NCC: Aṣẹ tuntun ní pé ọmọ Naijiria tí kò bá tí pé 18 kò lè lo ''SIM Card'' mọ́ ní Naijiria...

sim card

Oríṣun àwòrán, Twitter

Ajọ to n risi ọrọ igbohunsafẹfẹ lorilẹede Naijiria, NCC ti fofin de ẹnikẹni ti ko ba ti i pe ọmọ ọdun mejidinlogun lati lọ Sim Card ni Naijiria.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ NCC ṣẹṣẹ fi si oju opo itakun ayelujara wọn ni wọn ti aṣẹ tuntun naa lede.

Ninu atẹjade naa ni wọn ti ni ẹni ọdun mejidinlogun lọ si oke nikan lo le e ni Sim Card ni Naijiria.

Onibara to n seto iforukọsilẹ fun kaadi ipe rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

'' Awọn to n lo Sim Card pẹlu aṣẹ ijọba tunmọ si pe ẹni naa ni lati ti pe tabi kọja ẹni ọdun mejidinlogun.

Amọ ẹnikẹni ti ko ba i tii pe iye ọdun naa to n lo tunmọ si pe wọn rufin ati wi pe wọn ko ni aṣẹ lati lo lorilẹede Naijiria.

Àkọlé fídíò, Samuel Oluwafemi sọ bí Covid 19 ṣe bí ìdíje oníjó àti eré fún àwọn Odi àti Adití sí rere

Ajọ NCC ni awọn gbe igbeṣẹ naa pẹlu aṣẹ ti wọn ni labẹ ofin to de ajọ naa ni abala aadọta ti iwe ofin Nigerian Communications Act,2003.

sim card

Oríṣun àwòrán, Twitter

Wọn fukun un pe igbeṣẹ naa wayẹ lẹyin ijiroro ati agbeyẹwo pẹlu awọn to ṣakoso ajọ naa.

Amọ ninu ipade ti ajọ NCC ṣe pẹlu awọn eniyan ti igbeṣẹ yii kan bii ileeṣẹ igbohunsi afẹfẹ MTN ti wọn n pese SimCard ati awọn ileeṣẹ miran ko fi ara mọ igbeṣẹ yii.

Ninu ọrọ ti wọn, ileeṣẹ MTN ni ki wọn ge iye ori ti wọn fi ofin de naa si ẹni ọdun mẹrinla soke.

Amọ Ajọ NCC ko faramọ ibeere yii, ti wọn si tẹnumọ pe ẹni ọdun mejidinlogun nikan lo laṣẹ ni abẹ ofin lati le gba SIM Card lorilẹede Niajiria.