Burundi government fires workers with side chics: 'Bóo bá yan àlè lẹ́nu iṣẹ́ Ọba níbí, gbígba ilé lọ yá fún ọ nìyẹn!'

Oríṣun àwòrán, Burundi
Ààrẹ Burundi Evariste Ndayishimiye, ti pinu láti kọ̀wé lọ rọ́kún nílé fún àwọn tó dipò ìjọba mú sùgbọ́n tó ń yan àlè lẹyin ìyàwò ilé rẹ̀.
Mínístà tó n ri si ètò àbò abẹ́lé Gervais Ndirakobuca ni ìgbésẹ̀ tuntun ti ìjọba fẹ́ gbé láti mú ìmọ́tótó bá àwùjọ.
Gẹ́gẹ́ bí ìdarí náà ṣe wá ni pé gbogbo àwọn tó bá ti ní ìyàwó sílẹ̀ tí wọ́n tún ni àlè síta ni wọ́n yóò le kúrò lẹ́nu iṣẹ́.
- Irọ́ ni, kò sóhun tó jọ pé a fẹ́ gbẹ́sẹ̀ lé owó 'domiciliary account' àwọn ènìyàn Nàìjíríà- CBN
- Ẹ̀yin ọmọ Naijiria, ẹ ṣóra fún ''Frozen Turkey, Chicken'' àwọn ìkà ń fí ''Formalin'' sí i- NAFDAC
- Ìyàwó Ganduje ti kúrò lọ́dọ̀ọ́ EFCC, wo ohun tó gbé e lọ síbẹ̀....
- Èkó àti Rivers nìkan kọ, wo àwọn ìpínlẹ̀ Gúúsù-Gúúsù mi tó ṣetán láti lọ sílé ẹjọ́ gíga jùlọ lórí VAT

Oríṣun àwòrán, Burundi
Ìdarí kejì rèé láti mú ìmọ́tótó bá àwùjọ, ara àwọn ìlànà yìí ni ààrẹ Pierre Nkurunziza là sílẹ̀ kí ó tó kú.
Ní inú oṣù Karun ọdun 2017, ààrẹ Nkurunziza, tó jẹ́ àtúnbi onígbàgbọ́ ṣe ofin pe ki tọkọtaya ṣe ìgbéyàwó kó tó dí inú oṣù kejìlá, ọdún 2017 tàbí ki wọ́n kojú ìjà òfin.
Gẹ́gẹ́ bi ó ṣe sọ bi àwọn ènìyàn ṣe pọ̀ síi nílùú kò ṣẹ̀yìn bi àwọn ọkùnrin ṣe fún ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ obìnrin lóyín ti wọ́n ko si nifẹ wọn.
" A fẹ́ kí o yé àwọn ará Burundi pé, olúukúlùkù ni yoo mójú tó ayé ara rẹ̀, a fẹ́ kí ilú ni ètò ni orílẹ̀-èdè, èyí ni nkan ti agbẹnusọ mínísítà ọ̀rọ̀ abẹ́lẹ́ Terence Ntahirsja sọ fún AFP News.
Ọdún 2020 ni Nkurunziza kú, èyí sì ló mú kí Ologun Gervais gba ìjọba













