2021 AFCON Qualifier: Pinnick ní òun sọkún lẹ́yìn tí Sierra Leone dójúti Nàìjíríà, Super Eagles gbọdọ̀ lù wọ́n padà pẹ̀lú 4-0

Amaju Pinnick, Gernot Rohr

Oríṣun àwòrán, Twitter/Amaju Melvin Pinnick

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Omi bọ loju mi poro poro, lẹyin ti Sierra Leone da goolu mẹrin ti Super Eagles gba wọle wọn pada tan.

Aarẹ ajọ NFF to n ri si ere bọọlu afẹsẹgba lorilẹede Naijiria, Amaju Pinnick lo sọ bẹẹ lọjọ Abamẹta lẹyin ti Naijiria gba ọmi alayo mẹrin mẹrin ninu ifẹsẹwọnsẹ ati pegede fun idije AFCON 2021 niluu Benin nipinlẹ Edo.

Pinnick ni oun ko le ranti igba igba ti omi jabọ loju oun kẹyin, ṣugbọn eleyi waye nitori Super Eagles sun loju ogun ni Benin.

''Emi kọ ni akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles, to ba jẹ pe emi ni, awọn agbabọọlu kan wa ti mi o ni pe mọ laelae lati wa gbabọọlu fun Naijiria,'' Pinnick lo sọ bẹẹ.

Pinnick sọ fawọn agbabọọlu Super Eagles pe wọn o jara mọ ọrọ ere bọọlu naa to bo ti yẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

O sọ fun wọn pe afaani nla ni wọn ni pe wọn wa lara awọn mọkanla to n ṣoju orilẹede Naijiria nibi ti eeyan to le ni igba miliọnu wa.

Aarẹ ajọ NFF ni awọn agbabọọlu Super Eagles gbọdọ pe ara wọn si ajọ to ni ironu bayii ki wọn si lọ tun ọmọluabi wọn ṣe ni Sierra Leone.

Super Eagles gbọdọ lu Sierra Leone mọle pẹlu ami ayo mẹrin sodo bayii lọsẹ to m bọ.

Orukọ mi lawọn ọmọ Naijiria maa pe kii ṣe orukọ awọn agbabọọlu Super Eagles kuugba ti ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria fidi rẹmi.

Super Eagles dójúti Nàìjíríà ni pápá ìseré Ogbemudia ní Benin

Alex Iwobi, Victor Osimen, Samuel Chukwuezie lo koko gba bọ̀ọ̀lu sawón fun Naijiria ti a fi ni goolu merin

Awon orile ede mejeeji ti pade ara won ni igba merinla ni eyi ti Naijiria ti bori ni igba mẹ́san an sẹyin.

Nigeri Vs Serra Leone

Ninu idije yii ni awon agbaboolu Naijiria ti koko fakoyo pupo ti ọ̀pọ̀ si koko gboriyin fun wọn ki nkan to yipada

Ni abala idije naa akọ́kọ́ ni awọn agbabọọlu Naijiria ti kọ́kọ́ fun ti orile-ede Sieria Leone ni ami ayo mẹ́rin si ọ̀kan.

Awọn ẹgbẹ́ mejeeji yoo tun pade ni abala idije miran ni orile-ede Sieria Leone laipe.

Nigba ti abala naa di ikeji ni awon agbaboolu Sieria Leone gba ayo miran si awọ̀n Naijiria ni eyi to fi di merin si meji.

Leyin iseju die ni abala keji ni Leone Stars tun so ami ayo miran sinu awọn Naijiria.

Ni eyi to so idije naa di Merin fun Naijiria ati meta fun Sieria Leone.

Iseju die si asiko yii ni Leone Stars tun so ayo miran si awọn Naijiria ni eyi to sọ di merin si merin fun awọn mejeeji.

Àkọlé fídíò, Snake Market: Àwọn òńtàjà ẹran ejò ní ẹran ejò dùn ju ẹran adìẹ lọ