Family Planning: Obìnrin 200 gbé ìléeṣẹ́ tó ń ṣètò ìfètòsọ́mọbíbí lọ ilé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, HEALTHWATCH
Awọn agbẹjọro to n soju obinrin to le ni igba ti bẹrẹ igbẹjọ tako ileeṣẹ to n pese ohun elo ifetosọmọbibi ni Ilẹ Gẹẹsi.
Awọn obinrin ti ọrọ naa kan sọ wi pe ohun elo ifetosọmọbibi ti ileeṣẹ Essure gbe jade ti ṣe akoba fun ilera ara wọn.
Ohun elo ifetosọmọbibi to da bi irin-kọndọrọ (coil) naa ni wọn maa fi si oju ibi ti ọmọ n gba jade (Fallopian Tube) ni ara obinrin lati dena oyun lo n fa ipalara naa.
Ọdun 2002 ni wọn gbe irin-kọndọrọ (coil) naa jade to n dena oyun fun awọn obinrin lọna ati feto si ọmọ bibi.
''Wọn yọ ile ọmọ mi nitori ''coil ifetosọmọbibi'' to ṣe akoba fun mi''
Amọ ọpọlọpọ obinrin to loo fi irin-kọndọrọ(coil) naa soju ara wọn ni wọn ti bẹrẹ si ni lọ si ile iwosan ki wọn baa le yọ irin naa kuro ni oju ara wọn, nitori ipalara to n ṣee ni agọ ara wọn.
Awọn miran nilo ati yọ ile ọmọ wọn kuro ki wọn ba le gbadun ilera ara wọn.

Arabinrin Tracey Pitcher to sọ iriri rẹ ni oun gbe igbesẹ lati fi eto si ọmọ bibi, lẹyin ti oun ti bi gbogbo ọmọ ti oun fẹ bi tan.
''Dokita mi ni ki n ṣe ifetosọmọbibi oni ''coil'' lati le ri i pe o dena oyun daradara''.
''Amọ kaka ki o san lara mi, niṣe lo fa aisan si mi lara''.
''Nkan osu mi bẹrẹ si ni pọ sii, ori fifọ nigba gbogbo, ti mọ si ma n lọ si ileewosan ni igba de igba.''
''Awọn dokita ni ko si ohun to ṣe mi ni gbogbo igba ti aisan ba n ṣe mi''
''Amọ gbogbo igba ti mo ba ti lọ si ileewosan ni wọn ma n sọ fun mi pe ko si oun to ṣe mi'''.
''O to asiko kan ti mo bẹrẹ si ni rọ wipe mo ni aisan ọpọlọ ti mo fi n ro awọn aisan to n ṣe mi naa''.

Arabinrin Tracey Pitcher ni nkan yipada fun oun nigba ti o ri awọn obinrin bii tirẹ lori ẹrọ ikansiraẹni Facebook to n la iru ipọnju yii kọja, ti awọn dokita sọ wi pe ko si ohun to ṣe wọn.
''Igba ti a ba yọ kuro ni a maa to ni isinmi, amọ eyi ti ṣe ipalara fun ẹbi mi nitori aisan ojoojumọ ti ko jẹ ki n tọju awọn ọmọ mi.''
- Awọn ọlọ́pàá gbòde kan ní Ajah, ọwọ́ tẹ àwọn afurasi tó ń jalè
- Àwọn oniròyìn ló tú àṣírí ààbò Prof Peller, tí wọn fi ri pa - Lady Peller
- Iléeṣẹ́ ológun ní ó bàwọn lọ́kàn jẹ́ bí Sanwo-Olu ṣe ni kìí se òun ló pe sójà si Lekki
- Ohun tó ṣẹlẹ̀ rèé níbi ìsìnkú Ginimbi ọ̀dọ́mọdé olówó tó kú lẹ́ni ọdún 36
- Ipa tí mo kó lágbègbè mí lásìkò ìwọ́de EndSARS ló dènà làásìgbò - Alaafin
Amọ, ileeṣẹ to n pese ''coil" ifetosọmọbibi naa ti ni awọn rii daju ohun elo naa ko ni ṣe ijamba fun wọn.
Bakan naa ni wọn ni awọn ti pese iye owo to to $1.6bn (£1.2bn) lati fi ṣe eto gba ma binu fun obinrin ẹgbẹrun lọna ogoji (40,000) to ṣe ifẹtosọmọbibi naa.












