Femi Branch: Gbogbo dúkìá mi àti ti ìyá mi ni mo tà láti tọ́jú ẹsẹ̀ mi fún ọdún méjì
Gbajumọ osere tiata ni Femi Branch, to si ti kopa ninu ere tiata to le ni ọgọrun.
Koda, onkọtan, adari ere ati osere tiata ni pẹlu, to si ti bẹrẹ isẹ ni ni ọgbọn ọdun o le diẹ sẹyin.
Nigab to n ba BBC Yoruba sọrọ, Femi Branch ni isẹ agbẹjọro ni baba oun fẹ ki oun lọ ka nile ẹkọ fasiti amọ dipo bẹẹ oun yan isẹ ere tiata laayo ni.
O fikun pe idi eyi ni baba oun se kẹyin si oun nitori ko nifẹ si bi oun se yan isẹ tiata laayo, ti awọn ko si ba ara awọn sọrọ fun ọdun meji ju bẹẹ lọ.
Nigba to n salaye awọn ipenija to n koju awọn elere tiata, Femi Branch ni o dabi ẹni pe inu awọn eeyan maa n dun ti nnkan ba bajẹ fun awọn osere tiata, bẹẹ ni ololufẹ awọn ni araalu jẹ.
- Yekeen Ajileye, ọ̀gá mi nínú iṣẹ́ tíátà ṣẹ̀ mí, ó ṣẹ ẹlẹ́dàá mi - Abija
- Mo kan sara sawọn ayasọlo- Dayo Amusa
- Bí mó bá fojú kan Baba Wande lórí ìtàgé, ṣe ní ẹ̀rù máa ń bà mí - Tafa Oloyede
- Àwọn òṣèré Nollywood tí wọn ò sí lóri amóhùmáwòrán mọ́
- Kí ló mú omijé jáde lójú Lateef Adedimeji?
- Iṣẹ́ ọpọlọ ló yẹ ká ṣe nínú tíátà, kìí ṣe àfihàn ara bíbó àbí ìhòòhò wa - Binta Mọgaji
- Mo rí òkú TB Joshua tó yọ sí mi lẹ́yìn ikú rẹ̀ - Jaiye Kuti
- Olu Jacobs: Ipò wo ni gbajúmọ̀ òṣèré tíátà yìí wà?
O salaye pe awọn osere tiata kii se ẹbọra, bi awọn araalu si se n ni ipenija ara ati ọrọ aje naa ni awọn onitiata naa n ni, paapaa lori ọrọ igbeyawo.
O tun fikun pe akoko kan tiẹ wa ti oun ni ijamba ni oko ere tiata lọdun 2011 ni alẹ.
O ni ibi ti oun ti n fo lati ori ile ni oun balẹ, ti ẹsẹ oun mejeeji si kan, ti egungun mẹsan si fọ lẹsẹkẹsẹ.
O ni odidi ọdun meji ni oun fi tọju ẹsẹ naa, ti oun si ta gbogbo dukia oun ati ti iya oun lati tsju ẹsẹ naa.
O salaye pe oun ko kan pariwo fun araye lati tọrọ owotabi bẹbẹ fun iranwọ owo lagbo tiata nitori awọn ko fi bẹẹ nifẹ ara awọn lagbo tiata.
O wa fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni iwa ibanilopọ maa n waye ninu isẹ tiata, o si yẹ ki ẹgbẹ naa maa ja fun wọn.





