Sunday Igboho aides: Omolẹ́yìn Igboho mẹ́jọ gbòmìnira ní àhámọ́ DSS, ó ku mẹ́rin

Oríṣun àwòrán, Omoyele Sowore
Ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti tu mẹjọ lara awọn ọmọlẹyin Sunday Igboho mejila to wa ni ahamọ wọn silẹ.
Agbẹjọro awọn eeyan naa, Pelumi Olajengbesi lo fìdí ọrọ yii mulẹ fawọn akọroyin.
Awọn eeyan yii ti lo ojo mọkanlelọgọta lahaamọ awọn DSS niluu Abuja ki wọn to gbominira.
- Sunday Igboho tún dá Malami mọ́lẹ̀ fún ìgbà kejì nílé ẹjọ́
- Okùnrin ẹni ọdún 33 fi ipá bá obìnrin ẹni ọdún 27 lòpọ̀ torí ó ní kò kí òun
- Alálẹ̀ ló fi èmi àti Sunday Igboho pamọ́ sí àhámọ́ kí ewu le ré wa kọjá - Oba Ogboni
- Mo ní ẹ̀rí tó dájú pé àwọn Fulani fẹ́ gba gbogbo ilẹ̀ Nàìjíríà - Ortom
- Ilé Ife tako èrò Alaafin lórí ìfoyè dánilọ́lá nílẹ̀ Yorùbá
- Rotimi Ameachi sọ̀rọ̀ lórí bóyá lóòtọ́ ni àjọsọ wà láàrin Tinubu àti Buhari
- Ṣé lóòtọ́ ni tírélà ti gba ààrin Laide Bakare àti Kemi Afolabi nítorí ọkunrìn?
Abdullateef Onaolapo, Tajudeen Irinloye, Diekola Ademola, Ayobami Donald, Uthman Adelabu, Olakunle Oluwapelumi, Raji Kazeem, ati aiwo Tajudeen lawọn eeyan naa.
Ṣugbọn DSS ko fi awọn mẹrin tó kù silẹ, bó tilẹ jẹ pé ile ẹjọ ti pàá laṣẹ pe kí DSS fi gbogbo won silẹ.
Awọn merin naa ni Amudat Babatunde, Abideen Shittu, Jamiu Oyetunji ati Bamidele Sunday.
Amọ, agbẹjọro Olajengbesi ni gbogbo wọn pata lo gbọdọ gba ominira lẹyin ti ile ẹjọ ti gba oniduro gbogbo won.
Bakan naa lo sọ fún DSS lati sọ tẹnu wọn lori awọn eeyan meji ti wọn pa nígbà tí wọn yabo ile Igboho niluu Ibadan.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kinni, oṣu Keje, ọdun 2021 yii ni awọn DSS yabo ile Igboho, nibi ti wọn pa eeyan meji, ti wọn si ba ọpọlọpọ dukia jẹ.
- Ìbẹ̀rù-bojo gbalẹ̀ nílùú Oyo nítorí lẹ́tà tí àwọn adigunjalè kọ sí bánkì kan
- Ọjà títà, ọ̀kadà gígùn àti epo títà dèèwọ̀ ní Zamfara torí ọṣẹ́ ajínigbé, agbébọn
- Amotekun mú afurasí ajínigbé mẹ́rin lọ́nà Iseyin sí Oyo
- Wo àṣírí márùn-ún tí obìnrin kò gbọdọ̀ sọ fún ọkọ rẹ̀
- Nàíjíríà ń wó lọ o, Obasanjo, Babangida, ẹ má wo Nàìjíríà níran - Ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ Arewa figbe ta














