Adeyemi Olubunmi Crown: Láti ìgbà ti mo ti fún ọkọ mi ni ẹ̀bùn mọ́tò ni ìfẹ́ wa ti yàtọ̀

Àkọlé fídíò, Adeyemi Olubunmi Crown: Láti ìgbà ti mo ti fún ọkọ mi ni ẹ̀bùn mọ́tò ni ìfẹ́ wa ti yàtọ̀

Private Jet ló kù tí mo fẹ́ ra fún ọkọ mi nítorí pé aláànú ni- Gbadewole Olubunmi

Se ẹ ranti arabinrin to fun ọkọ rẹ ni ẹbun ọkọ ayọkẹlẹ fun ayẹyẹ ọdun meje lọọdẹ re?

BBC Yoruba ti wa arabinrin Gbadewole Olubunmi Mary kan.

crown

O sọ idi to ṣe fun olowo ori rẹ ni ẹbun ọkọ yii pe alaanu ọkunrin to n fi obinrin lọkan balẹ ninu ile ni fun ọdun meje ti wọn ti jọ fẹ ara wọn.

crown

Adeyemi Olubunmi Crown ni ọkọ oun n ṣaanu ṣugbọn kii ri ẹbun gba lọwọ awọn eeyan.

Arakunrin Gbadewole to gba ẹbun okọ yii pẹlu ayọ lọwọ aya rẹ gba awọn eeyan nimọran lati maa san oore pada fun alaanu wọn.

O ni ọpọ eniyan lo jẹ pe muwa muwa nikan ni wọn mọ bẹẹ o dara lati maa ṣe oore.

crown

O ni o dara lati maa ranti ẹni to ba ti ṣe eeyan ni oore ri ki eeyan naa gbiyanju lati san oore pada fun iru ẹni bẹẹ nitori yinyin eniyan ati didupẹ oore maa n jẹ koriya ni

crown

Ogbeni Gbadewole ni oun kii ṣe ọkọ ole, ati pe oun mọ ibi ti iyawo oun ti ri owo ra mọto naa fun oun gẹgẹ bii ẹbun ifẹ.

Bakan naa ni Arabinrin Adeyemi Crown naa gba awọn aya ni iyanju lati ma ṣe ohun iyalẹnu fun olowo ori wọn loorekoore ki inu wọn le maa dun pe ọkọ ri oju rere bi o ṣe fẹ iyawo rẹ.