Sunday Igboho Health Condition: Ààrẹ Talon, a fẹ́ kí ẹ pàṣẹ ìtúsílẹ Igboho kí o ba à lè rí ìtọjú gbà- Koiki

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Asiwaju Igbimọ Yoruba lagbaye, Yoruba World Congress,Ọjọgbọn Banji Akintoye ti ni kawọn alatilẹyin idasilẹ Yoruba Nation fọkan balẹ lori idande Sunday Igboho.

Sunday Adeyemo Igboho to jẹ ọkan gbogi ninu awọn to n ja fun ẹtọ Yoruba wa ni ahamọ awọn agbofinro ni orileede Benin.

O ti to ọjọ mẹta to wa nibẹ ti awọn to sunmọ si n paya lori ipo ti alaafia rẹ wa.

Ninu fọnran fidio kan ni alagba Naji Akintoye ti n ba awọn eeyan sọrọ loju opo Instagram pe awọn tawọn jẹ Baba fun Igboho ko da Igboho da bukata ara rẹ ni Benin.

''Awa taa jẹ Baba rẹ, a ko kuro nibi. Laipẹ yi ni ọrọ yoo niyanju''.

Àkọlé fídíò, Samuel Oluwafemi sọ bí Covid 19 ṣe bí ìdíje oníjó àti eré fún àwọn Odi àti Adití sí rere

Ọjọgbọn Banji Akintoye sọ pe idaduro to n waye ko ṣẹyin bi awọn adajọ orileede Benin ṣe maa n gba isinmi lọdọọdun eyi to fa ti wọn ko fi tete yanju ọrọ Sunday Igboho.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

O tẹsiwaju pe lọjọ Iṣẹgun to kọja ni wọn gbe Sunday Igboho lọ si ile ẹjọ lẹyin tawọn adajọ wọle pada sẹnu iṣẹ.

Agbaọjẹ ajafẹtọmọniyan yi dupẹ lọwọ awọn alatilẹyin Igboho to si ni ''asiko ti to ki awa Yoruba kuro ni orileede Naijiria ki a si ni orileede tiwa.''

Igboho

Oríṣun àwòrán, others

Ipo wo ni Sunday Igboho wa paapa nipa alaafia rẹ

BBC ko ribi fidi ọrọ mulẹ nipa ipo alaafia Sunday Igboho ju nkan ti agbẹnusọ rẹ Olayomi Koiki fi sita ninu atẹjade kan.

Akori atẹjade naa to wa loju opo Instagram rẹ lede Gẹẹsi ati Faranse ni pe Oloye Sunday Igboho nilo itọju kiakia.

Koiki sọ pe awọn fẹ ki aarẹ orileede Benin Patrice Talon lo ipo rẹ lati seto itọju Sunday Igboho nitori ailera rẹ.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

Koiki ko sọ ibi to ti fẹ ko gba itọju tabi iru ailera to n ba Sunday Igboho ṣugbọn o ni ko ni da a to ki nkan ṣẹlẹ si Igboho lakata ijọba Benin to wa.

''Aarẹ Talon, ẹ jọwọ ẹ bawa fẹnu si ọrọ ki wọn baa le tu Igboho silẹ nitori ilera rẹ nilo itọju kiakia''

Àkọlé fídíò, Africa Eye wádii àwọn tó wà nídìí ìgbésùmọ̀mí ni Mozambique

''A mọ pe ẹ lagbara lati ṣe nitori a ko fẹ ki nkankan ṣẹlẹ si lasiko to wa labẹ ahamọ lorileede yin''

Lati ogunjọ oṣu Keje ni Oloye Sunday Adeyemo Igboho ti wa ni ahamọ lorileede Benin.

Àkọlé fídíò, Ebun Oloyede Olaiya Igwe sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí lásìkò àìsàn kídìnrín tó yọ ọ́ lẹ́nu