N6.25trn deficit: Àwọn onímọ̀ ètò ọrọ̀ ajé ní kí ilé aṣòfin takò owóyàá tí ìjọba fẹ fí ṣètò ìṣúná ọdún 2022

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmad
Ẹgbẹ awọn to n pese oun elo,Manufacturers Association of Nigeria, ati awọn onimọ eto ọrọ aje ti n sọ ero ọkan wọn nipa gbese ti ijọba fẹ gba lati le ṣeto isuna ọdun 2022.
Lara awọn to tako igbesẹ yi to ba ileeṣẹ iroyin Naijiria Punch sọrọ la ti ri gbajugbaja onimọ eto ọrọ aje,Pat Utomi.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo ti wọn ṣe pẹlu awọn akọroyin Naijiria, wọn ni ki ile aṣofin Naijiria tete kesi aarẹ Buhari ko tọwọ ọmọ bọ aṣọ lori ẹyawo to n gbero lati fi ṣeto iṣuna.
Wọn ni bi ko ba ṣe bẹ, o ṣeeṣe ki o sọ ọjọ iwaju Naijria sinu ewu nla.
Lọjọru ni ijọba Naijiria sọ erongba rẹ lati ya owo ti yoo fi ṣeto isuna N16.45tn lọdun 2022.
Gẹgẹ bi ijọba ti ṣe sọ, apapọ owo ti wọn ya ko ti ju ida mejilelogun ninu ida ọgọrun owo ọja ati nkan ti wọn ba pese ni Naijiria lọdun naa.
- Ìdí rè é. tí ọmọ tí kò bá tí pé 18 kò ṣe lè lo ''SIM Card'' mọ́ ní Naijiria...
- Kéére o! Ojú òpó WhatsApp kò ní ṣiṣẹ́ mọ́ lórí àwọn ẹ̀rọ ìléwọ́ yìí láti Nov 1
- Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin yan ẹ̀ní tó tí bẹ̀rẹ̀ iléẹ̀kọ́ kí wọ́n tó bíi sáyé gẹ̀gẹ̀ bí ọmọ ìgbìmọ̀ Àjọ EFCC
- Iléẹjọ́ ti ṣetán lórí ẹjọ́ Omolọla ọlọ́pàá obìnrin tí wọ́n lé lẹ́nu iṣẹ́ nítorí pé o gboyún
- Òpópónà àti afárá 19 níjọba fẹ́ ṣe nínú àbá ìṣúná ọdún 2020
Minisita feto isuna Zainab Ahmed ni o di dandan kawọn maa ya owo lati fi pese ohun amayedẹrun nitori owo to n wọle fun ijọba ko to.
O ni ''bi a ba gbẹkẹle owo to n wọle nikan,bo tilẹjẹ wi pe owo to n wọle n lekun,owo ina ijọba n lekun si ni to fi mọ owo oṣu oṣiṣẹ''.
''Owo gbese ti Naijiria n ya jẹ ohun to n kan awọn eeyan lominu. ṣugbọn bi a ba ṣafiwe iye ti Naijria n ya, ko ti kọja agbara''
Amọ kii ṣe bayi lawọn onimọ bi Pat Utomi tiṣe ri ọrọ yi si.
Utomi to fi igba kan dije ipo aarẹ Naijiria sọ pe ọwọngogo nkan le ma jẹ ki iyatọ kankan wa ti owo isuna ba lekun si.
O ṣalaye pe nkan ti o yẹ ki ijọba ṣe ni ki wọn diowo ina ku ki wọn si wo awọn ọna miran lati fi pa owo wọle si yatọ si eleyi to wa nilẹ.
Ninu alaye ti rẹ, ọjọgbọn Fasiti Olabisi Onabanjo nipa eto ọrọ aje,Sheriffdeen Tella ni ''O yẹ ki ile aṣofin foju sunukun wo alaye ti ijọba gbe kalẹ''
O ni gbese yi ti pọju to si tunmọ si pe ''wọn yoo tẹsiwaju lati maa ya owo si ni.Nkan to ṣe pataki ni ki a mọ bi isuna ti owa nile ba ti ṣe n ṣe si.A le maa le ribi ṣeto isuna yi bo ṣe yẹ''
Ẹwẹ,onimọ mii, Bongo Adi sọ pe iye owo ti ijọba n pa wọle labẹle ṣi kere ati pe ko si iyipada kankan to lamilaka nipa owo ori ti wọn n ri gba.
Lakotan ẹgbẹ awọn to n pese nkan ilo,MAN sọ pe owo isuna N6.25trn ti ijọba n gbero yi n kan awọn lominu.
Ọga agba ẹgbẹ yi Segun Ajayi Kadri ni ''gbese owo taa ya ti wọ wa lọrun,ki a tun fi owo gbese ṣeto owo isuna yo tun da kun wahala to wa nilẹ ni''
O ni gbese kii ṣe nkan to buru ṣugbọn ki wn lo owo naa si ipese ohun amayedẹrun ati igbega eto ọrọ aje ni eyi to ṣoro lati ṣe.
Segun ni ọrọ ku si ọdọ ile aṣofin lati boya wn yoo buwọlu owo ti ijọba fẹ ya yi abi wọn yoo tako.
O rọ awọn aṣofin lati daabo bo ọjọ iwaju orileede Naijiria nitori ojuṣe wọn nilati ṣe agbeyẹwo nkan ti wọn fẹ fi ẹyawo yi ṣe.
- Obìnrin mẹ́rin ni igi Ọdán wó pa ni Oyo kó tó tún dìde padà- Eni tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú ẹ
- Ìyàwó Ganduje ti kúrò lọ́dọ̀ọ́ EFCC, wo ohun tó gbé e lọ síbẹ̀....
- Ọwọ ọlọ́pàá tẹ afurasí ajínigbé tó máa n dibọn bí dírẹ́bà láti jí àwọn arìnrìnàjò gbé
- Ìdí rè é. tí ọmọ tí kò bá tí pé 18 kò ṣe lè lo ''SIM Card'' mọ́ ní Naijiria...
- Àpẹ́rẹ́ àìsàn tó ń fa àrùn jẹjẹrẹ pọ̀ lára àwọn obinrin tó wà ní ìlú Ibadan - Ìwádìí fìhàn


















