EFCC Board Screening: Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin yan ẹ̀ní tó tí bẹ̀rẹ̀ ilélkọ́ kí wọ́n tó dé ilé ayé gẹ̀gẹ̀ bí ìgbìmọ̀ EFCC

Ile Aṣofin

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ile Igbimọ Aṣofin Agba ti buwọlu arakunrin Yahaya Mohammad lati ipinlẹ Yobe gẹgẹ bi ọkan lara awọn igbimọ Ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ibajẹ ati jẹgudujẹra ni Naijiria.

Amọ, lasiko ti ile igbimọ aṣofin agba naa n ṣe ayẹwo awọn iwe ẹri rẹ ni wọn ri i pe o ti bẹrẹ ileẹ̀kọ́ ki wọn to bi i si aye nipa ọjọ ori to fi silẹ̀.

Sẹnetọ to fi aṣiṣe to wa ninu ẹri rẹ naa han ni ṣẹnatọ to n soju agbegbe iha ariwa ipinlẹ Jigawa, Hassan Hadeija.

Hadeija lasiko ijoko ile ni asiko ti Muhammad lọ si ileẹ̀kọ́ saaju igba ti wọn bi nitori ọdun 1969 ni wọn bii gẹgẹ bi iwe ẹri rẹ ṣe ṣọ, to si bẹrẹ ileẹkọ alakọbẹrẹ ni ọdun 1968.

''Oun ti mo ri ninu iwe ẹri arakunrin Muhammad ni pe Muhammad ti bẹrẹ ileewe rẹ ki wọn to bii eleyii ko bojumu.

Àkọlé fídíò, Samuel Oluwafemi sọ bí Covid 19 ṣe bí ìdíje oníjó àti eré fún àwọn Odi àti Adití sí rere

Ọjọ Kọkandinlọgbọn, Oṣu Kẹsan an, ọdun 1969 ni wọn bi amọ o bẹrẹ ileẹkọ alakọbẹrẹ Central Primary School ni ọdun 1968.

Bakan naa ni iwe ẹri rẹ fihan pe o lọ si ileewe giga meji lẹẹkan naa, eleyii ti yoo nira lati ṣe lasiko naa.

Nigeria anti-corruption officials

Oríṣun àwòrán, EFCC

Iwe ẹri rẹ ni o lọ si ileẹkọ Borno Teachers' College ni ọdun 1975 si ọdun 1988, to si tun lọ si ileẹkọ College of Administration ni ọdun 1980 si ọdun 1981.

Àkọlé fídíò, Adepoju Abdulsalamm ẹni ọdun 18 tó n fi kẹ̀kẹ́ dára fi kiri ẹja tó fi n tà wàràwàrà

Ti eleyii ba jẹ aṣiṣe afi ọwọ kọ, ki wọn tete ṣe atunṣe ki o le wa ni akọsilẹ to dara.

Amọ, Alaga igbimọ to ṣe ayẹwọ awọn ti wọn yan si igbimọ ajọ EFCC naa,Suleiman Abdu Kwari ni ki wọn yan an nitori o kunjuwọn.

Sẹnetọ Kwari ni Mohammad ko ni ẹsun iwa ibajẹ kankan ti ẹnikẹni le tọka si.

Ile Igbimọ Aṣofin ko gbiyanju lati ṣe atunṣe awọn aṣemaṣe to wa ninu iwe ẹri rẹ ki wọn to buwọlu gẹgẹ bi ọkan lara awọn igbimọ Ajo EFCC.

Àkọlé fídíò, Àwọn ọkùnrin tó wà nínú ayé wa gbúdọ̀ bọ̀wọ̀ fún wa - Adarí FIN

Muhammad wa lati ipinlẹ Yobe kan naa pẹlu aarẹ ile igbimo Asofin, Ahmad Lawan.

Àkọlé fídíò, Ebun Oloyede Olaiya Igwe sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí lásìkò àìsàn kídìnrín tó yọ ọ́ lẹ́nu