High Bread Price: Ìwà ìkà gbáà ni gbígba owó orí lórí Búrẹ́dì - Gómìnà Yahaya Bello

Iroyin kan to gbalẹ kan bayii ni pe ijọba yoo maa gba owo ori lori eroja burẹdi ti wọ́n ba se jade nipinlẹ Kogi.
Atẹjade tileesẹ to wa fun eto okoowo ati ileesẹ aje nipinlẹ Kogi fi sita ni owo ori ọja lori burẹdi yoo mu ki owo to n wọle labẹle tubọ ru gọgọ si nipinlẹ naa.
Ẹwẹ, Gómìnà ìpìnlẹ̀ Kogi Yahaya Bello ti kéde pé, ìwà ìkà láti fí owó orí lé búrẹ́dì àti pé òun kò mọ̀ ǹkan kan nípa rẹ̀.
O ní ìwà àburu gbáà ni.
- Báa ṣe dóòlà ọba Akiolu lásìkò táwọn jàndùkú kọlu ààfin rèé
- Ohun tó ṣẹlẹ̀ rèé níbi ìsìnkú Ginimbi ọ̀dọ́mọdé olówó tó kú lẹ́ni ọdún 36
- Iléeṣẹ́ ológun ní ó bàwọn lọ́kàn jẹ́ bí Sanwo-Olu ṣe ni kìí se òun ló pe sójà si Lekki
- Mo sọkún lẹ́yìn tí Sierra Leone ta ọ̀mì pẹ̀lú Nàìjíríà, Super Eagles gbọdọ̀ lù wọ́n padà pẹ̀lú 4-0 - Pinnick
Ìgbákèjì gómínà, Edward Onoja nínú àjẹjáde kan tó fi síta ló sàlàyé pé owó orí ti àwọn ìgbìmọ̀ aláṣẹ ìjọba fi sórí búrẹ́dì kò hàn sí gómìnà rará, ilé iṣẹ́ tó ń ri sí okóòwò àti ìdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ ló gbe jáde.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ̀: "Gómìnà ní kí ń mu wá sí etí ìgbọ́ yín pé irọ́ gbáà ni owó orí tí wọ́n fi sórí ìṣù búrẹ́dì kọ̀ọ̀kan nípìnlẹ̀ Kogi".
"Kò sí òtítọ́ kan níbẹ̀ rárá, ó tún wá buru jáì pé wọ́n ní mó ti buwọ́lù ú, mí o búwọ́ lù ú, mí ò sì le búwọ́ lù ú rárá."
Owó orí òun bí Onoja ṣe sọó yàtọ̀ sí ǹkan ti wọ́n ń polongo kiri lórúkọ ìjọba ]ipińlẹ̀ Kogi, kò sì ní bójú mu kí àwọn ènìyàn Kogi máa tẹ̀lé ìrú àwọn ọ̀rọ̀ báyìí, pàápàá jùlọ lẹ́yìn ìnira tí ààrùn Coronavirus ti kó bá ará ìlú.
Ó fi kun un pé àkọsílẹ̀ wà nínú ìwé ìròyìn pé, gómìnà ìpoińlẹ̀ Kogi Yahaya Bello ń já àwọn ogun àìfójú ri kan to jú èyí ti gómìnà kankan ti jà ní ìpińlẹ̀ Kogi lọ pàápàá jùlọ láti mú kí àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Kogi fi le wa ní àláfíà.















