obinrin to ba n da gbe bukata ara wọn ko yatọ si kni ti ko lọkọ.
Lori ọrọ yii, awọn eeyan o jẹ ko tutu rara ti wọn fi n sọ oniruuru ero wọn. Awọn mii kẹyin si Kemi Afolabi ti wọn si n buu, awọn mii fọwọ si nkan to n sọ ti wọn si n tẹpẹlẹ mọọ pẹlu alaye tiwọn.
Mccoyinnocent beere pe "ki wa ni o yẹ ki awọn obinrin fi owo ṣe?
Ademola Balogun ni ko yẹ ko yẹ ko pe iru obinrin bẹẹ ni alailọkọ bi ko ṣe ẹni to yan lati da duro funra rẹ.
Justdamz ni tirẹ diidi lodi si ọrọ Kemi Afolabi ni pe "ootọ kọ lo sọ, dẹkun lati ṣi awọn ọdọ obinrin lọna. Kọ wọn lati maa gbe bukata ni ko le baa jẹ pe ẹnikẹni to ba wa sinu aye wan yoo kan jẹ oluranlọwọ ati afikun ọrọ fun wọn".
Dami6ambode ni ootọ lo sọ amọ gbogbo ẹ kọ ni ootọ.

















