Kidnapping in Zamfara: Àwọn jàndùkú tún ti jí èèyàn méjì gbé ní Zamfara

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn agbebọn kan ti kọlu agbegbe Nahuche, ni ijọba ibilẹ Bungudu to wa ni ipinlẹ Zamfara.
Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ, Malan Abubakar, sọ pe lara awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ ni ọlọpaa kan ati adari ikọ awọn fijilante.
Abubakar sọ fun awọn akọroyin pe awọn janduku ọhun tun ji eeyan meji gbe lọ lasiko ikọlu naa.
- Àìsàn wo ló ń bá Okele, òṣèré tíátà finra, tó fi dèrò ilé ìwòsàn?
- Á ṣiṣẹ́ tako Seyi Makinde fún sáà kejì - Igun PDP l‘Oyo fọnmú
- Wàhálà lẹ̀ ń wá tẹ́ ẹ̀ bá tú Sunday Igboho àtàwọn èèyàn rẹ̀ mẹ́rin sílẹ̀ ní àhámọ́ - Ọmọ Nàíjíríà lókè òkun
- "Ọmọ Naijiria, ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Elédùà tó fi ìjọba Buhari ta wá lọ́rẹ''
- Ẹ wo àtúpalẹ̀ bí Bobrisky ṣe ná ₦500m péré láti ṣe ọjọ́ ìbí
- Wo ohun mẹ́rin tó lè mú ikú wá lásìkò ìbálòpọ̀
- Afurasí mẹ́jọ tó tẹ ayédèrú ₦98m àti $1.5m wọ gàù àjọ DSS
- Àwọn tó lu ₦6trn owó àjọ NDDC ní póńpó rugi oyin - Buhari fọnmú
- Kí ló dé tí Oluwo àti ìyàwó rẹ̀ àná ń sòkò ọ̀rọ̀ síra wọn lórí ayélujára?
O ni awọn janduku naa kọkọ ya bo abule kan ni Nahuche ti wọn n pe ni Gidan Jan Bula, wọn si fi alupupu pa olori awọn fijilante naa lẹyin to kọju ija si wọn.
O ṣalaye pe "Wọn gbe iyawo mi lọ lasiko ikọlu naa."
Abubakar sọ siwaju si pe awọn janduku naa lọ si agọ ọlọpaa Nahuchi nibi ti wọn ti doju ibọn kọ awọn ọlọpaa, ti ẹmi eeyan kan lara awọn ọlọpaa naa si sọnu.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, lẹyin na ni awọn janduku naa lọ sile ọkunrin kan, Alhaji Makwashe Nhuche to jẹ oniṣowo, ti wọn si ji okunrin ati obinrin kan gbe nibẹ.
O ni nnkan bii aago mẹta owurọ si aago mẹrin idaji ni awọn janduku naa ṣọṣẹ naa.
Kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn janduku yoo ji awọn eeyan gbe tabi kọlu agọ ọlọpaa nipinlẹ Zamfara, ijọba ipinlẹ ọhun si sọ pe adiyẹ oun n laagun, ṣugbọn iyẹ ara rẹ ni ko jẹ ki awọn ọmọ Naijiria mọ.
Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?
Agbébọn tún kó akẹ́kọ̀ọ́ 73 ní Zamfara, Ọlọ́pàá ń bẹ̀bẹ̀ àdúrà

Oríṣun àwòrán, Muhammed Maradun
Ero gomina ipinlẹ Zamfara, Bello Matawalle ati ile iṣẹ ọlọpaa ṣọtọtọ lori ati dóòlà akẹ́kọ̀ọ́ mẹtalelaadọrin ti ile ẹkọ gírámà ilu Kaya ni ijọba ibilẹ Maradun ipinlẹ naa.
Lẹyin ọjọ marun ùn ti awọn akẹkọọ ile ẹkọ eto ọgbin ati ìmọ nípa ẹranko tó wà nílùú Bakura gb'ominira lọwọ awọn ajinigbe, ni iṣẹlẹ yii tun ṣẹlẹ.
Iroyin sọ pé nínú yara ikawe lawọn akẹ́kọ̀ọ́ ọhún wá, ti awọn janduku ajinigbe yìí fi dé, ti wọn sì gbe wọn lọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ohun mẹ́rin tó lè mú ikú wá lásìkò ìbálòpọ̀
- Kí ló dé tí Oluwo àti ìyàwó rẹ̀ àná ń sòkò ọ̀rọ̀ síra wọn lórí ayélujára?
- Sé sàgbẹ̀lójúyòyò ni àtúnṣe pápá Lekan Salami tí Sèyí Makinde se ni? - Aráàlú ní N5.3bn wọgbó
- Fíìmù India tó gbé agbára oṣó àti àjẹ́ ga ló mú kí ń gbaná jẹ fún Jésù láti ṣe sinimá - Mike Bamiloye
- Ó dìgbà tí mo bá lọ, kí Nàìjíríà tó mọ iyì mi - Buhari
- Buhari ṣíjú àánú wo àádọrin Sọ́jà tó gbọjọ́ ikú, bo ṣe ń dárí jin àwọn Boko Haram tó ronú pìwàdà - Falana
- "Alhaji Fatai, ti DSS pa nílé Sunday Igboho ni kò ríran"
Olugbe ilu Kaya, Mallam Abu Kaya ṣàlàyé pe o ṣeéṣe kí àwon akẹ́kọ̀ọ́ ti wọn gbé lọ to ọgọrun.
Àmọ́, ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Zamfara ní mẹtalelaadọrin awọn akẹkọọ ti wọn jigbe lọ.
Abu fikun ọrọ rẹ pé, alupupu lawọn ajinigbe naa gbe wá sí ile ẹkọ ọhun.
Abu ṣàlàyé pe "awọn janduku ajinigbe yìí di gbogbo ọnà tó lọ sí ile ẹkọ naa, wọn sì bẹrẹ si ni yinbọn lati d'ẹru ba awọn eeyan.
Nibi ti awọn kan ti n yinbọn, lawọn mii ninu wọn ti wọ ile ẹkọ naa lọ lati gbe awọn akẹẹkọ ọhun.
Ẹwẹ, Gomina Matawalle ti wa rọ àwọn eeyan ipinlẹ Zamfara lati lo gbogbo ohun ìjà ti wọn ba ni, lati doola ara won lọwọ awọn janduku ajinigbe.
"Lati oni lọ, mo fẹ ki ẹ maa tu yaya jade doju ija kọ awọn janduku ajinigbe.
Ẹ ko gbọdọ sun ti ẹ ba ti gbọ pe awọn janduku ajinigbe n bọ wa si abule yin.
Ẹ mura silẹ dè wọn pẹlu ohun ija ti ẹ ba ni lọwọ.
A ko gbọdọ ṣojo mọ pẹlu ọrọ awọn janduku ajinigbe yìí, kì wọn le mọ pe a le bawọn ja," Matawalle lo sọ bẹẹ.
Amọ, ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Zamfara ti bẹbẹ adura, ki igbiyanju awọn ọm'ogun ati agbofinro lati doola awọn akẹẹkọ ti wọn jigbe le yọri sí rere.
Alukoro ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Zamfara, Mohammed Shehu rọ àwọn obi ninu atẹjade to fi sita pe, ki wọn maa gbàdúrà, ki wọn sì ṣe suuru bi awọn ọlọpaa ṣe n gbiyanju lati doola awon ọmọ wọn.
Eégún ń tọpinpin kónílé ó gbélé nílẹ̀ Igbo, nǹkan yan

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gómìnà ìpínlẹ̀ Imo fi ọkàn àwọn ará ìlú balẹ̀ pé kí olúkúlùkù lọ sí ibi iṣẹ́ òòjọ́ wọn, síbẹ̀ wọ́n ni ó sàn kí àwọn pàdánù iṣẹ́ òòjọ́ àwọn ju kí àwọn sọ ẹ̀mí nù lọ.
Gbogbo àwọn awakọ̀ nipinlẹ naa pẹ̀lú lo gbe ilé wọn jòkó, tí wọ́n sì sọ gbogbo àwọn arìnrìn-àjò sì kolobo.
Ṣáájú ni àwọn ọmọ IPOB ti sọ fún àwọn ọmọ Igbo pé kí olúkúlùkù jòkó sílè láti fi ẹ̀honu hàn lórí bí wọ́n ṣe tí aṣáájú wọn nínú ìjìjàgbara Nnamdi Kanu mọ́lé fún ẹ̀sùn ṣíṣe lòdì sí oríléedè rẹ̀, tí ó sì ń bá ìjọba àpapọ̀ jẹ́jọ́ n'ilu Abuja.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho fi ọ̀rọ̀ ìyànjú ránṣẹ́ sáwọn olólùfẹ́ rẹ̀ láti Cotonou
- Ẹ̀yin olùwọ́de Yoruba Nation, Arewa ń fẹ́ kẹ jáwọ́ àmọ́... - Àgbàgbà Yoruba
- Sunday Igboho, Nnamdi Kanu tó ń dàámú wa ti kó sẹ́wọ̀n, Ọlọ́run wa kò sùn - Miyetti Allah
- Ajínigbé kọlu ìjọ David Oyedepo, wọ́n jí èèyàn mẹ́ta gbé lọ
- Àjàlú ńlá ń bọ̀ Buhari múra, màrìwò eégún lásán lo rí ní NDA - Fr Mbaka
- Sunday Igboho tún dá Malami mọ́lẹ̀ fún ìgbà kejì nílé ẹjọ́
- DSS tú mẹ́jọ sílẹ̀ nínú àwọn ọmọlẹyìn Igboho, mẹ́rin ṣì wà ní àhámọ́
- Alálẹ̀ ló fi èmi àti Sunday Igboho pamọ́ sí àhámọ́ kí ewu le ré wa kọjá - Oba Ogboni
Bakan naa ni wọ́n ṣe kóníléógbéle náà ni ọjọ́ Kẹ̀sán oṣù kẹjọ, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì bàa lọ, ọ̀pọ̀ dúkìá ló ṣòfò pẹ̀lú.
Ní Ìpínlẹ̀ Ebonyi, gómìnà David Umahi tilẹ̀ sọ pé òṣìṣẹ́ tó bá kọ̀ láti wá síbi iṣẹ́ yóò pàdánù iṣẹ́, síbẹ̀ wọ́n gbà láti pàdánù iṣẹ́ tí ó fi mọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ilé epo gómìnà fúnra rẹ̀.
Sọja ati ajijagbara fija pẹẹta, eeyan mẹta ku:
Làsìkò tí wọ́n ni àwọn IPOB ń fi dandan mú àwọn ènìyàn láti tẹ̀lé òfin kóníléógbéle ni agbègbè Umuonyewere Umuowa ni ìjọba ìbílẹ̀ Ngor Opala, ìpínlẹ̀ Imo, ni àwọn àti sọ́jà kọjú ìbọn sí ara wọ́n ti àwọn mẹ́ta sì bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rin.
Àwọn tí ọ̀rọ̀ náà sójú wọ́n ṣàlàyé pé àwọn tó ń lọ láti ojúlé dé ojúlé yìí ń jà àwọn ènìyàn lólè.
Ó ní àwọn sójà kojú àwọn jàndùkú náà nílé epo kan nibí ti wọ́n ti ń jà ilé epo náà lólè owó àti fóònù.
Ọkọ̀ méjì tó fi mọ́ Rav4, ìbọn ìbílẹ̀, àwọn oògùn olóró nọ́mbà ọkọ̀ méjì ni wọ́n rí gbà lọ́wọ́ wọn.
Janduku dana sun ọkọ to n ko iwe iroyin, awakọ morile igbo:
Ni ìpínlẹ̀ Imo yìí bákan pàápàá jù lọ ní Àwo Omamma, ìjọba Ìbílẹ̀ Oru East náà, ni wọ́n ti dáná sun ọkọ̀ tó ń kó ìwé ìròyìn lọ agbègbè naa.
Gẹ́gẹ́ bi nǹkan tí awakọ̀ náà, Lateef Akanbi sọ, "wọ́n dá mi dúró, ṣùgbọ́n bí mo ṣe rí pé jàndùkú ni wọ́n, pé wọn kii se ọlọ́pàá, mo bẹ́ wọ igbó ni,
mo ti lọ sá pamọ́.
Láti jìnà ni mo ti gbọ́ tí wọ́n sọ pé ‘mú ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọrun wá’, ó kó sí owó kankan lọ́wọ́ mi, mi ò jáde kúrò nínú mọ́tò, nnkan ti mo kan rí ní pe wọ́n ti dáná sí mọ́tò.
Agbenusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Imo, Michael Abattam ni ìwádìí tí bẹ̀rẹ̀, nítorí pé ọ̀daràn ni àwọn tó kú, ìwádìí wá ń lọ lọ́wọ́.
Eegun n yide ni Enugu lati fi tipa mu kawọn araalu fidi mọle:
Ẹ̀wẹ̀ ni Nsukka ni ìpínlẹ̀ Enugu, àwọn egungun lo ń yíde láti pọ́n ni dandan fún àwọn ènìyàn láti jòkó sile.
Bí ó tílẹ jẹ́ pé wọ́n ti dáwọ́ òfin kóníléógbélé ọjọọjọ́ Ajé dúró, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ ni ẹ̀rù ń bá láti jáde lọ wá oúnjẹ òòjọ́ wọn.
Gbogbo òpópónà lọ dá páropàro.























