Iya Ife: Said Balogun, Kemi Afolabi àtàwọn òṣèré míràn ń ṣèdárò Iya Ife tó fayé sílẹ̀

Ashabi Ayantunde, Iya Ife

Oríṣun àwòrán, bukysmart/Instagram

Ẹgbẹ awọn oṣere tiata ni Naijiria tun ti n ṣọfọ lẹyin ọjọ diẹ ti agba oṣere nni, Orisabunmi jade laye.

Ẹgbẹ awọn oṣere tiata Yoruba ti kede iku Ashabi Ayantunde, ti ọpọ eeyan mọ si Iya Ife.

Iya Ife jẹ ọkan gboogi lara awọn oṣere tiata Yoruba to dantọ to si mọ ere ṣiṣe, ede Ile Ife si lo maa n sọ ninu ere tiata.

Gẹgẹ bii ohun ti agbọ, obinrin naa dagbere faye laarin wakati diẹ to yẹ ko ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lara awọn akẹgbẹ rẹ nidii iṣẹ tiata to kede iku rẹ sọ pe, o jẹ ohun ibanujẹ gidi fun awọn ẹbi atawọn akẹgbẹ rẹ nidi iṣẹ ọhun.

Nigba ti Bukky Smart n ṣedaro rẹ loju opo Instagram rẹ, o ni bi iya ni Iya Ife jẹ si oun, lẹyin naa lo gbadura pe ki Ọlọrun dari ẹṣẹ rẹ jin, ko si tun tẹ si afẹfẹ rere.

Ashabi Ayantunde, Iya Ife

Oríṣun àwòrán, bukysmart/Instagram

Oṣere miran to tun kẹdun iku rẹ ni Adigun to sọ pe nnkan bii aago mẹta oru ni oun ṣi n ki oloogbe ọhun ku oriire ọjọ ibi rẹ lai mọ pe ọlọjọ ti de.

Ọpọ awọn gbajumọ oṣere miran lo ti bẹrẹ si n kẹdun iku Iya Ife lori ayelujara.

Lara awọn oṣere naa ni, Saidi Balogun, Damola Olatunji, Kemi Afolabi, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ọrọ ti Kemi Afolabi sọ nipa Iya Ife

Oríṣun àwòrán, bukysmart/Instagram

Kemi Afolabi ni iya naa maa n fi ifẹ nla han si oun, to so maa n pariwo ọmọ ti wọn n sọ nigbakuugba to ba ri oun loko ere tiata.

Titi di akoko ti a n ko iroyin yii jọ, ko sẹni to le sọ ni pato ohun to ṣokunfa iku oṣere naa.

A gbadura pe ki Ọlọrun tẹ si afẹfẹ rere.

Iya Ife

Oríṣun àwòrán, bukysmart/Instagram