Sunday Igboho: Ìkà t'éèyàn fí inú hàn lẹ́ni tó gbé "audio" síta pé Igboho ní mí ò yẹ òun wò lẹ́wọ̀n - Salami

Igboho

Oríṣun àwòrán, @Sunday Igboho

Agbẹjọro Oloye Sunday Igboho to n gba ẹjọ rẹ ro ni orilẹede Benin Republic bá BBC Yoruba sọrọ lati yanana rẹ boya lootọ ni ara rẹ ko ya gẹgẹ bi awọn iwe iroyin ṣe sọ.

"Lootọ ara Oloye Sunday Igboho ko ya, nigba ti wọ́n gbogun tii ni Naijiria ti o bọ lọwọ awọn onijamba, o farapa ni ọwọ ọtun rẹ́".

Ipò tó le gidi ní Oloye Sunday Igboho wà báyìí lóòtọ́ tó sì nílò kó lọ sí Germany - Salami

Agbẹjọro Ibrahim Salami ṣalaye pe Igboho fẹrẹ ku amọ toripe o jẹ ọkunrin Akin gidi ni, tori naa lo fi ni o nilo dokita ti yoo tọju rẹ daadaa.

Oloye Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Koiki Media

Orilẹede Germany ni Sunday Igboho ti n fẹ ki wọn gba a laye lati lọ gba itọju.

Agbẹjọro Salami ṣalaye pe idi ti ko fi fẹ gba itọju ni Cotonou ni wi pe Naijiria lo ti kuro to si n gba France kọja lọ si Germany nigba ti wọn fi ọwọ ofin muu tori naa Germany ọhun naa lo ti fẹ lọ gba itọju, wọn.

Àkọlé fídíò, Ṣé ìwọ mọ̀ pé Olodumare lè lo Aje láti gbé ẹ lọ síbi ire?- Abiodun Fatomilola

O le muu ni dandan ko lọ ile iwosan Cotonou.

"Ohun to n fẹ naa ni pe ki idajọ ododo waye, ki wọn fii silẹ ki wọn si gbaa laye lati lọ gba itọju ni Germany".

Salami ṣalaye pe nigba ti adajọ agba orilẹede Benin rii, o daa loju pe tori ọrọ abo ni wọn fi daa duro ko ma lọ to si fi da awọn loju nigba naa pe wọn yoo to gbaa laye lati lọ amọ Salami ni o ti n pẹ.

Agbẹjọro naa mẹnu baa pe ki eeyan to kẹnu bọ ọ̀rọ̀ ofin, o gbudọ mọ nipa rẹ daadaa, o ni tori bi wọn ṣe n ṣe ofin ni Benin yatọ si ti Naijiria.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Femi Falani ní ẹjọ́ Igboho ní Cotonou ń kọ́ àwọn amòfin Nàíjíríà ní ẹ̀kọ́

"Akọkọ ti ọna ofin tiwa fi yatọ ni pe ile ẹjọ ti wọn gbe Sunday Igboho si, ile ẹjọ iwadii ni, o dẹ maa n pẹ, ti adajọ ba ṣe iwadii tirẹ tan ni a ṣẹ fi ṣọwọ si adajọ agba ti yoo wa sọ boya ki wọn fii lẹ ni ẹwọn, adajọ yẹn si wa ni asiko isinmi tirẹ ni ko pẹ ti wọn mu Sunday Igboho tori o wa ninu ofin wa".

O ni eyi lo mu ki awọn ọgbẹri kan maa sọ pe fun oṣu kan adajọ naa ko ṣe nkankan. "Awa o le ṣalaye gbogbo rẹ fun awọn to n gbọ wa".

Salami ni awọn mọ pe niwọn igba ti awọn eeyan ko ba tii ri ki Sunday Igboho jade, wọn a ni awọn o ṣiṣẹ kankan ni "amọ mo lee sọ fun yin pe koda a n ṣe ju iṣẹ lọ".

Nigba ti akọroyin BBC Yoruba bere lori rẹkọọdu ọrọ kan to jade ninu eyi to jọ pe Sunday Igboho n sọ fun oniroyin naa pe agbẹjọro oun ko wa wo oun bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ, Agbẹjọro Sunday Igboho ni ọrọ yẹn bi wahala silẹ ni awujọ Yoruba.

oloy

Oríṣun àwòrán, Koiki Media

"Ohun to ṣẹlẹ ni pe ki Ọlọhun ma jẹ ka fi inu wa han fun ika ni toripe ẹni ti a ni ko yọ nkan loju fun eeyan to tun wa n ṣe aburu fun eeyan ni".

Lootọ, ahọn pẹlu eyin maa n ja. Nigba ti mo lọ wo Oloye Sunday Igboho ni ẹwọn, o dabii pe wọn o tete sọ fun wọn torinaa o pẹ diẹ ki wọn to jade si mi, eeyan kan to jẹ bi ọrẹ lo ṣi ọrọ gbọ to gbee jade".

Àkọlé fídíò, Adeyemi Olubunmi Crown: Láti ìgbà ti mo ti fún ọkọ mi ni ẹ̀bùn mọ́tò ni ìfẹ́ wa ti yàtọ̀

Agbẹ́jọro Salami ni labẹ ofin, ẹni naa ru ofin gidi gan, "lakọkọ o ba Oloye Adekunle to sunmọ Oloye Igboho sọrọ tori o mọ pe ati Oloye Adekunle ati emi lo ṣee gbagbọ lori ọrọ Sunday Igboho. O tun ru ofin ikeji nipa biba Oloye Igboho funra rẹ sọrọ, ikẹta o tun ba emi agbẹjọro gan sọrọ o si tan an ka ori ayelujara".

O ni igba to wa gbee saye ti awọn mii n bu awọn ti awọn mii n ṣẹ epe. "Mo ti kọ ẹkọ kan lọdọ iya mi pe, ẹni ti ko ba huwa epe, epe ko ni muu, ẹni ti wọn ba si gbadura fun un... tọ̀ọ̀ọ̀". "Niwaju Ọlọrun to da aye ati ọrun, emi mọ pe mi o dalẹ Sunday Igboho".

Salami ni ni ikẹyin ẹnu oun ati Sunday Igboho tun ti wa ko gaan "koda ẹ o le wọ aarin wa".

"Lónìí olónìí, èmi àti Olóyè Sunday Igboho rí ara wa, a sọ̀rọ̀ ọmọ Yorùbá to sí tún wá fi ọ̀kan tán mi gan, a si ti gba pe awọn to n ṣẹ epe ki epe jẹ tiwọn awn to si n gbadura, ki adura maa ba wọn".

Àkọlé fídíò, Samuel Oluwafemi sọ bí Covid 19 ṣe bí ìdíje oníjó àti eré fún àwọn Odi àti Adití sí rere

Esi si ọrọ aarẹ Buhari pe awọn oloṣelu Naijiria kan lo n ṣe agbatẹru Sunday Igboho ati Nnamdi Kanu

"Ninu gbogbo awọn agbẹjọro to n gbẹjọ Sunday Igboho ro, o fun emi laye lati maa gba ẹnu sọrọ fun ohun".

Salami ni oun rii pe nkan ti aarẹ Buhari sọ dabii ki wọn fẹ maa ba eeeyan jẹ ni awọn si ti sọ fun ijọ Yoruba ni apapọ agba ye pe ki wọn ṣe suuru pe laipẹ otitọ yoo jade ti gbogbo nkan to ṣẹlẹ to ru eeyan loju pata ni oun yoo tu aṣiri si wọn lọwọ.

Àkọlé fídíò, Àwọn ọkùnrin tó wà nínú ayé wa gbúdọ̀ bọ̀wọ̀ fún wa - Adarí FIN

"Boo lo ṣe maa n ri lara wọn gan ki wọn maa fi Sunday Igboho we ọkunrin ọmọ Igbo ti wọn mu ni Kenya, eeyan nla Yoruba ni Sunday Igboho eeyan bii rẹ si ṣọwọn ninu itan Naijiria koda eeyan bii meji pere la le fi we Igboho - Oloye Awolowo ati Oloye MKO Abiola.

"Igboho ni Ọlọrun yan lati ja ija Yoruba ni Naijiria torinaa ni ko ṣe si ẹni ti wọn le fi we lasiko yii.

Àkọlé fídíò, Ọ̀ṣọ́ Aṣọ Òkè ti kọjá lílo ìlẹ̀kẹ̀ níkan

Ṣe Femi Fani-Kayode ti kan si Igboho lati igba to darapọ mọ ẹgbẹ Oṣelu APC?

Laipẹ yii ni ọpọ eeyan n gbe fọto Sunday Igboho ati Minisita irina ofurufu tẹlẹ Femi Fani-Kayode sita lati ranti bi o ṣe maa n ja fitafita fun Igboho

To maa n sọ oko ọrọ si aarẹ Buhari.

Àkọlé fídíò, Ebun Oloyede Olaiya Igwe sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí lásìkò àìsàn kídìnrín tó yọ ọ́ lẹ́nu

Amọ niwọn igba to ti lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu to wa lori alefa bayii, APC to si ti n fọnrere aarẹ́, awọn eeyan ni o ti dalẹ Igboho pe o si le ti maa fa jamba fun un tipẹ ti Igboho ko mọ.

Agbẹjọro fun Sunday Igboho ni esi nipa Fani-Kayode kii ṣe ohun ti onibara oun Sunday Igboho gba oun laye lati sọrọ nipa rẹ.

"To fi mọ eyi ati ohun ti iran Yoruba yoo ṣe nigba idibo ọdun 2023, Oloye Sunday Igboho ni bi oun ba jade, gbogbo rẹ ni oun yoo sọ.

Njẹ ilera Sunday Igboho lee gbee di igba ti yoo kuro ni ẹwọn?

Agbẹjọro Salami ni nkan to le ni eyi o to si nilo ki wọn ṣe itọju fun un. O ni o wa ninu ofin orilẹede Cotonou pe wọn ko gbudọ fi ipa mu eeyan lati ṣe itọju ara rẹ ni orilẹede wọn.

Àkọlé fídíò, Ẹni tó bá ni kí n fi iṣẹ́ kòkò mímọ sílẹ̀, mi ò lè fẹ́ẹ láéláé - Adekemi Àgùnbánirọ̀

Abi ijọba Benin ti gba ibọde ni?

Agbẹjọro Salami ni oun mọ o si da oun loju pe ijọba Benin ko gba ibọde kii sii ṣe ni akoko yii ni wọn yoo gba ibọde.

"Mo gbagbọ pe titori aabo Igboho funrarẹ ni wọn ko ṣe tii jẹ ko lọ".

Àkọlé fídíò, Nàìjíríà kàn wà ni, ẹ ò páàsì, ẹ ò féèlì, ẹ ò kúrò ní kíláàsì kan náà - Àwọn ọ̀dọ́

Agbẹjọro Salami tun ni orilẹede Naijiria ko tilẹ beere fun pe ki ijọba Benin gbe Sunday Igboho ranṣẹ si awọn ni ọna to tọ to si ni bi wọn ba tilẹ wa ṣẹṣẹ ṣee lọna to tọ, ko ni ṣeeṣe lọdọ awọn tori oun gẹgẹ bi agbẹjọro rẹ ti fi ofin beere fun ki wọn jẹ ki o sapamọ fun ewu lorilẹede awọn.

Àkọlé fídíò, Adepoju Abdulsalamm ẹni ọdun 18 tó n fi kẹ̀kẹ́ dára fi kiri ẹja tó fi n tà wàràwàrà

"A rii pe wọn n gbogun ti Sunday Igboho ni Naijiria ti awọn agbẹjọro rẹ si n bori amọ ìjọba ṣi n ranṣẹ si Benin pe ki wọn jọwọ Sunday fun awọn".

Salami n fi gbogbo ọmọ Yoruba lọkan balẹ pe ki wọn ṣe suuru toripe awọn ti sun mọ ibi ti awọn fẹ de amọ oun ko le sọọ koda bi oun ba mọ nitori aṣiri lo jẹ fun Sunday Igboho. O tun fi n da awọn eeyan loju pe alafia ni iyawo Sunday Igboho wa "amọ mi o le sọ ibi ti o wa fun yin".

Àkọlé fídíò, Africa Eye wádii àwọn tó wà nídìí ìgbésùmọ̀mí ni Mozambique