Solar Power Naija: Ṣe lóòtọ́ ní ọmọ Nàíjíríà mílíọ́nù 25 yóò má ló ìná Solar látí Dec 1, 2020?

Oríṣun àwòrán, Google
Ijọba apapọ lorilẹede Naijria ti kede pe awọn ọmọ Naijiria to to miliọnu marundinlọgbọn ni yoo jẹ anfaani ina ọba ti oorun n pese, iyen Solar Power.
Ninu atẹjade ti oluranlọwọ pataki fun aarẹ Buhari, Laolu Akande fi lede ni Ọjọ Kini, Oṣu Kejila, ọdun 2020 ni wọn yo bẹrẹ si ni lo awọn ina Solar naa.
Ijọba fikun pe awọn ti yoo jẹ anfaani naa ni awọn to wa ni igberiko abi awọn ilu nla ti ko jẹ anfaani ina ọba ni agbegbe wọn.
- 110 ni ìyè àwọn àgbẹ̀ tí Boko haram dúmbú ní Borno tí dì báyìí-UN
- Bí mo bá leè rí ọmọ alágbe t'áyé fẹnu sí pé mo fi ẹlẹ́rìndòdò lá lójú, máa kúnlẹ bẹ ẹ - Motara
- Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọba tó kọ ifá sílẹ̀ gbé Bíbélì àti Kùránì
- Èèyàn 82 tún ti ní COVID-19 ní Nàìjíríà
- Ẹ wo ìdí tí Oby Ezekwesili ṣe ń pè fún àyẹ̀wò ọpọlọ fún Ààrẹ Buhari
Bakan naa ni ijọba ni awọn eniyan yii yoo ma a san ẹgbẹrun mẹrin loṣooṣu fun ọ̀dun mẹta ti wọn yoo fi san owo naa tan.
Ko tan si bẹẹ o, awọn eniyan naa ni anfaani lati ma a san ẹgbẹrun kan abo ni osoosẹ lati le tete san owo ina solar naa tan ni kiakia
'' Ẹka Rural Electrification Agency ni ileeṣẹ ijọba to n risi ina ọba lo ṣe olugbọwọ ipese ina ọba Solar naa.
'' A gba owo lọwọ Banki apapọ lorilẹede Naijiria , CBN lati le ṣe igbese ina Solar naa fun awọn Niajiria''
- Bí mo bá leè rí ọmọ alágbe t'áyé fẹnu sí pé mo fi ẹlẹ́rìndòdò lá lójú, máa kúnlẹ bẹ ẹ - Motara
- N81m pọ̀ lóòtọ́ láti fi gé koríko Stadium, Ọ̀gá Mínísítà,èló lẹẹ́ san fáwa ọ̀dọ́ láti gè e?
- Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọba tó kọ ifá sílẹ̀ gbé Bíbélì àti Kùránì
- Omo Ghetto: Funke Akindele ṣàlàyé bí àwọn agbébọn ṣe kọlù wọn làsíkò tí wọ́n ń ya fíìmù
Laolu Akande ni ipese ina Solar naa yoo pese iṣẹ fun ẹgbẹgbẹrun ọmọ Naijiria ti ko ni iṣẹ.
Ijọba Naijiria ni yoo tun pese iṣẹ fun awọn ti yoo ma fi si awọn ile wọnyii lati ri wi pe o ṣiṣẹ doju ami.
Amọ, gbogbo igbiyanju wa lati ba ẹka Rural Electrification Agency sọrọ lori awọn agbegbe ti yoo kọkọ jẹ anfaani yii ni ko i tii kẹsẹjari nitori a ko ri ẹka naa basọrọ lori ẹrọ iabnisọrọ wọn.












