Dubai drone rain: UAE lo 'drone' láti fi fòpin sí ooru tó mú púpọ̀ ní Dubai

Dubai

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oirle-ede United Arab Emirate n seto ọna lati mu òjò rọ lọna atọwọda.

Wọn n lo ẹrọ to n fo loju ofurufu ti awọn oloyinbo n pe ni "Drone"

Diroonu yii lo n lo ina mọnamọna lati fi fọ oju ikuuku lati fi rọ ojo atọwọda silẹ.

Ooru to le ni 122 degrees Fahrenheit ti o tumọ si 50 degree Celsius ni wọn n koju ni Dubai.

Ọna lati wa ojutu si isoro ooru to mu ju yii lo fa igbesẹ awọn akọsẹmọsẹ lorile-ede UAE naa.

UAE jẹ ọkana lara orilẹ-ede agbaye ti ooru n mu ju.

Eyi jẹ ki wọn pinnu lati maa se ojo wọn funra wọn.

Afihan fọnran fidio ti ajọ to n ri si ayipada oju ọjọ n i UAE fi sita ni ọpa ti gboriyin fun isẹ ọpọlọ naa.

Ajọ National Center of Meteorlogy ni Dubai ni lo gbe fọnran fidio naa to fi diroonu to n fọ ikuuku naa han ti ojo si n da lati arun silẹ lai naa ni ooru to mu lasiko ọhun.

Àkọlé fídíò, Ilorin Cripple Couple: Ọṣẹ ìfabọ́ ni tọkọ-taya tó ní ìpèníjà ẹsẹ̀ ń tà láti bọ́ ọmọ mẹ́ta

Aọ NCM yii salaye nipa igbesẹ to jẹ ki eyi seese ni Dubai ati iye owo ti wọn na lati rii pe ojo pada rọ nibẹ.

Ojogbon Maarten Ambum to sisẹ lori isẹ akanse naa salaye fun BBC pe orilẹ-ede UAE ni ikuuku oju ọjọ to to lati lo ina mọnamọna fi rọ ojo silẹ.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ladoja ní bí ìjọba kò bá fi ẹ̀lẹ̀ ṣe, ọ̀pọ̀ ajìjàgbara míì yóò dìde

Alya Al-Mazroui, to je adari ikọ oluwadii isẹ akanse naa ni awọn diroonu yii lo n fọn omi ojo naa kaakiri Dubai.

Lati ọdun 2017 ni UAE ti n gbe milionu dola meedogun kalẹ fun isẹ iwadii to le mu ojo rọ lasiko kalẹ.