Fake Naira: DSS gbé afurasí mẹ́jọ tó tẹ ayédèrú ₦98m àti $1.5m lọ sílé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Pointblank
Ile ẹjọ Majisireeti kan ni agbegbe Gwagwalada, nilu Abuja, ti pàṣẹ pe ki wọn o fi eeyan mẹjọ ti wọn fi ẹsun kan pe wọn tẹ ayederu owó Naira ti iye rẹ jẹ miliọnu mejidinlọgọrun.
Bakan naa ni wọn tun tẹ owó Dọla ti iye rẹ ku diẹ ko pe miliọnu kan aabọ Dọla.
Ileesẹ alaabo DSS lo gbe awọn eniyan naa, ọkùnrin meje ati obinrin kan, lọ sile ẹjọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwọn tó lu ₦6trn owó àjọ NDDC ní póńpó rugi oyin - Buhari fọnmú
- Kí ló dé tí Oluwo àti ìyàwó rẹ̀ àná ń sòkò ọ̀rọ̀ síra wọn lórí ayélujára?
- "Ojú mi rí màbo lásìkò tí mo lọ gbé N2.5m fáwọn jàndùkú tó jí ẹbí mi gbé"
- Wo ohun mẹ́rin tó lè mú ikú wá lásìkò ìbálòpọ̀
- Ẹ se mẹ̀dọ̀ ẹ̀yin olórí Fulani, ẹ yé tàbùkù àṣà Yorùbá nílẹ̀ wa mọ́ - YCE kìlọ̀
- "Tí Taliban bá rí mí, ikú ní yóò gbẹyìn mi, kò sí ìdáríjìn fún mi"
- Omi lórí pápá ìṣeré Lekan Salami kìí ṣe tuntun, ó lè ṣẹlẹ níbikíbi - Ìjọba Oyo
- Fíìmù India tó gbé agbára oṣó àti àjẹ́ ga ló mú kí ń gbaná jẹ fún Jésù láti ṣe sinimá - Mike Bamiloye
Ẹsun meji to ni i ṣe pẹlu yíyí ìwé ni wọn fi kan Musa Mayo, Bala Jatau, Ibrahim Dangana, Luka Daniel, Nnemeka Ude, Asebe Zainab, Sani Muhammed ati Abdulkarim Ahmed.
Agbẹjọro ajọ DSS to rojọ tako wọn nile ẹjọ, Victor Ejelonu sọ nile ẹjọ pe laarin oṣu Kinni si oṣu Keje, ọdun 2021, ni awọn eniyan naa, ati awọn akẹẹgbẹ wọn to ti salọ, gbimọpọ lati lu awọn araalu ni jibiti.
Ejelonu sọ pe wọn tẹ ayederu owo Naira ati Dọla, pẹlu erongba pe awọn yoo fi lu àwọn eeyan ni jibiti.
Ẹsun ti wọn fi kan wọn tako ofin iwa ọdaran, abala ofin 96 ati 368.
Simon Okoro to jẹ agbejọro fun olujejọ kinni, ikeji, ati ikarun, bẹ ile ẹjọ pe ko gba beeli awọn onibaara oun pẹlu ọwọ ẹ̀rọ̀.
Bakan naa ni awọn agbejọro àwọn afurasi mẹrin tó kù, Chinyere Muoneme ati M. D Ayodele, bẹbẹ fun gbigba beeli wọn.
Sugbọn sa, adajọ ile ẹjọ naa, Onidajọ Aliyu Shafa sọ fun awọn agbẹjọro naa lati kọwe beere fun beeli.
O ni fifi ọrọ ẹnu lasan gba beeli wọn ko ṣe itẹwọgba, nitori bi ẹsun ti wọn fi kan wọn ṣe l'agbara.
O si sun igbẹjọ si ọjọ kẹtala, oṣu Kẹsan-an

Ọkọ̀ agbépo tún gbiná ní òpópónà Ibadan sí Eko, ọkọ̀ mẹ́sàn jóná

Ọkọ nla to fi mọ awọn ọkọ ayọkẹlẹ mẹsan tun ti ba iṣẹlẹ ijamba ọkọ agbepo to gbina lọ ni opopona Ibadan si Eko.
Agbegbe Ogere ni ipinlẹ Ogun ni iṣẹlẹ naa ti waye, amọ ti ko si ẹmi enikankan to sọnu ninu iṣẹlẹ naa.
Adari ileeṣẹ to n risi ọrọ oju popo, FRSC, Ahmed Umar to ba BBC Pidgin sọrọ ni ọkọ agbepo to gbina naa waye ni oru mọju Ọjọbọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ohun mẹ́rin tó lè mú ikú wá lásìkò ìbálòpọ̀
- Kí ló dé tí Oluwo àti ìyàwó rẹ̀ àná ń sòkò ọ̀rọ̀ síra wọn lórí ayélujára?
- Ẹ se mẹ̀dọ̀ ẹ̀yin olórí Fulani, ẹ yé tàbùkù àṣà Yorùbá nílẹ̀ wa mọ́ - YCE kìlọ̀
- Omi lórí pápá ìṣeré Lekan Salami kìí ṣe tuntun, ó lè ṣẹlẹ níbikíbi - Ìjọba Oyo
- Agbébọn tún kó akẹ́kọ̀ọ́ 73 ní Zamfara, Ọlọ́pàá ń bẹ̀bẹ̀ àdúrà
- Fíìmù India tó gbé agbára oṣó àti àjẹ́ ga ló mú kí ń gbaná jẹ fún Jésù láti ṣe sinimá - Mike Bamiloye
- Ó dìgbà tí mo bá lọ, kí Nàìjíríà tó mọ iyì mi - Buhari
- Buhari ṣíjú àánú wo àádọrin Sọ́jà tó gbọjọ́ ikú, bo ṣe ń dárí jin àwọn Boko Haram tó ronú pìwàdà - Falana
- "Alhaji Fatai, ti DSS pa nílé Sunday Igboho ni kò ríran"
Umar ni iṣẹlẹ naa waye nigba ti ọkọ to wa lẹyin ọkọ agbepo naa kọlu ọkọ agbepo naa, ti ọkọ naa si kọlu awọn ọkọ miran, eleyii to mu ko gbina.
''Titi owurọ yii ni ina naa fi jo, to si ba ọkọ mesan jẹ, amọ meji jona raurau.''
''Gbogbo ọna mejeeji to wa loju popo ni ina naa gba patapata, amọ awọn panapana ti ri pe ina naa ti ku lọwọ.''

Oríṣun àwòrán, Others
''Ko si ẹni to ku ninu iṣẹlẹ naa, amọ awọn to farapa ti wa ni ileewosan.''
''Ere asapajude lo fa iṣẹlẹ to ba ọpọlọpọ dukia jẹ nitori ọkan lara awọn ọkọ to jo naa gbe gilaasi ti wọn n ta, amọ to jona raurau to fi mọ taya ọkọ naa.''
Adari ileeṣẹ to n risi ọrọ oju popo, FRSC, Ahmed Umar rọ awọn eniyan lati ma a rọra loju popo, ki wọn sọra fun ere asapajude eleyii to n fa ijamba ọkọ loju popo.
Agbegbe Ogere yii kan naa ni iru ijamba ọkọ agbepo yii ti waye to si mu ẹmi eniyan to le ni mẹta lọ, ti ọkọ to le ni mejila naa jona raurau ninu iṣẹlẹ ọhun.














