Osun Couple Death: Tọkọ-taya kú lẹ́yìn tí wọ́n jẹun tán ní Ọjọ́ Àyájọ́ Ọ̀mìnira Nàíjíríà

Osun

Oríṣun àwòrán, Instagram

Idarudapo ṣẹlẹ ni agbegbe Ireti Ayo ni opopona Ijebu-Jesa lẹyin ti wọn ri oku tọkọ-taya kan ninu ile wọn lẹyin ti wọn jẹun tan.

Iroyin gbe e pe iṣẹlẹ ọhun waye ni Ọjọ Kini, Oṣu Kẹwaa, ọdun 2021 lasiko ayẹyẹ Ayajọ Ọjọ ti Naijiria gba ominira ni ọdun 1960.

Olugbe agbegbe naa to ba awọn oniroyin sọrọ ni o ṣeeṣe ko jẹ majele lo pa awọn tọkọ-taya to di ọlọgbe naa.

''Nitori ori tabili ti wọn ti jẹun tan ni wọn ti ba oku wọn, ti ko si si ẹni to le e sọ pato ohun to ṣẹlẹ si wọn.

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun gba ẹnu agbẹnusọ wọn, SP Yemisi Opalola fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ pe lootọ ni iṣẹlẹ naa waye.

Àkọlé fídíò, Adeyemi Olubunmi Crown: Láti ìgbà ti mo ti fún ọkọ mi ni ẹ̀bùn mọ́tò ni ìfẹ́ wa ti yàtọ̀

Yemisi Opalola ni ''lootọ ni a ba ọku arakunrin Olasunkanmi Eso to jẹ ẹni ọdun marundinlọgọta ati oku iyawo rẹ, Fisayo Eso, to jẹ ẹni aadọta ọdun ninu ile wọn ni ọjọ ayajọ ominira orilẹede Naijiria, ni Ọjọ Kini, Osu Kẹwaa.''

Àkọlé fídíò, Africa Eye wádii àwọn tó wà nídìí ìgbésùmọ̀mí ni Mozambique

''Bi o tilẹ jẹpe a ko tii fi idi rẹ mulẹ iru iku to pa mọ, amọ iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹwu lori iṣẹlẹ naa.''

''Amọ ohun ti a ri nigba ti a de be ni pe oorun ẹrọ agbenawa gẹnẹratọ pọ ninu ile naa, ti eniyan le sọ wi pe ẹrọ gẹnẹratọ naa ṣokunfa iku wọn.''

''A n ṣewadii ohun to fa iku wọn, ti a o si gbe iwadii jade laipẹ nitori a ti gbe wọn lọ si ile igbokusi lati mọ iru iku to pa wọn.''

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa naa rọ awọn eniyan lati gba alaafia laaye lori iṣẹlẹ nitori awọn yoo ri pe gbogbo ohun to ṣokunkun nipa iṣẹlẹ naa ni wọn tan imọlẹ si.

Àkọlé fídíò, Samuel Oluwafemi sọ bí Covid 19 ṣe bí ìdíje oníjó àti eré fún àwọn Odi àti Adití sí rere