Ààrẹ Muhammadu Buhari tí ṣe àtúntò àwọn mínísíta rẹ̀

Buhari

Oríṣun àwòrán, Femi Adesina

Ààrẹ Muhammadu Buhari tí buwọ́lu àtúntò àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ aláṣẹ ìjọba tó yàn sípò ni ọjọ́ kọkànlélógún, ọdún 2019.

Nínú àtẹ̀jáde kan sì àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ aláṣẹ nínú ìpàdé tó wáyé lọ́jọ́ru, ọjọ́ kini oṣù Kẹ̀sán, ni ààrẹ̀ tí kéde ayipada ọhun.

Atẹjade naa ni Mohammad Sabo Nanono to je mínísíta fún iṣẹ́ ọ̀gbìn àti ìdàgbàsókè ìgbèríko àti ónímọ̀ ẹ̀rọ Sale Mamman tó jẹ́ mínísíta ọ̀rọ̀ àmúșagbára, n kúrò nínú ọmọ ìgbìmọ̀ aláṣẹ ìjọba.

Bákan náà ni mínísíta fún ètò àyíká, Mohammed Mahmood Abubakar yóò lọ gba iṣẹ́ mínísíta ètò ọ̀gbìn àti ìdàgbàsókè àyíká.

Nígbà tí onímọ̀ ẹ̀rọ Abubakar Aliyu yóò bọ́ si ipò mínísíta iná àmúșagbára.

Àkọlé fídíò, Kola Tubosun: Ọ̀pọ̀ ọmọ òyìnbó ló ń kọ́ èdè Yorùbá, ẹ̀yin ọ̀dọ́ ẹ gbé èdè abínibí lárugẹ

Àtúntò ààrẹ yìí kò sẹ́yìn ìlànà ìjọba Muhammadu Buhari tó má ń ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn iṣẹ́ ìjọba nípa bí àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ ṣe má ń ṣe ìpàdé àti ìpàgọ́ láti fikulukù.

Ó fi kún pé ìpàdé yìí lọ jẹ̀ kí àwọn rí ibi tí ìdàgbàsókè de ba, ti àwọn ìhà tó kú díẹ̀ káàtó fún àti ọ̀nà láti mú ìdàgbàsókè bá ètò ọ̀rọ̀ ajé àti láti mú ojúlówó àṣeyọrí bá àwọn ọmọ Nàìjíríà.

Ó pari atgẹjade naa pé ní àìpé yìí ìjọba yóò yàn àwọn ènìyàn tuntun láti rọ́pò àwọn ayé tó ṣì sílẹ̀ ni ìlànà tí òfin fi lélẹ̀