Amotekun Ondo; Agbébọn yìnbọn pa akẹ́gbẹ́ rẹ́ lásìkò ìjínígbé tí wọ́n kójú Àmọ̀tẹ́kùn

Agbebon

Oríṣun àwòrán, Others

Afurasi agbebọn kan ti pa akẹgbẹrẹ lasiko ti wọn wọ iya ija pẹlu awọn oṣiṣẹ ikọ ẹṣọ alaabo ti ipinlẹ Ondo, iyẹn Amọtẹkun.

Iroyin ni afurasi agbebọn to ri iku rẹ, ti orukọ rẹ n jẹ Funmi Adenuoye naa ni akẹgbẹ rẹ Kunle yinbọn pa lasiko ti wọn n sa asala fun ẹmi wọn lọwọ ikọ Amọtẹkun.

Awọn agbebọn yii n sa lasiko ti wọn ji arakunrin oniṣoro, Alhaji Shakirudeen gbe ni ipinlẹ Ogun, ti wọn si wa ọkọ rẹ wa si ipinlẹ Ondo ki ọwọ to tẹ wọn.

Lasiko ti ọkan lara awọn agbebọn naa n sọrọ ni awọn n gbe ẹni ti wọn jigbe naa lọ si agbegbe JK ati Ajebandele nibi ti awọn ti fẹ gba owo ẹmi arakunrin naa.

''Wọn kọkọ ni ki arakunrin naa san miliọnu mẹwaa naira, amọ ẹni ti wọn jigbe naa bẹ wọn ki wọn jẹ ki oun san miliọnu meji naira, to si pe awọn mọlẹbi rẹ ki wọn gbe wa si ibẹ.''

Àkọlé fídíò, Ẹni tó bá ni kí n fi iṣẹ́ kòkò mímọ sílẹ̀, mi ò lè fẹ́ẹ láéláé - Adekemi Àgùnbánirọ̀

Amọ, ikọ Amọtẹkun to ri bi wọn ṣe n sa loju popo fihan pe nkan n ṣẹlẹ ninu ọkọ naa ti wọn si tẹlẹ wọn.

Ọwọ tẹ Ibrahim to jẹ ọkan lara awọn mẹta ajinigbe naa, nigba ti Kunle fi ẹṣẹ fẹ, amọ ti ibọn pa Funmi lasiko ti ikọ Amọtẹkun doju ibọn bo wọn.

Amotekun

Oríṣun àwòrán, Others

Adari ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adeleye ni iwadii awọn lo fihan pe bi awọn awakọ naa ṣe n sare loju popo jẹ ki awọn furasi awọn to wa ninu ọkọ naa.

''Bi o tilẹ jẹpe a ko mọ awọn to wa ninu ọkọ naa, a dẹkun fun wọn si agbegbe Okitipupa ni ipinlẹ Ondo lati mu wọn.''

Àkọlé fídíò, Nàìjíríà kàn wà ni, ẹ ò páàsì, ẹ ò féèlì, ẹ ò kúrò ní kíláàsì kan náà - Àwọn ọ̀dọ́

''Awọn ajinigbe naa doju ibọn kọ wa amọ adoola ẹmi ẹni ti wọn jigbe naa, Alhaji Shakirudeen, ti a si fi panpẹ ọba mu Tayo Ibrahim to fẹ gba owo ẹmi miliọnu mẹwaa naira ni oju popo naa.''

''Bakan naa ni wọn jẹwọ pe awọn mọlẹbi ẹni ti wọn jigbe naa ti ṣeleri lati san miliọnu meji naira fun awọn ki ọwọ to tẹ wọn.''

Adari ikọ Amọtẹkun naa fikun un pe awọn tun mu awọn ajinigbe to ma n lọ ra ohun eelo fun awọn akẹgbẹ wọn ninu igbo ni agbegbe ijọba ibilẹ ọwọ nipinlẹ Ondo.

Àkọlé fídíò, Adeyemi Olubunmi Crown: Láti ìgbà ti mo ti fún ọkọ mi ni ẹ̀bùn mọ́tò ni ìfẹ́ wa ti yàtọ̀