Traditional Birth Control: Wò àwọn nkán ìbílẹ̀ tí àwọn obìnrin òde òní fi n fètòsọ́mọbíbí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ki a to lọ jina ninu apilẹkọ yi, a fẹ fi ikilọ kekere yi sita.
Ko si aridaju pe ilana ifetosọmọbibi kankan wa ti kii ja ni kulẹ.
Yala ti oloyinbo ni tabi ti ibilẹ, eeyan le lo ilana ifetosọmọbibi ki o si pada wa loyun to n sa fun.
Ko si ohun ti ko le ṣẹlẹ.
- Ṣé lóòtọ́ ni ìjọba orílẹ̀-èdè Benin ti gba àbọ̀dè lórí ẹjọ́ sunday Igboho?
- Ààrẹ Buhari, wá ọ̀nà míràn látí wá owó fún ètò ìṣúná 2022, ẹ̀yáwó ojojúmọ́ tí pọ̀jù- Ilé Ìgbimọ̀ Aṣòfin
- Wo ohun tó yẹ kí o ṣe sí ojú abẹ́ rẹ, ''vagina'' lẹ́yìn ìbálòpọ̀
- Ojú wa rí tó lásìkò tì a wà ní àhámọ́ ajínigbé, koríko la jẹ fún ọjọ́ 52
- Wò ó ọ̀nà láti mú ara rẹ dé ibi tó ga jùlọ nínú ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ìlànà Tantra
- Bó o bá ń gba ẹnu ní ìbálòpọ̀, wo àìsàn tó o lè kó lójú ara rẹ
- Wo bí o ṣe lè ṣe eré ìdárayá tí yóò fún ọ ní adùn àti okun fún ìbálòpọ̀
- Eré ìfẹ́ di eré ẹkún! Olólùfẹ́ méjì lẹ̀pọ̀ lásìkò tí wọ́n n bá ara wọn sùn nínú adágún odò
Igbagbo Yoruba ati ifetosọmọbibi
Bayi taa ti sọ eyiun ni tan, ka bọ si akori ọrọ wa gan an.
Aṣa awọn Yoruba kun fun orisi ilana ati eto eleyi ti wọn fi n gbọ ipenija eyikeyi to ba de ba wọn lagọ ara.
Lara awọn ipenija yi leleyi to ni ṣe pẹlu ilera awọn obinrin paapa fawọn to ba fẹ fi eto si ọmọ bibi.
Ki awọn obinrin to bẹrẹ si ni lo kọndọọmu,abẹrẹ tabi awọn oogun lati fi feto si ọmọ bibi, awọn iya wa paapa ti wọn ni imọ nipa ewe ati egbo, wọn a maa lo nkan ibilẹ ti wọn naa.
Lara nkan ti wọn maa n lo ni oruka,ẹgba ọwọ, asejẹ ati ilẹkẹ idi lati fi ṣeto ifetosọmọbibi.

Oríṣun àwòrán, nanbyet
Njẹ awọn nkan wọn yi ṣi wa ati pe ṣe wọn tilẹ n ṣiṣẹ bi atijọ?
Awọn alagbo ọmọ kan to fi ilu Osogbo ṣe ibujoko ṣalaye fun ileeṣẹ iwe Iroyin Punch pe awọn nkan wọn yi ṣi wa.
Koda wọn ni awọn obinrin ode iṣẹnyi a maa wa sọdọ awọn lati wa ra a.
Arakunrin Shina Elebuibon to n ta ewe ati egbo ni Osogbo ṣalaye pe ẹgba ọwọ,oruka ati ilẹkẹ idi wa lara awọn nkan tawọn n peelo.
''Lootọ lawọn mii a maa fi awọn ilẹkẹ idi yi ṣe oge ṣugbọn fawọn to ba beere wọn le lo lati feto sọmọ bibi.''
- Ìjọba Nàìjíríà n fẹ́ kí àwọn obìnrin maa fi àláfo sílẹ̀ láàrin ọmọ kan sí kan
- Ǹkan yíwọ́! Obìnrin 200 gbé ìléeṣẹ́ tó ń ṣètò ìfètòsọ́mọbíbí lọ ilé ẹjọ́
- Ìlẹ̀kẹ̀ ìdí mi ló kó mi yọ lọ́wọ́ àwọn afipábánilòpọ̀ ní Lebanon
- Òní ní BBNaija 2021 ń parí, tani yóò fí 90m naira sara rindin?
- Kí ní ọ̀rọ̀ mí tí ẹ mú bẹnu lórí onimọ̀ àyẹ̀wò 'Forensic' tí ilé ẹjọ́ pè kó wá jẹ́rìí- Yomi Fabiyi
Shina Elebuibon ṣalaye pe awọn maa n ṣalaye orisi ilana ifetosọmọbibi fawọn obinrin to ba wa sọdọ awọn.
O ni bi apẹrẹ, pipeelo ilẹkẹ idi ko gba asiko pupọ lati ṣe bẹẹ naa ni ti ẹgba ọwọ.
Elebuibon ni: ''Mo ma ni ki wọn ra awọn ilẹkẹ tabi ẹgba yi wa.Bi a ba ti peelo to yẹ si tan, ẹni naa gbọdọ wọ to ba fẹ ni ibalopọ ki o baa maa fi loyun''
Ọgbẹni Shina tun sọ pe awọn a tun maa lo koro kan ti wọn n pe orukọ rẹ ni iwerejeje tabi oju ologbo.

Oríṣun àwòrán, @nanbyet
Shina Elebuibon ni: ''Bi a ba ti lọ koro yi tan,ma o fi awọn nkan eelo miran si ti obinrin naa yoo si gbe mi.
Iye koro to ba gbe mi ni yoo tọka iye ọdun ti ko fi ni loyun''
Arabinrin Afolabi ti oun naa ṣalaye nipa awọn nkan ibilẹ yi sọ pe tẹlẹ lawọn alakọwe ko fi taratara gba ti wọn ṣugbọn nisin yi, awọn naa ti n lo ti ibilẹ yi.
''Lọwọlọwọ awọn alakọwe,oṣiṣẹ ijọba Kristẹni ati musulumi lo maa n wa si ọdọ wa.Ohun to jẹ ki wọn maa wa ni pe pupọ lo jẹri si pe awọn nkan wọn yi n ṣiṣẹ daada.''
Ninu alaye tawọn elewe ọmọ yi ṣe wọn ni awọn le fọwọ rẹ sọya pe awọn nkan wọn yi a maa jẹ bi idan.
Botilẹ jẹ wi pe awa ko ri aridaju pe bẹẹ lọrọ ri, iru nkan bayi ko jẹ tuntun lawujọ awọn Yoruba.
Owo ṣipini ti ko gun ni lapa lawọn elewe ọmọ a maa gba lọwọ awọn alabara wọn gẹgẹ bi wọn ṣe ṣalaye.
Kaakiri awọn ile iwosan ọfẹ ni idanilẹkọ ati eto ifetosọmọbibi fawọn araalu.
Ninu awọn eto yi leleyi tawọn obinrin a maa fi sinu apa, oju ara tabi eleyi ti wọn a maa lo bi tabilẹti loore koore.
Eyikeyi to ba ṣiṣẹ fun yin, ẹ ma gbagbe pe Eledua lo n fi ọmọ ta ni lọrẹ nigba kigba to ba wu.

Oríṣun àwòrán, Facebook/YohaibFashionStudio
Igbiyanju lda n gba, eleyi ti yoo ba di ọmọ iriri ti fi han lorisirisi pe ifetosọmọbibi ko ni le daa duro.
Ati sayẹnsi ati imọ awọn baba wa, ko si eleyi to le sọ pato bi iru nkan bayi ṣe n waye.
- Eré ìfẹ́ di eré ẹkún! Olólùfẹ́ méjì lẹ̀pọ̀ lásìkò tí wọ́n n bá ara wọn sùn nínú adágún odò
- Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ogun ti pàsẹ pé ki adarí OPIC tẹ́lẹ̀ri dá #40 miliọ̀nù padà
- "Ó yẹ kí ìjọba máa fún wa ní ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ tí oyún bá bàjẹ́ mọ́ wa lára"
- Chiwetalu Agu ti gba òmìnira lọ́wọ́ àwọn sọ́jà tó mú u
- Ẹ wo Ajá tó ń gbọ́ òórùn àìsàn ibà, ẹja tí a kò gbọdọ̀ pa àti ọọ̀nì tó ń gbọ́ àdúrà ní Ìbàdàn
- Àwọn Òṣèré fíìmù Yorùbá tẹ́ ò ro tó tí jápaa lọ ìlú Òyìnbó rèé




















