NDDC Audit Report: Buhari ní ìwádìí fihàn pé báńkì 362 ní NDDC ń lò láti lu jìbìtì owó

Oríṣun àwòrán, @NigeriaGov
Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣeleri pe gbogbo awọn ọmọ Naijiria to lọwọ ninu bi Ajọ Niger Delta Development Commission, NDDC, ṣe lu owo to to triliọnu mẹfa naira ni ponpo, ni yoo fi oju wina ofin.
Aarẹ Buhari sọrọ yii ni Abuja lasiko ti awọn oluyẹwe owo wo (auditors) wa jabọ fun aarẹ lori iṣẹ ti wọn ṣe ni ẹka naa.
O ni iye owo to to N3, 375, 735, 776, 794 , ti wọn fun wọn lati apo iṣuna ọlọdọọdun ti ijọba n gbe kalẹ, ni wọn lu ni ponpo labẹ ajọ to wa fun ọrọ agbegbe Niger-Delta naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kí ló dé tí Oluwo àti ìyàwó rẹ̀ àná ń sòkò ọ̀rọ̀ síra wọn lórí ayélujára?
- "Ojú mi rí màbo lásìkò tí mo lọ gbé N2.5m fáwọn jàndùkú tó jí ẹbí mi gbé"
- Wo ohun mẹ́rin tó lè mú ikú wá lásìkò ìbálòpọ̀
- Ẹ se mẹ̀dọ̀ ẹ̀yin olórí Fulani, ẹ yé tàbùkù àṣà Yorùbá nílẹ̀ wa mọ́ - YCE kìlọ̀
- "Tí Taliban bá rí mí, ikú ní yóò gbẹyìn mi, kò sí ìdáríjìn fún mi"
- Omi lórí pápá ìṣeré Lekan Salami kìí ṣe tuntun, ó lè ṣẹlẹ níbikíbi - Ìjọba Oyo
- Fíìmù India tó gbé agbára oṣó àti àjẹ́ ga ló mú kí ń gbaná jẹ fún Jésù láti ṣe sinimá - Mike Bamiloye
Ko tan si bẹ, Aarẹ ni wọn tun lu iye owo to to N2, 420, 948, 894, 191 to n wọle sinu ajọ naa, ni wọn ti fi iwa ajẹbanu lu ni ponpo.
Aarẹ Buhari ni iwadii fihan pe apo asunwọn owo nile ifowopamọ to le ni ọtalelọọdunrun ati meji ni ajọ NDDC nikan n lo, ti wọn fi n san owo awọn oṣiṣẹ ti wọn ba gbe iṣẹ akanṣe fun, eleyii ti wọn ko ṣe, abi ti wọn pati.
Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, gbogbo igbiyanju ijọba lati ri pe ẹkun Niger Delta dagba, ki wọn kuro ninu iya ati iṣẹ lo n jasi pabo nitori awọn oniwa ajẹbanu ẹda ti wọn wa ni ajọ naa.
''Gbogbo awọn to wa ni ẹka naa, ti wọn fun ni iṣẹ akanṣe to le ni ẹgbẹrun mẹtala, 13,777 ni wọn yoo fi oju wina ofin''
''Mo ti paṣẹ fun ẹka eto idajọ ni Naijiria lati bẹrẹ ayẹwo iwadii iwa ajẹbanu ni ẹka naa, ki wọn si fi awọn ti igba iṣẹlẹ naa ba ṣi mọ lori jofin.''
Adari awọn oniwadii naa, Alhaji Kabiru Ahmed ni awọn ileeṣẹ epo rọbi n jẹ ẹka NDDC ni iye owo to le ni biliọnu mẹrin dọla owo ilẹ okeere.
Ahmed rọ ijọba lati ripe wọn gba owo naa pada, ki aye le rọrun fun awọn eniyan to n gbe ni agbegbe naa, nitori iya n jẹ awọn eniyan yii.
Lara awọn aba ti awọn oniwadii naa gbejade ni pe ki iṣẹ awọn ajọ NDDC ma jẹ iṣẹ ojojumọ mọ, amọ ko jẹ iṣẹ igba de igba.
Bakan naa ni o rọ ijọba wi pe ki wọn ri daju pe gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba ti wọn n gba iṣẹ akanṣẹ laiṣe gbọdọ foju wina ofin.


















