Kidnapping: Àwọn agbébọn kó oúnjẹ àti ọbẹ̀ nílé mọ̀lẹ́bí mi kí wọ́n tó jí wọn gbé

bandits

Oríṣun àwòrán, Anadolu Agency

Okunrin kan, Kehinde Ibiteye ti fi ẹmi ara rẹ sinu ewu lati gbe miliọnu meji abọ naira fun awọn ajinigbe gẹgẹ bii owo itusilẹ awọn mọlẹbi rẹ.

Kehinde ṣalaye fun BBC Yoruba pe, ọwọ Ọlọrun ni oun fi ẹmi oun le lasiko ti oun gbe owo naa lọ fun ajinigbe ọhun lọna ati doola ẹmi àna oun ọkunrin ati ọmọ rẹ ninu igbo kiji kan l'Abuja.

O ṣalaye pe ọjọ kẹtalelogun, oṣu to kọja ni awọn afurasi Fulani kan yabo adugbo aburo iya oun obinrin lagbegbe Ungwan-Fulani, to wa ni Bwari l'Aabuja, ti wọn si ji ọkọ rẹ ati ọmọ rẹ kan gbe lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kehinde sọ pe "Loru ọjọ naa, awọn Fulani kan pẹlu ibọn lọwọ wọn kọlu ile nla kan lẹgbẹ ile aburo iya mi, ṣugbọn wọn ko ba ẹnikẹni ninu ile naa, lẹyin naa ni wọn lọ sile ẹgbọn mi ti wọn si fi tipatikuku wọle."

"Wọn ko ounjẹ, burẹdi ati ọbẹ ninu ile idana pẹlu ẹgbẹrun lọna ogun naira."

"Lẹyin naa ni wọn sọ fun aburo iya mi naa pe awọn kii ṣe adigunjale o, pe ajinigbe ni awọn, ati pe awọn yoo ji ọkọ ati ọmọ rẹ gbe lọ."

Àkọlé fídíò, Femi Branch: Gbogbo dúkìá mi àti ti ìyá mi ni mo tà láti tọ́jú ẹsẹ̀ mi fún ọdún méjì

Kehinde ṣalaye pe ko to iṣẹju marun un si asiko ijinigbe naa, ti awọn ọlọpaa yọju, awọn si ṣalaye ohun to ṣẹlẹ.

O sọ siwaju si pe miliọnu marundinlogun naira ni awọn ajinigbe naa kọkọ beere lọwọ wọn, ṣugbọn wọn din owo naa ku si miliọnu meji abọ naira lẹyin ti oun dunadura pẹlu wọn ni ede Hausa.

Gẹgẹ bo se sọ, okunrin ọlọkada kan lo tẹle oun lati lọ gbe owo naa fun awọn ajinigbe naa ninu igbo kiji kan.

O ni "Lọjọ ti a gbe owo naa lọ, ẹru ba mi gidi gan, koda, mi o bun iyawo ile mi gbọ fun odidi ọjọ mẹta ti mo fi n ba wọn dunarura, ṣugbọn mo fi ẹmi mi le ọwọ Ọlọrun."

"Nnkan bii oṣu meji sẹyin ni mo padanu iya mi, mo si n ṣọfọ rẹ lọwọ, idi ree ti awọn mọlẹbi mi ko ṣe fẹ ki n gbe owo lọ fun awọn ajinigbe naa nitori ewu to wa ninu rẹ."

"Ṣugbọn mo yọnda lati gbe owo ọhun nitori ede Hausa ni wọn n sọ, mo si le sọ ede Hausa daadaa."

"Ohun ti oju mi ri lalẹ ọjọ naa ninu igbo ti mo ti lọ gbe owo fun wọn ko ṣe fẹnusọ, ṣugbọn lẹyin ti wọn gba owo naa tan, wọn tu ọkọ aburo iya mi ati ọmọ rẹ silẹ, ni nnkan bii aago mẹwa abọ alẹ."

Àkọlé fídíò, Babatunde Gbadamosi: Mo ta gbogbo dúkìá mi lásìkò kan kí ń tó padà di eèyàn lónìí

Kehinde ṣalaye pe bo tilẹ jẹ awọn ọlọpaa gbọ nipa iṣẹlẹ ijinigbe naa ṣugbọn wọn ko kọbi ara sii, idi ree ti awọn ko ṣe bun wọn gbọ pe awọn n lọ gbe owo fun awọn ajinigbe naa.

O ni "Awọn ọlọpaa kilọ fun wa pe a ko gbọdọ gbe owo fun awọn ajinigbe naa, ṣugbọn a lọ gbe owo naa fun wọn lẹyin ti awọn ọlọpaa n fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ naa.

Awọn ajinigbe ọhun si n dunkoko mọ awọn mọlẹbi mi pe awọn yoo pa wọn ti a ba kọ lati gbe owo fun wọn."

"Kaka to yẹ ki awọn ọlọpaa jara mọ ọrọ naa, ni ṣe ni wọn tun beere awọ owo kekeke lọwọ wa bii owo epo ati bẹẹ bẹẹ lọ."

"A tilẹ fẹ lọ ba awọn ikọ IRT Abuja tẹlẹ, ṣugbọn ẹnikan sọ fun wa pe wọn maa beere ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (₦ N500,000) lọwọ wa."

Kehinde pari ọrọ rẹ pẹlu arọwa si ijọba apapọ pe ki wọn fi ọwọ pataki mu ọrọ eto abo.

Àkọlé fídíò, Senato francis Fadahunsi: Ká ni wọ́n fún Buhari ladún mẹ́wàá sẹ́ypin ní, bóyá kò bá rí i ṣ

Lẹyin naa lo ni ọrọ ijinigbe ti kọja ohun amuṣere ni Naijria.

O ni "Niwọn igba ti awọn ajinigbe ba ti le laya lati ji eeyan gbe ni Bwari ni Abuja nibi, o n tumọ si pe ko si ẹni ti wọn ko le ji gbe niyẹn, yala minisita tabi sẹnetọ tabi mọlẹbi wọn.