Isa Patami: Mínísítà fèsì sí ìròyìn tó ní ó wà lára àwọn bàbá ìsàlẹ̀ Boko Haram àti Al-Qaeda

Isa Patani

Oríṣun àwòrán, @DrIsaPantami

Minisita fun ileeṣẹ ijọba to n ri eto ibaraẹnisọrọ ni Naijiria, Isa Pantami ti fesi si iroyin kan to sọ pe, orilẹ-ede Amẹrika kede rẹ gẹgẹ bi ọkan lara awọn baba isalẹ ẹgbẹ agbesunmomi Boko Haram.

Pantami sọ loju opo Twitter rẹ pe, ile iṣẹ iroyin to gbe iroyin ọhun jade yoo foju ba ileẹjọ fún ibanilorukọ jẹ.

Laarọ ọjọ Aje ni iroyin naa lu ori ayelujara pa pe, Amerika darukọ minisita eto ibaraẹnisọrọ gẹgẹ bi ọkan lara awọn to n ṣe onigbọwọ ẹgbẹ agbesunmomi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iroyin kan tiẹ ṣalaye pe, ẹka ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ Amerika sọ pe ki Pantami to de ipo minisita, lo ti jẹjẹ lati maa ṣe atilẹyin fún ẹgbẹ Al-Qaeda.

Iwe iroyin naa tun sọ pe, Pantami ni ibaṣepọ pẹlu olori akọkọ fun ikọ Boko Haram, Mohammed Yusuf at'awọn olori ẹgbẹ Abu Quatada Al-Filistini ati Al-Qaeda.

Ikọ Boko Haram

Oríṣun àwòrán, NigeriaArmyHQ

Amọ, minisita naa ni fun bi ọdun mẹẹdogun loun ti n ṣe idanilẹkọ tako awọn alakatakiti ẹsin.

Pantami ni lori ọrọ lilo kaadi idanimọ NIN lati fi koju eto abo to mẹhẹ, o ni ijọba ko ni boju w'ẹyin.

Ẹwẹ, iwadii fihan pe orukọ Pantami ko si ninu awọn orukọ awọn to niṣe pẹlu ẹgbẹ agbesunmomi ti awon ọlọpaa FBI fi lede.

Agbẹnusọ fun minisita feto ibaraẹnisọrọ naa, Uwa Suleiman sọ fun BBC pe, iwe iroyin to gbe iroyin naa jade fẹ fi ba minisita lórúkọ jẹ lasan ni.

Suleiman ni onimọ nipa ẹsin Islam ni Pantami, o sí kẹkọọ kaakiri orilẹ-ede agbaye to fi de orilẹ-ede Saudi Arabia.

Àkọlé fídíò, Female Car Painter: Èmi ní obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò máa ṣiṣẹ́ akunmọ́tò ní Ibadan

O ṣalaye pe koko miran to fihan pe Pantami ko mọ ohun kan nipa awọn ẹgbẹ agbesunmomi ni fidio ti olori Boko Haram Abubakar Shekau ṣe ninu eyi to ti sọ pe Pantami wa lara awọn eeyan ti oun fẹ pa.

O ni Shekau sọ ninu fidio ọhun lọdun 2020 pe Pantami lọ darapọ mọ ijọba bo tilẹ jẹ pe onimọ nipa ẹsin musulumi ni.