Rape: Wo bí àwọn ọlọ́pàá ṣe yìnbọn pa afurasí ajínigbé nínú igbó l‘Ogun

Afurasi to ku ati eyi ti ọwọ tẹ

Oríṣun àwòrán, Ogun state Police Command

Wo bí àwọn ọlọ́pàá ṣe yìnbọn pa afurasí ajínigbé nínú igbó Abeokuta

Ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti ṣàlàyé bi o ṣe yinbọn pa afurasi ajinigbe kan, ti o sí tún fọwọ ofin mu omiran ninu Igbo Ilala lagbegbe Imala nipinlẹ Ogun.

Alukoro ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abímbóla Oyeyemi ṣàlàyé pé, isẹlẹ naa waye lẹyìn ọjọ kan tàwọn ọlọpaa tun yinbọn pa awọn janduku ajinigbe meji mii ni Itori ni ijọba ibilẹ Ewekoro nipinlẹ Ogun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

DSP Oyeyemi ṣàlàyé pe awọn ọlọpaa mori le inú igbo Imala lẹyin ti ile iṣẹ ọlọpaa to wa lagbegbe naa ni awọn ri ajinigbe mẹfa pẹlu ibọn lọwọ wọn ninu igbo.

"Lẹyin naa ni CSP Bernard Ediagbonya ko àwọn ọlọpaa, fijilante, awọn ọlọdẹ at'awọn ọdọ Fulani, ti wọn sì mori le igbo naa.

Lati okeere tàwọn ajinigbe ti ri awọn ọlọpaa ni wọn ti bẹrẹ sí ní yinbọn, ti awọn ọlọpaa sí bẹrẹ si ni dáa pada.

Nigba ti ọta ibọn n ro yìí gan an ni ọkan lára àwọn ajinigbe ọhún gbẹmi mi.

Bakan naa ni ọwọ tẹ ọkàn lára wọn ti o pe orúkọ ará rẹ ni Usman Maidama.

Awọn mẹrin to ku sa wọ inu igbo lọ pẹlu ọgbẹ ọta ibọn lára wọn.

Awọn nkan ti ọlọpaa gba lọwọ awọn janduku ọhún ni ibọn kan, iboju ati bàtà meji," Oyeyemi ṣàlàyé.

DSP Oyeyemi ni kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Edward Ajogun ti paṣẹ pe kí àwọn ọlọpaa wa awọn janduku ajinigbe to sa lọ ri ni kiakia.

Amin iyasọtọ kan

Okùnrin ẹni ọdún 33 fi ipá bá obìnrin ẹni ọdún 27 lòpọ̀ torí ó ní kò kí òun

Imoleaye Adekoya

Oríṣun àwòrán, Bimbola oyeyemi

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ogun ti fi ṣikun ofin mu okunrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn kan, Imoleaye Adekoya, lori ẹsun pe o fiipa ba obinrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan lopọ.

Iroyin ni Adekoya fi ipa wọ obinrin naa lọ kọrọ ẹyin kan lẹyin to ti kọkọ sọ pe ko ki oun, to si fi ipa ba lopọ.

Agbenusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, ASP Abimbola Oyeyemi lo fi ọrọ naa lede fun awọn akọroyin ninu atẹjade kan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oyeyemi ni awọn fi panpẹ ofin mu afurasi naa lẹyin ti obinrin naa fi ẹjọ rẹ sun ni agọ awọn to wa ni Sakora, niluu Sagamu.

Agbenusọ ọlọpaa naa ṣalaye pe obinrin ọhun sọ pe Adekoya da oun lọna lagbegbe Ipoji, ni Sagamu, to si fi ẹsun kan oun pe oun ko ki i.

Atẹjade naa tẹsiwaju pe "O bẹ Adekoya pe ko ma binu pe oun ko mọ ni ko jẹ ki oun ki."

Àkọlé fídíò, Oba Ogboni: Bí ìwọ́de Yoruba Nation bá tún wáyé, màá bá wọn kópa níbẹ̀

"Ṣugbọn ni ṣe ni Adekoya ki obinrin naa mọlẹ to si bẹrẹ si n lu nilu bara ko to wọ lọ si ẹyin ile rẹ nibi to ti fi ipa bọ aṣọ rẹ to si ba ni ajọṣepọ."

Oyeyemi sọ pe ni kete ti awọn gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni awọn oṣiṣẹ awọn tẹkọ leti lọ si ibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye pẹlu baba obinrin ọhun, ti wọn si fi panpẹ ofin mu afurasi naa.

Gẹgẹ bii ohun ti atẹjade naa sọ, afurasi naa ti jẹwọ ni agọ ọlọpaa pe lootọ ni oun fi ipa ba obinri ọhun lopọ ṣugbọn ki wọn fori jin oun nitori oun mu ọti yo lọjọ naa ni.

Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Edward Ajagun ti paṣẹ pe ki wọn bẹrẹ iwadii ni kankan ki afurasi naa le foju bale ẹjọ laipẹ.