Obateru Akinruntan: Olugbo Obateru akinruntan ṣalaye ìdí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láàrín òhun àti Ooni Ile Ife

ooni, Oba ilu Eko ati Oba Olugbo

Oríṣun àwòrán, Twitter/Obatakinruntan

Olugbo ti ilu Ugbo, Ọba Frederick Ọbatẹru Akinruntan ti ṣalaye ohun to n ṣẹlẹ laarin oun ati Ọọni ile ifẹ.

Olugbo ni awọn eeyan ti oye ko ye lo n ro pe aawọ wa laarin oun ati Ọọni ile Ifẹ. Gẹgẹ bi ọrọ rẹ ọmọ iya loun ati Ọọni jẹ.

O ni ohun ti oun ṣi n tẹnumọ ni pe awọn eeyan Ugbo lo ni ifẹ ti wọn si ti tẹdo sibẹ ki Oduduwa atẹwọnrọ to de lati tẹdo sibẹ.

Ọba Akinruntan sọ ọrọ yii di mimọ lasiko to fi n ṣe ajọyọ ayẹyẹ ọdun kọkanla ti o n lo lori itẹ gẹgẹ bii Olugbo ti ilu Ugbo.

O ni Ọbamakin Ọsangangan to jẹ Ọọni akọkọ ni iran baba nla oun ati pe ileto mẹtala ni baba oun ti ni ni ile iIfẹ ki Oduduwa to de.

Bakan naa lori ọrọ abo lorilẹede Naijiria, Kabiyesi naa pe fun idasilẹ Ọlọpaa agbegbe. O ni bi awọn fijilante ba darapọ ṣiṣẹ pẹlawọn ọlọpaa, eto abo to mẹhẹ lorilẹede Naijiria a duro deede.