Mike Bamiloye: Inú bí mi sí fíìmù ayé tí Ogunde, Baba Sala àti Ade-Love máa ń ṣe ni mo fi bẹ̀rẹ̀ sinimá ẹ̀mí

Mike Bamiloye

Oríṣun àwòrán, Mikebamiloye/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajúgbajà òṣèré sinimá nilana ẹsin Kristẹni, tii tun se olùdásílẹ̀ ẹgbẹ osere Mount Zion Ministry, Mike Bamiloye, tí ṣàlàyé lórí bí òun ṣe bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe sinimá àti àwọn ìpèníjà tí òun ti kojú nígbà náà.

Bamiloye, tii se ẹni ọdún mọ́kànlelọ́gọ́ta náà ló bọ́ sójú òpó instagram rẹ̀ láti ṣàlàyé bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò ìdásílẹ̀ ileesẹ iransẹ Mount Zion Ministry.

Ó ní ọmọ ọdún márùn-úndinlọ́gbọ́n ni òun, nígbà tí òun wo fíìmù India kan tí ó ń fi títóbi oṣó àti ajẹ́ hàn nínú sinimá náà, àti pé èyí ló bí òun nínú láti gbaná jẹ fún Ọlọ́run.

"Àkòrí fíìmù náà ni "WHEN THE POWER CHANGE Hands", mo wo sinima naa nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún márùn-úndinlọ́gbọ́n lọdún 1985, mò si ń gbóná fún Ọlọ́run pẹ̀lú ìran àgbàyanu láti sìn.

A ṣẹ̀ṣẹ̀ dá Mount Zion Ministry silẹ ni, a ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣe ètò ìpàdé àdúrà ni.

Àkọlé fídíò, Ẹ̀yin olórin ẹ̀mí tó ń bóra, lo èékáná gígùn, oò yàtọ̀ sí aṣẹ́wó hòtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ń gbé bíi súùtì Pepper Menti - Bola Are

Mo ní amóhùnmáwòràn aláwọ̀ dúdú àti funfun nígbà náà, tí mo gbé si ori àpótí nínú yàrá kan tí mo ń gbé.

Ní alẹ́ ọjọ́ kan, mo wo sinimá India kan tí ó sì ká mì lára láti ìbẹ̀rẹ̀ de òpin.

Láti ìbẹ̀rẹ̀ eré náà dé òpin ni mo fi ọkàn sí ṣùgbọ́n nígbà tí mo wòó tán, mo bú sẹ́kún, mo sá lọ sí àárín ọ̀dẹdẹ̀ ilé mi mo wa n kígbe lóhùn rara.

"Jésù! lo mi! Jésù! Mo fẹ́ ṣe sinimá fún ọ! Na ọwọ rẹ lé mi kì ó lò mi! Ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe sinimá fún ọ!"

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Bamiloye ni kò ye òun bí òun yóò ṣe wo sinimá tí kìí se tí ẹ̀mí, tí ìsọjí yóò sì bẹ́ sílẹ̀ nínú ayé oun.

Ó ní òun ti o wu òun jùlọ ni láti ṣe sinimá fún Ọlọ́run, ti èyí sì ń gbòòrò sì lojojumọ́

"Inú ń bí mi sí gbogbo àwọn sinimá ayé tí wọ́n ń ṣe nígbà yẹn, kò tíì sí Nollywood nígbà náà"

Ṣùgbọ́n àwọn sinimá Hubert Ogunde bí Aiye, Jayesinmi, Aropin-Nteniyan, Ayanmo.

Àti fíìmù Moses Olaiya (Baba Sala) bi: Mosebolatan, Orun Mooru, Diamond, àti àwọn fíìmù tí Ade Afolayan (ADE Love) ṣe bi Taxi Driver."

Àkọlé fídíò, Femi Branch: Gbogbo dúkìá mi àti ti ìyá mi ni mo tà láti tọ́jú ẹsẹ̀ mi fún ọdún méjì

Gbajúgbajà òṣèré tó ṣe sinimá Abejoye tun ṣàlàyé pé, ní àsìkò náà kò sí Nollywood ṣùgbọ́n iná Jésù ń jó gidi nínú òun.

O ni inu a máa bí òun sì àwọn sinimá tí wọn máa fi ń hàn ní ilé ìjọsìn lásìkò ìsọjí, tí ènìyàn kò ní gbọ́ nnkan ti àwọn oyinbo ń sọ, tí ẹni tó ṣe òngbifọ̀ náà yóò máa sọ ń kan tó bá bọ́ síi lẹ́nu

Ó ní èyí gan ni àwọn nǹkan tí ó má ń bí òun nínú, ti oun se fẹ́ sinimá tí Naijiria fún àwọn Kristẹni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Mo lọ sí ọgbà ilé ẹ̀kọ́ Fáṣítì Ife ni gbọ̀ngàn Odùduwà nígbà naa, lati lọ wo sinimá Hubert Ogunde tí àkọlé rẹ ń jẹ́ AIYE.

Lẹ́yìn tí sinimá náà tan ní bí aago mọ́kànlá alẹ́, mo jáde ní gbọ̀ngàn náà báyìí, ọkàn mi kún fún èrò láti ṣe nǹkan fún Jésù ni, inú mi bajẹ́ gidi."

Amọ lẹyin akoko naa ni Mike Bamiloye gbe ọpọ sinima ẹmi jade, ninu rẹ si ni sinima olokiki ‘Agbara Nla’, to se afihan bi agbara Jesu se ju agbara awọn mi okunkun lọ.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Timi Orokoya ní orin Iléyá tí òun kọ lọ́dún 28 sẹ́yìn, ló padà wá ṣẹ báyìí