Nollywood: Gbajugbaja òṣèré ''Toromagbe'' nínú fíìmù ''Arelu'' ti jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Facebook
Ẹbi ati ara gbajugbaja oṣere, Oloye Abdul Tawab Olaitan Ile-Aje Adeniyi ti kede iku rẹ ni ẹni mẹtalelọgọta.
Oloye Abdul Tawab Olaitan Ile-Aje Adeniyi lo kọpa ninu ere agbelewo ti wọn ṣe ni ọdun 1986, ti wọn si pe akọle rẹ ni ''Arelu''.
Ẹgbọn rẹ, Tola Adeniyi lo kede rẹ fun aye pe o ti jade laye.
- Wọ́n fẹ́ ba dáadáa ààrẹ Buhari jẹ́ ni wọ́n ṣe ń lọ́ kíkojú ìṣòro àbò mọ́ ikú àwọn àgbẹ̀ Koshebe
- Ẹ wo ọmọ Yoruba, Adewale Adeyemo tí yóò jẹ igbákejì akọ̀wé akápò ní ilẹ̀ Amẹrika
- Ṣe lóòtọ́ ní ọmọ Nàíjíríà mílíọ́nù 25 yóò má ló ìná Solar látí Dec 1, 2020?
- Mi ò ṣe ẹ̀tánú Ọọ̀ni ilé Ifẹ̀, ọmọ ìyá mi ni ṣùgbọ́n...-Olugbo Obateru Akinruntan
Oloye Abdul Tawab Olaitan Ile-Aje Adeniyi ni o kopa gẹgẹ bi ''Toromagbe'' ninu fiimu naa, to si jẹ ọkọ fun ''ọwọ otori'' ti wọn gbe ninu aginju.
Tani gbajugbaja òṣèré ''Toromagbe'' nínú fíìmù ''Arelu'' tí jáde láyé
- Gbajugbaja òṣèré ''Toromagbe'' nínú fíìmù ''Arelu'' to jáde láyé jẹ akanda ẹda ti gbogbo eniyan mọ si 'arara'' nitori eniyan kukuru ni.
- Ọmọ bibi ilu Ago Iwoye nipinlẹ Ogun ni Oloye Abdul Tawab Olaitan Ile-Aje Adeniyi.
- Oun si ni ọmọ kẹrin ti iya rẹ bi ninu awọn mẹfa ti iya rẹ bi ninu ile olorogun, ti iya rẹ ti jẹ iyawo akọkọ.
- Bi o tilẹ jẹ pe akanda ẹda ni nitori ko ga rara, o sọ ninu ifrọwanilẹnuwo kan pe gbogbo awọn aburo ati ẹgbọn oun lo jẹ eniyan to ga to fi mọ baba ati iya oun.
- Oloye Abdul Tawab Olaitan Ile-Aje Adeniyi pe ara rẹ ni araye-rọrun nitori iji gbe e lọ fun ọjọ mẹrinla lasiko ti wọn n ṣe fiimu ''Arelu'', ti o ni oun si le sọ nipa igbeaye eniyan nipa wiwo ọwọ rẹ.
- O kopa ninu fiimu Orunmoru, Are Agbaye, Mosebolatan, Agbarun, ti Baba Sala ṣe ati Arelu ti Jimoh Aliu gbe jade ni ọdun 1986.
- Iyawo mẹta ati ọpọlọpọ ọmọ lo gbẹyin rẹ.








