PDP NEC 2023 decision: Àríwá Nàìjíríà ní alága PDP yóò tí wà ṣùgbọ́n lórí ọ́rọ́ 'Zoning' ipò ààrẹ...

Oríṣun àwòrán, PDP
Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ti fẹnuko pe awọn yoo yan alaga ẹgbẹ lati ariwa orileede Naijiria.
Eleyi jẹ ọkan lara abajade ipade ti wọn ṣe nilu Abuja lỌjọbọ.
Ọrọ ibi ti wọn yoo gbe ipo alaga ẹgbẹ si jẹ eleyi ti awọn eeyan ti n sọ iriwisi ọtọọtọ le lori lẹnu ọjọ mẹta yi.
- Ìyàwó Ganduje ti kúrò lọ́dọ̀ọ́ EFCC, wo ohun tó gbé e lọ síbẹ̀....
- Agbébọn yìnbọn pa akẹ́gbẹ́ rẹ́ lásìkò ìjínígbé tí wọ́n kójú Àmọ̀tẹ́kùn
- Wàhálà bẹ́ sílẹ̀ nílé aṣòfin, káńsẹ́lọ̀ obìnrin ní alága káńsù ló pàṣẹ káwọn jàndùkú fa aṣọ òun ya.
- Kí ni òṣèré Chiwetalu Agu ṣe tí àwọn ológun gbé e jàǹtò? Ẹṣẹ tí wọn kà síi lọrùn rèé
- Àpẹ́rẹ́ àìsàn tó ń fa àrùn jẹjẹrẹ pọ̀ lára àwọn obinrin tó wà ní ìlú Ibadan - Ìwádìí fìhàn
Sẹnẹtọ Ibrahim Tsauri to jẹ akọwe agba ẹgbẹ naa sọ fun BBC pe koko mẹrin pataki lawọn ipinu le lẹyin ipade naa.
Awọn ipinnu mẹrin naa ree:
- Alaga ẹgbẹ gbọdọ wa lati apa ariwa orileede Naijiria
- Wọn yoo ṣe paṣiparọ awọn ipo laarin awọn to wa lati Ariwa Naijiria ati awọn to wa lati Guusu Naijiria
- Pasiparọ ipo yi kokan awọn to di ipo mu lọwọlọwọ bayi
- Gbogbo ọmọ ẹgbẹ lo lẹtọ ki wọn gbọ eyikekyi ẹhonu to ba mu wa.
Ipinnu yi wa ni ibamu pẹlu aba ti igbimọ to da lori pinpin ipo ti Gomina Ifeanyiu Ugwuanyi dari rẹ da.
Kola Ologbondiyan to jẹ akọwe ipolongo ẹgbẹ sọ pe lori ọrọ ibi ti wọn yoo gbe oludije ipo aarẹ si awọn ko ti fẹnu ko tan.

Oríṣun àwòrán, @PDP
O ni gbogbo ọmọ ẹgbẹ ni yoo sọ ẹni ti yoo lanfaani lati dije dupo aarẹ.
Atiku Abubakar to jẹ ọkan lara awọn eekan ẹgbẹ ti ṣaaju sọ pe ki ẹgbẹ ma ṣe lo ilana zoning lati fi yan ẹni ti yoo dije ipo aarẹ.
O sọ pe ọrọ ibi ti aarẹ ba ti wa ti n da wahala silẹ lati ọjọ to ti pẹ
''Ko si nkan to n jẹ aarẹ to wa lati Guusu tabi lati ariwa aarẹ kan ṣoṣo lo wa eyi si ni aarẹ Naijiria fun Naijiria fawọn ọmọ Naijiria''.
Àwọn adari ẹgbẹ́ òṣèlú PDP bẹ̀rẹ̀ ìpàdé lórí ọjọ́ ọ̀la ẹgbẹ́ náà
Oni, ọjọ keje, oṣù Kẹwaa, ọdún 2021 ni ẹgbẹ oṣelu PDP n ṣe ìpàdé awọn adari rẹ èyí tí ọ le yọri sí itẹsiwaju tabi ifasẹyin ẹgbẹ náà.
Ireti wa pé àwọn adari ẹgbẹ ọhun yóò jíròrò lórí gbígbé ipò Ààrẹ lọ sí ẹlẹkunjẹkun eyiti ti igbimọ kan ti gomina Ifeanyi Ugwuanyi darí rẹ daba.
Lasiko to n tẹwọ gba esi ìpàdé igbimọ náà, alaga fidihẹ ẹgbẹ ọhun, Yemi Akinwonmi sọ pé ìpàdé tí yóò waye lonii ni yóò ṣàpèjúwe ọjọ iwájú ẹgbẹ oṣelu PDP.
- Ọwọ ọlọ́pàá tẹ afurasí ajínigbé tó máa n dibọn bí dírẹ́bà láti jí àwọn arìnrìnàjò gbé
- Ìyàwó Ganduje ti kúrò lọ́dọ̀ọ́ EFCC, wo ohun tó gbé e lọ síbẹ̀....
- Ìdí rè é. tí ọmọ tí kò bá tí pé 18 kò ṣe lè lo ''SIM Card'' mọ́ ní Naijiria...
- Kéére o! Ojú òpó WhatsApp kò ní ṣiṣẹ́ mọ́ lórí àwọn ẹ̀rọ ìléwọ́ yìí láti Nov 1
- Àwọn adari ẹgbẹ́ òṣèlú PDP bẹ̀rẹ̀ ṣèpàdé lórí ọjọ́ ọ̀la ẹgbẹ́ náà
Igbimọ náà ti kọkọ sọ ṣáájú pe kí wọn paarọ ipo awọn adari ẹgbẹ náà, ki awọn èèyàn òkè ọya paarọ ipò wọn pẹlu awọn èèyàn ìhà gúsù.
Ti awọn adari ẹgbẹ náà bá gbe aba yìí wọlé, ọ n túmọ sí pé apa oke ọya ni alaga tuntun ẹgbẹ náà yóò ti wa.
Awọn ipò míràn yóò tún lọ sí òkè ọya, bíi ipo akápò gbogbogbò, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Nigba ti akọwe gbogbogbo yóò wá láti ìhà gúsù, to fi mọ alukoro, atawọn ipo mii.
Ẹwẹ, awọn èèyàn kan ninu ẹgbẹ ọhún ti n fapajanu pe imọran igbimọ náà dára, sùgbón kò ṣe é tẹle.
Wọn ni imọran naa kii se fun itẹsiwaju ẹgbẹ oṣelu PDP, bi ko ṣe fún apo awọn èèyàn kan nínú ẹgbẹ náà.
- Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin yan ẹ̀ní tó tí bẹ̀rẹ̀ iléẹ̀kọ́ kí wọ́n tó bíi sáyé gẹ̀gẹ̀ bí ọmọ ìgbìmọ̀ Àjọ EFCC
- Bí ẹnu rẹ bá ń rùn, ọ̀nà márùn-ún tí o lè gbà láti ṣẹ́gun ẹnu rírùn àti ìṣòrò eyín
- Kéére o! Ojú òpó WhatsApp kò ní ṣiṣẹ́ mọ́ lórí àwọn ẹ̀rọ ìléwọ́ yìí láti Nov 1
- Iléẹjọ́ ti ṣetán lórí ẹjọ́ Omolọla ọlọ́pàá obìnrin tí wọ́n lé lẹ́nu iṣẹ́ nítorí pé o gboyún
- 'Bóo bá ní "side chic" lẹ́nu iṣẹ́ Ọba níbí, gbígba ilé lọ yá fún ọ nìyẹn!'
- Ilé alájà méjì dàwó nílùú Abuja, èèyàn kan kú, orí kó àwọn míì yọ



















