Electricity Blackout IBEDC: Òṣìṣẹ́ tó sọ ìlú s'ókùnkùn àìsíná ọba fojú kó ẹbọ ní Magboro, Ìpínlẹ̀ Ogun

Ina

Oríṣun àwòrán, others

Àwọn olugbe ilu Magboro, ilu Makogi, ilu Oke-Afa, ilu Ibafo, ilu Orimerimun ni ijọba ìbílẹ̀ Obafemi Owode ni Ipinle Ogun ti wa ninu okunkun birimu lati ile ise to n pín iná ọba ni Ibadan (IBEDC).

Ṣaadede ni iroyin sọ pe àwọn ará ilu kan ti ẹni kankan ko tii mọ wọn lọ gbe ẹbọ síbi òpó iná ti wọn ti maa n tan tabi pa ina ti wọn si tun so ẹ̀wọ̀n ìrìn mọ irinṣẹ wọn.

Lẹyin ti ìròyìn jade ni wọn ja iná wọn, pe nitori àwọn araalu kan gbé awọn nkan etutu síbi ti ileese apinna ti maa n tan tabi pa ina ni agbegbe Magboro.

Ẹbọ Oríta: Àwọn òṣìṣẹ́ iná ọba, IBEDC fojú kó ẹbọ ní Magboro torí àìsí iná

Adari igbimọ ìlú Magboro lórí ọrọ iná Ọba, Moses Omoniyi ni ko si ẹni to dá wọn mọ.

O ni bí wọn ṣe máa ń fun awọn ni iná ni pé bí wọn ba ti fa ojuko ibi tí wọn ti ń tàn an sókè, Iná yóò wà, bí wọn ba si ti faa wá silẹ, kò ní sí iná.

esu

Ẹwẹ, "lọtẹ yìí, nkan naa wa lókè wọn ni iná, làwọn kan bá lọ gbe ẹbọ síbẹ̀ ni ọjọ Satide, wọn si tun so ẹ̀wọ̀n irin mọ ọ.

Láti ìgbà náà, kò si ẹni tó lè lọ faa wá silẹ torí ao mọ ẹni tó gbé ẹbọ síbẹ̀".

Àkọlé fídíò, Ẹni tó bá ni kí n fi iṣẹ́ kòkò mímọ sílẹ̀, mi ò lè fẹ́ẹ láéláé - Adekemi Àgùnbánirọ̀

Kété tí ileese to n pín iná ọba rii pe wọn kò lè fà irinse a una wá náà silẹ kí iná wọn le lọ ní wọn pàṣẹ pé kí wọn pa gbogbo iná ìlú Magboro, Makogi, Oke-Afa, Ibafo1, Ibafo2 àti Orimerimun patapata láti Oke -Aro bẹẹ si ni gbogbo ileese to n fi iná ọba ṣiṣẹ́ kò rí iná lo lati igba naa.

Àkọlé fídíò, Nàìjíríà kàn wà ni, ẹ ò páàsì, ẹ ò féèlì, ẹ ò kúrò ní kíláàsì kan náà - Àwọn ọ̀dọ́

"Taa bá mọ àwọn tó gbe ẹbọ síbẹ̀, a máa ní láti bẹ wọn ni lati lọ gbee kúrò ká lè rí ọna àbáyọ".

Ẹbọ ati ina ọba

Ó ní òun gbagbọ pé àwọn lọba lọba ìlú náà tí ń gbé igbese láti mọ awọn tó gbe ẹbọ síbẹ̀

Àkọlé fídíò, Ọ̀ṣọ́ Aṣọ Òkè ti kọjá lílo ìlẹ̀kẹ̀ níkan

Ara ilu míì ni "ṣe ẹ lè gbagbọ pé a ní iná wákàtí mẹ́jọ péré fún ọjọ́ mẹta gbáko? IBEDC ń fi wá ṣeré nìyẹn. Ìgbà tí àwọn ọdọ pinu pé a ó ní san owó iná tí a kò lo, awọn àgbà kan tún lọ ń ṣàn owó lẹyin wá. Àwọn òní iná náà tí gba abẹtẹlẹ wọn ò sì jẹ ká rí ọna àbáyọ".

Àkọlé fídíò, 'Ìyà Muinat kú nígbà tó ń mu ọmú lọ́wọ́ ni èmí ìyà-ìyá rẹ̀ ń tọ́jú rẹ̀ kí ògiri kíláàsì tó wó pa á'

Ó ní ìdí nìyí tí wọn fi ń sọ pé àwọn ọdọ lo n da omi alafia ìlú ru.

Titi di asiko ti a ko ìròyìn yìí jọ, wọn ò tíì ri ọna àbáyọ.

Àkọlé fídíò, Adepoju Abdulsalamm ẹni ọdun 18 tó n fi kẹ̀kẹ́ dára fi kiri ẹja tó fi n tà wàràwàrà