Ban on Open Grazing deadline: Miyetti Allah ní eré lásán làwọn gómìnà gúúsù ń ṣe lórí òfin máse da ẹran nígboro

Oríṣun àwòrán, other
Ọjọ kini oṣu kẹsan ọdun 2021 ni gbendeke ti awọn gomina guusu Naijiria gbe kalẹ lati fopin si dida ẹran jẹ ni gbangba, ti n ṣe kẹrẹkẹrẹ sunmọ etile bayii.
Amọṣa, awọn fulani darandaran lorilẹede Naijiria ti ṣalaye pe ala ti ko lee ṣẹ ni ọrọ naa, awọn gomina naa kan n pa ila sẹnu ni.
Awọn darandaran Fulani labẹ aṣia ẹgbẹ Miyetti Allah ni awọn ko ni lee tẹle ofin naa nitori ọrọ ti kọja lori rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ̀yin olùwọ́de Yoruba Nation, Arewa ń fẹ́ kẹ jáwọ́ àmọ́... - Àgbàgbà Yoruba
- Ajínigbé kọlu ìjọ David Oyedepo, wọ́n jí èèyàn mẹ́ta gbé lọ
- Àjàlú ńlá ń bọ̀ Buhari múra, màrìwò eégún lásán lo rí ní NDA - Fr Mbaka
- Sunday Igboho tún dá Malami mọ́lẹ̀ fún ìgbà kejì nílé ẹjọ́
- DSS tú mẹ́jọ sílẹ̀ nínú àwọn ọmọlẹyìn Igboho, mẹ́rin ṣì wà ní àhámọ́
- Alálẹ̀ ló fi èmi àti Sunday Igboho pamọ́ sí àhámọ́ kí ewu le ré wa kọjá - Oba Ogboni
Ninu ifọrọwerọ kan pẹlu iwe iroyin Leadership, akọwe apapọ ẹgbẹ Miyetti Allah Kauta Kore, Saleh Hassan ni awọn darandaran Fulani ko ni tẹle ofin naa.
O fi kun un pe igbesẹ titọpasẹ awọn ojuna idaran jẹko ti ijọba apapọ ṣẹṣẹ gbe kalẹ, ni awọn fara mọ.
Alhassan ni pẹlu aṣẹ irina bo se wu ni ti iwe ofin Naijiria gbe kalẹ, ko si ẹnikẹni to le le awọn lati mase daran jẹ nigboro, awọn ko lee tẹle aṣẹ awọn gomina naa.
Bakan naa lo fi kun un pe, ọgbọn ati da ipo aarẹ pada si ẹkun guusu Naijiria lawọn gomina naa n da ati pe ko lee bọ si.
"Agbara ti wọn n wa ko ni tẹ wọn lọwọ. A ti fi ẹjọ wọn sun Allah lati da ede aiyede silẹ laarin wọn. Nibo ni Sunday Igboho wa bayii? Nibo ni Nnamdi Kanu wa? Gbogbo wọn ti wa ni ẹwọn.
O ni gbogbo awọn to n foro ẹmi awọn darandaran bii Sunday Igboho, Nnamdi Kanu lo ti dero ẹwọn nitori Ọlọrun awọn ko sun.
Bakan naa lo fi kun un pe, gomina ipinlẹ Benue, Ortom pẹlu yoo foju wina idajọ to ba yẹ lẹyin to ba kuro ni ipo.
Ẹgbẹ Miyetti Allah ni bi ajọ EFCC ko ba gbe Ortom lẹyin to ba fi ipo silẹ, awọn funra awọn lawọn yoo ko ikọ fijilante awọn sita lati lọ mu u, ki wọn si faa le ọlọpaa lọwọ.
- Mo ní ẹ̀rí tó dájú pé àwọn Fulani fẹ́ gba gbogbo ilẹ̀ Nàìjíríà - Ortom
- Ilé Ife tako èrò Alaafin lórí ìfoyè dánilọ́lá nílẹ̀ Yorùbá
- Rotimi Ameachi sọ̀rọ̀ lórí bóyá lóòtọ́ ni àjọsọ wà láàrin Tinubu àti Buhari
- Ṣé lóòtọ́ ni tírélà ti gba ààrin Laide Bakare àti Kemi Afolabi nítorí ọkunrìn?
- "Ọkàn mi gbọgbẹ́ lórí aya, ọmọ àti ẹbí mi márùn ún tí agbébọn pa lọ́jọ́ kan"



















