Nigeria's budget and borrowing: Bí a kò bá yá owó, Nàìjíríà ò bá má bọ́ nínú ìfàsẹ́yìn ọ̀rọ̀ ajé - Mínísítà ètò ìsúná

Zainab Ahmed

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Minisita fun eto isuna, aba isuna ati aato lorilẹede Naijiria, Zainab Ahmed ti tun gboriyin fun bi ijọba ṣe n ya owo.

Minisita ọhun ni ẹyawo ọhun wulo gidi lati yọ Naijiria kuro ninu gbese.

O sọ eyi lọjọ Ẹti nigba ti wọn n ṣe agbeyẹwo itagbangba ati atupalẹ iwe aba eto isuna ọdun 2022.

Minista ni: "Pẹlu iriri ifasẹyin lẹẹmeji, a ti ni lati na ọpọlọpọ owo kuro ninu ifasẹyin ọrọ aje eyi to da kun idagbasoke gbese wa,".

Minisita sọ eyi nilu Abuja lẹyin ọjọ ti aarẹ Buhari gbe aba eto isuna ọdun 2022 lọ siwaju ile igbimọ aṣofin.

Àkọlé fídíò, Ṣé ìwọ mọ̀ pé Olodumare lè lo Aje láti gbé ẹ lọ síbi ire?- Abiodun Fatomilola

O ni ko ṣeeṣe ki jijade ninu ifasẹyin yii yara bẹẹ naa bi kii ba ṣe pe ijọba n ri owo lo paapaa eyi ti awọn gbese owo yiya ṣe iranlọwọ fun.

Ṣaaju akoko yii, minisita naa ti sọ pe owo ti orilẹede Naijiria yoo fi gbọ bukata eto isuna ọdun 2022 eyi to to N6.258 triliọnu amọ nipasẹ ẹyawo tuntun ni yoo jẹ.

Igbesẹ yii mu ki awọn eeyan gbana jẹ kaakiri Naijiria. Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu alatako gan fesi pe igbesẹ naa atawọn ẹyawo mii ti ijọba apapọ n ṣe loriṣiriṣi nilo amojuto.

"Ẹgbẹ oṣelu wa rii gẹgẹ bi iwa aburu pe awọn eeyan to mọ pe awọn ko ni to ọdun meji mọ lati kuro lori aleefa wa n ko gbese jọ bi ẹni n mọ oke gelete.

Àkọlé fídíò, Adeyemi Olubunmi Crown: Láti ìgbà ti mo ti fún ọkọ mi ni ẹ̀bùn mọ́tò ni ìfẹ́ wa ti yàtọ̀

O ni: dipo ti o yẹ ki wọn wa ọna ati mu adikun gbese ti wọn ti ko ba orilẹede.

Egbẹ oṣelu PDP sọ eyi lẹyin ti aarẹ Buhari beere fun ki ile aṣoin buwọlu ẹyawo $4 bilọnu ati #710 miliọnu lati di gbese isuna ti ọdun 2021.

Àkọlé fídíò, Samuel Oluwafemi sọ bí Covid 19 ṣe bí ìdíje oníjó àti eré fún àwọn Odi àti Adití sí rere

Amọ Zainab ti ṣalaye pe ẹyawo gangan lo ti ran ijọba lọwọ lati pese awọn nkan amayedẹrun ki ọrọ aje le gberu sii.

"Yiyawo ṣe pataki lati mu wa ri awọn owo to yẹ na ati lati doko owo fun awọn eniyan", Zainab ṣe afikun yii.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, iṣoro aabo ni Naijiria to n peleke sii yii, ijọba nilo lati ya owo.

Àkọlé fídíò, Ebun Oloyede Olaiya Igwe sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí lásìkò àìsàn kídìnrín tó yọ ọ́ lẹ́nu

"Eyi to tun wa buru jai ni pe ogun ti Naijiria n ba ipenija abo yii ja kii ṣe kekere jakejado orilẹede eyi si ti ko ọpọlọpọ inawo ba rira nkan ijagun".

Minisita tun mẹnu ba bi awọn ọmọ Naijiria ṣe n paya lori owo ti ijọba n ya, o ni "o ṣi wa ni odinwo ohun ti wọn le ya torinaa ki ẹnikẹni ma ṣe bẹru".