Taliban in Afghanistan: Ìrírí àwọn ènìyàn tó kù ní Afghanistan rè é, ó burú jáì

Awọn obinri Afghanistan n ki ara wọn ni papakọ orfurufu Vienna

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹgbẹgbẹrun awọn eniyan lorilẹede Afganistan ni wọn n kuro lọgọọrọ lati sa asala fun ẹmi wọn.

Fun ọpọlọpọ ọjọ ni wọn fi pejọ si papakọ ofurufu lọna ati sa kuro lorilẹede naa pẹlu bi awọn Taliban ṣe n pa awọn eniyan.

Awọ̣n oṣiṣẹ lati orilẹede Amẹrika pẹlu awọn oluranlọwọ wọn ti doola ẹmi eniyan ẹgbẹrun lọna mẹtalelọgọfa((123,000) ki gbedeke Oṣu Kẹjọ ti wọn fun wọn to pari.

Amọ awọn oṣiṣẹ ijọba, obinrin, oniroyin, to fi mọ awọn ẹlẹṣin kekeeke ni wọn ha si Afghanistan.

Ileeṣẹ iroyin BBC ba awọn eniyan mẹta sọrọ ti wọn ha si Afghanistan, ti wọn ko si le e lo orukọ abisọ wọn lati doola ẹmi wọn.

Taliban kan gbe ibọn dani

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Mi o le duro si Ile mọ! Iku lo n duro de mi- Nazeef

Lẹyin ti awọn alakatakiti Taliban gba Iṣakoso ilu Kabul, ni Afghanistan, ni Nazeef, iyawo rẹ ati ọmọ ọwọ rẹ ti n sa lati ibi kan si omiran.

"Ko si ibi ti mo le duro si fun gbogbo igba, lati ọdọ ẹbi kan si omiran "

Nazeef n ṣiṣẹ fun ijọba Afghanistan, eleyii to mu ni iṣoro pẹlu awọn Taliban.

Nazeef to jẹ ọmọwe nipa eto iṣiro owo ati ẹyawo lo ṣiṣẹ ni awọn igberiko ti Taliban n ṣakoso ibẹ, to si fi awọn aiṣedede wọn han.

Lati igba naa ni wọn ti mu ni ọta ti wọn si ti dunkoko mọ ni ọpọ igba.

Nazeef ni oun gbọ lati ọdọ awọn ara ile oun pe awọn alakatakiti Taliban ti yabo ile oun ti wọn ṣi n wa oun fun bi igba mẹrin laarin ọjọ meji.

Taliban kan gbe ibọn dani

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bakan naa lo fikun pe o kere tan ikọ Taliban ti pa oṣiṣẹ ijọba meje ni ibi iṣẹ oun lati igba ti wọn ti gba ijọba.

"Gbogbo igbiyanju lati salọ si papakọ ofurufu lo jasi pabo nitori ko ba ijọba orilẹede okeere ṣiṣẹ, ti ko tilẹ de ẹnu ọna nitori bi awọn eniyan ṣe pọ to ni papakọ.

Nazeef ni igiyanju oun bayii ni lati san owo fun awọn ọlọja okunkun, ti yoo ba oun ṣe iwe ayederu ti yoo mu oun gba ibode ilu lọ si orilẹede miran bii Pakistan.

Awọn Taliban ko le dariji mi lai, pipa ni wọn yoo pami ti ọwọ ba tẹ mi'" - Ahmed

Biotilẹ jepe Ahmed ko i tii gba lẹta iku lati ọdọ awọn Taliban, o ni o da oun loju pe iku ni ọrọ oun yoo jasi, ti ọwọ ba tẹ oun.

Idi ni pe awọn Taliban ti ṣekọlu si ileeṣẹ ijọba ti oun ti n ṣiṣẹ, ti wọn si ti mu awọn orukọ awọn oṣiṣẹ lọ, lọna ati wa wọn ri.

Ahmed to ni iwe igbelu Ilẹ Gẹẹsi lo gbiyanju lati sakuro ni Afghanistan, amọ papakọ lo wa nigba ti ibugbamu waye ni papakọ naa, to si mu ẹmi eniyan bii ọgọjọ lọ, pẹlu oku awọn eniyan to sun silẹ.

Nibẹ lo ti pada si Ile lẹyin ti awọn ẹbi rẹ doola ẹmi rẹ.

Nibayii, oun reti ki wọn ṣi papakọ ofurufu silẹ ni ilu naa,ki oun le sa kuro ni orilẹede Afghanistan, kii ọwọ awọn Taliban to ba oun.

Ọkọ mi ṣiṣẹ pẹlu ikọ ọmọogun ile okeere, ẹmi mi wa ninu ewu"

Mọlẹbi kan ni Afghanistan de si papakọ ofurufu Dulles nipinlẹ Virginia, lorilẹede Amẹrika

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Arabinrin Parvana ni lati igba ti awọn Taliban ti gbakoso ni oun ti n tiraka lati sakuro ni Afghanistan nitori inu ewu ni oun wa.

Parvana ni wọn le gba ẹmi oun nitori ọkọ oun ṣiṣẹ pẹlu ikọ ọmọogun Ilẹ Gẹẹsi, eleyii to fun ni anfaani amọ pẹlu ewu.

Ọkọ Parvana ti lọ si Ilẹ Gẹẹsi ni nkan bii ọdun melo sẹyin nitori iṣẹ rẹ.

o ku diẹ ki iyawo lo ba ọkọ rẹ, amọ o ku ki wọn gbe ontẹ lu iwe Irinna rẹ lọ si Ilẹ Gẹẹsi, ni awọn Taliban gbakoso Kabul to jẹ olu ilu Afghanistan.

Nibayii, ireti Parvana ti pin pẹlu bi awọn ọkọ baalu to n ṣe iranwọ lati gbe awọn eniyan ti kuro lorilẹede naa.

O kesi awọn orilẹede ni ilẹ okeere lati paṣẹ fun awọn ikọ Taliban lati gba awọn eniyan laaye ki wọn lọ si orilẹede to ba wu wọn.

Afghan Diaspora in Canada holding a protest

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Afghan Diaspora groups like the one in Canada are urging the global leaders not to trust the Taliban

Bakan naa ni Parvana parọwa si awọn orilẹede wọn yii lati maṣe gbagbẹ wọn nitori wọn nilo iranwọ.