Family Planning: Ìjọba Nàìjíríà n fẹ́ kí àtúnṣe wà sí bí àwọn obìnrin ṣe n bímọ

Iya atọmọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ijọba sọ pe igbesẹ naa jẹ ọkan lara ọna lati mu idagbasoke ati irapada ba ọrọ aje Naijiria.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Minisita fun eto isuna orilẹede Naijiria, Zainab Ahmed, ti salaye pe kii ṣe pe ijọba fẹ fi gbedeke si iye ọmọ ti obinrin gbọdọ bi.

O fi ikede naa sita loju opo Twitter rẹ, gẹgẹ bi alaye loti ọ̀rọ̀ kan to sọ nibi ipade apero kan to waye nilu Abuja l'ọjọ Iṣẹgun.

O ni kii ṣe pe ijọba orilẹede fẹ ẹ maa fi gbedeke sita lori iye ọmọ ti obinrin kọọkan gbọdọ bi.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Amọ, ijọba Naijiria n wa gbogbo ọna lati ri i daju pe awọn obinrin n fi alaafo si aarin awọn ọmọ ti wọn ba n bi.

Nibi eto apero ọrọ aje, ikẹrinlelogun iru rẹ to waye nilu Abuja ni ọ̀rọ̀ naa ti jẹyọ.

Ahmed sọ pe ijọba ti fi ọrọ naa lọ awọn ọba alaye ati awọn olori mi i jakejado orilẹede Naijiria.

O ṣalaye pe igbesẹ naa jẹ ọkan lara ọna lati mu idagbasoke ati irapada ba ọrọ aje Naijiria.

Àkọlé fídíò, Ìyá àkàndá ẹ̀dá: Àwọn ẹbí mi fẹ́ kí n pa ọmọ mi torí ó jẹ́ àkàndá ẹ̀dá

O sọ pe 'bi awọn eniyan ṣe pọ to ni Naijiria ni wọn ti tọka si gẹgẹ bi ọkan lara awọn ipenija ti ko jẹ ki igbiyanju ijọba o yọ lori eto ọrọ aje.

Ahmed sọ pe ifọwọsowọpọ awọn lọbalọba ni ireti wa pe yoo jẹ ki o rọrun lati gbe eto kan kalẹ ti yoo jẹ ki awọn obinrin maa fi aaye silẹ lẹyin ti wọn ba bi ọmọ kan, ki wọn tun to o bi omiran, nitori pe o sẹ pataki fun idagbasoke awujọ.

Igba akọkọ kọ niyii ti ijọba yoo fi gbedeke si iye ọmọ ti obinrin gbọdọ bi. Ijọba orilẹede China ti gbe ofin kalẹ pe ọmọ kan ṣoṣo ni ẹnikọọkan gbọdọ bi, ko to o di pe wọn tun sọ ọ di meji.

Àkọlé fídíò, Stella Akinsọ: Àwọn Ìwé Mímọ́ fi àsẹ sí ìfètòsọ́mọbíbí

Ọna ti ijọba Naijiria fẹ ẹ gbe e gba ko ti i fojuhan, nitori igbagbọ ọpọ eniyan ni pe Ọlọrun lo n ṣọmọ, ẹnikẹni ko si gbọdọ ka ọmọ f'ọlọmọ.