Ajah Stealing: Awọn ọlọ́pàá gbòde kan ní Ajah, ọwọ́ tẹ àwọn afurasi tó ń jalè

Awọn afurasi ole

Oríṣun àwòrán, Twitter/Lagos State Police Command

Bo ṣe n tẹ wa lọwọ ni wipe awọn janduku yabo adugbo ni agbegbe Ajah ni ipinlẹ Eko lọjọ Aiku ọjọ kẹẹdogun oṣu kọkanla.

Ileeṣẹ Ọlọpaa fi aridaju han fun BBC pe awọn ti wa ni adugbo ti iṣẹlẹ naa ti waye bẹẹ si ni ọwọ ti tẹ awọn jaguda tawọn ti ọpọlọpọ nkan ti wọn ji.

Àkọlé fídíò, 'Mo ní àṣírí ìyá tó fẹ́ ọmọ rẹ̀ láya fún Boko Haram torí ẹbí rẹ̀'

Lowurọ ọjọ Aiku ni awọn aworan kan fọnka lori ayelujara ti o ṣafihan ina to n ru soke.

"Ṣe ni awọn eeyan n sa soke sodo nigba ti iro ibọn n dun kola kola to gba gbogbo adugbo kan"

Nicky Ofondo to jẹ olugbe agbegbe naa lo sọ ohun toju rẹ ri fun BBC.

"Lati bii ọjọ marun ni mo ti n fura tori bi mo pari ti mo kuro nibi iṣẹ, ẹru a maa ba mi bi mo ba ti n sunmọ adugbo mi ni Ajah, a maa ri bii ibi ti awn eeyan ti ṣẹṣẹ sa kuro, waa maa gbọ itan pe wọn ja awọn eeyan lole".

O fi kun un pe "eleyi bẹrẹ lẹyin gbogbo rogbodiyan ifẹhonuhan EndSARS, koda mo n sọ fun ọkọ mi pe a o ko kuro lagbegbe naa bi wahala yii ba tẹsiwaju".

Bakan naa, dokita kan nileewosan aladani kan ni Ajah sọ fun wa pe wọn kọ eeyan kan ti ọta ibọn ta ba loju lọjọ Abamẹta nileewosan mii ti wọn si gbe e wa sọdọ awọn. O fẹsun kan pe ọlọpaa lo yinbọn ba a.

Aja, Eko

Oríṣun àwòrán, @Gidi_Traffic

Ṣaaju l'Ọbọjọ ni iroyin kan jade pe awọn janduku kọlu ọkọ kan to gbe owo ti wọn pa eeyan kan ti wọn si ṣe aṣọna kan leṣe lagbegbe Ado ni Ajah kan naa.

Nigba to fi di ọjọ Aiku, dokita to n ṣetọju aṣọna naa ti oruk rẹ n jẹ Daniel Ali fi idaniloju han fun BBC pe arakunrin aṣọna ọhun ti pada gbẹmi mi lẹyin iṣẹ abẹ ti wn ṣe fun un.

O to ọjọ diẹ bayii ti iroyin n ta kalẹ pe awọn janduku n fa wahala lawọn agbegbe kọọkan ni ipinlẹ Eko lẹyin iwọde EndSARS to waye nipinlẹ naa.