Ondo Government: Gbogbo olùgbé ìpínlẹ̀ yìí gbọ́dọ̀ gbabẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 láàrín ọ̀sẹ̀ méjì

Abẹrẹ Ajẹsara Covid-19

Ijọba ipinlẹ Ondo ti sọ pe oun yoo fofin de ẹnikẹni to ba kọ lati gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 lati wọ awọn ileeṣẹ ijọba, ile itaja, ibi idokowo atawọn ile ijọsin lẹyin ọsẹ meji.

Kọmiṣọna fun ọrọ iroyin, Donald Ojogo lọ fi ọrọ naa lede.

O ni ijọba ipinlẹ naa ti pinnu lati ri daju pe gbogbo awọn eeyan ipinlẹ ọhun ni yoo gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kọmiṣona ọhun ni awọn gbe igbesẹ yii ki ajakalẹ arun naa le di ohun igbagbe nipinlẹ Ondo, paapaa ẹda rẹ tuntun ti wọn n pe ni Delta Variant.

Ojogo sọ pe "Yatọ si awọn alakalẹ to ti wa nilẹ tẹlẹ, gbogbo awọn olugbe ipinlẹ Ondo gbọdọ gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 laarin ọsẹ meji si asiko yii."

Àkọlé fídíò, Grace Oyin Adejobi: Bí mo bá tún ayé wá, ọkọ mi ni màá padà fẹ́

"Lẹyin ọsẹ meji naa, awọn eeyan naa ni lati fi ẹri han pe awọn ti gba abẹrẹ ajẹsara ọhun ki wọn to le lanfaani lati awọn ile ijọsin bii ṣọọṣi ati mọṣalaṣi to fi mọ awọn gbọngan mii ti ọpọ ero n korajọ si."

Kọmiṣọna naa fi kun pe, olori awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa ti gba aṣẹ lati daju pe awọn eeyan tẹle aṣẹ tuntun ọhun.

Ẹwẹ, aṣẹ tuntun ti ijọba ipinlẹ Ondo pa lori Covid-19 yii ko kan awọn ọmọde.

Bi ẹ ko ba gbagbe, lara awọn to ti ba Covid-19 lọ ni Naijiria ni kọmiṣọna fun eto ilera ipinlẹ naa ana, dọkita Wahab Adegbenro.

Adegbenro ku sile iwosan ijọba apapọ, FMC, niluu Owo, lọjọ keji, oṣu Keje, ọdun 2020.

Bẹẹ naa ni gomina ipinlẹ ọhun, Arakunrin Rotimi Akeredolu ti figba kan ba arun naa finra, ṣugbọn o moribọ.

Àkọlé fídíò, Ọlatunji, akẹ́kọ̀ọ́gboyè 'graduate' tó ń ta àkàrà 'Ó ta lẹ́nu' nílùú Osogbo