Etche local Council fracas: Kà nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ táwọn jàǹdùkú fi fa aṣọ ya mọ́ káńsẹ́lọ̀ obìnrin lára

Aworan Cynthia Nwala

Oríṣun àwòrán, Cynthia Nwala

Ọrọ ti di gbọnmi si omi o to laarin obinrin aṣofin kan nile aṣofin ijọba ibilẹ Etche ni Rivers ati alaga kansuu ijọba ibilẹ naa.

Ko si syin bi arabinrin Cynthia Nwala ṣe fẹsun kan alaga kansuu na pe o ni ki awọn janduku fa aṣọ rẹ ya ti wọn si ba ọkọ rẹ jẹ.

Babanbari ọrọ yi ni bi aworan kansẹlọ ti wọn fa aṣọ rẹ ya yi,arabinrin Cynthia Nwala ṣe gba oju opo ayelujara kan.

Ninu aworan naa niṣe ni aṣọ rẹ ya ti ara rẹ si han sita.Bẹẹ naa ni a ri aworan ọkọ kan ti wọn fọ gilasi rẹ.

Arabinrin Cynthia Nwala to jẹ olori ọmọ ile aṣofin ni Etche sọ pe alaga kansuu Chinedu Onyeche lo ran adari eto aabo rẹ CSO lati da sẹria fun oun.

Àkọlé fídíò, Ṣé ìwọ mọ̀ pé Olodumare lè lo Aje láti gbé ẹ lọ síbi ire?- Abiodun Fatomilola

Ninu alaye rẹ to ṣe fawọn akọroyin, o ni nitori ti oun fẹ gbe ọpa aṣẹ ile kuro ni wọn fi fa aṣọ oun ya ti wọn si ba ọkọ oun jẹ.

O ni atunṣe n lọ lọwọ ni ile aṣofin nitori naa loun fi gbe ọpa aṣẹ ki nkan ma baa ṣe ọpa naa.

Àkọlé fídíò, Samuel Oluwafemi sọ bí Covid 19 ṣe bí ìdíje oníjó àti eré fún àwọn Odi àti Adití sí rere

Iṣẹlẹ yi ti mu iriwisi ọtọọtọ wa ṣugbọn alaga kansuu ti wọn fẹsun kan pe o ni ki awọn janduku lu Cynthia,Chinedu Onyeche sọ pe irọ ni Cynthia pa mọ oun.

Agbẹnusọ alaga yi Oluo Anyimachukwu to fi ọrọ lede loju opo Facebook rẹ ni alaga ko ran eeyan kankan lati ya aṣọ Cynthia tabi ki wọn ba ọkọ rẹ jẹ.

O ni adari eto aabo CSO alaga kii ṣe ọmọ ile igbimọ aṣofin tori naa ko le da si ọrọ to n lọ laarin awọn aṣofin.

Àkọlé fídíò, Adepoju Abdulsalamm ẹni ọdun 18 tó n fi kẹ̀kẹ́ dára fi kiri ẹja tó fi n tà wàràwàrà

Atẹjade to fi sita ni yatọ si ohun to sọ fawọn akọroyin''Cynthia lo ko awọn ọlọpaa ati janduku ogun wa lati wa fi ipa gbe ọpa aṣẹ kuro nile''

O ni igbe gbajare ti awọn aṣofin ke lo mu ki CSO wa lati wa daabo bo awọn ọmọ ile aṣofin lọwọ Cynthia ati awọn janduku to ko lọwọ.

Àkọlé fídíò, Adeyemi Olubunmi Crown: Láti ìgbà ti mo ti fún ọkọ mi ni ẹ̀bùn mọ́tò ni ìfẹ́ wa ti yàtọ̀

Lori ọrọ yi, awọn ikọ ajafẹtọmniyan obinrin ni ilu Port Harcourt ti ṣe iwọde lọ si ọfisi Gomina ipinlẹ naa.

Wọn ni awọn fẹ ki Gomina wa wọrọkọ fi ṣada lori bawọn eeyan ṣe n ṣe ikọlu sawọn obinrin lọna ti ko bofin mu.

Àkọlé fídíò, Ẹni tó bá ni kí n fi iṣẹ́ kòkò mímọ sílẹ̀, mi ò lè fẹ́ẹ láéláé - Adekemi Àgùnbánirọ̀