Dangote fárígá, Ó ní kí ọ̀gá àjọ alámójútó epo rọ̀bì wá sọ bó ṣe rí $5 mílíọ̀nù tó fi rán ọmọ mẹ́rin lọ kàwé lókè òkun

Oríṣun àwòrán, Getty/Ahmed Farouk
Ọrọ to ba dani loju ki i kọsẹ lete ni Aliko Dangote,
Baba olowo ilẹ Naijiria ati gbogbo Africa, fi ọrọ ṣe lanaa ọjọ Aiku, nigba to n fẹsun ajẹbanu ati kiko owo ẹka epo rọbi Naijiria si apo ara rẹ, kan Farouk Ahmed, ọga ajọ to n ṣamojuto kata-kara epo rọbi ni Naijiria, Nigerian Midstream and Downstream Petroleum Regulatory Authority, (NMDPRA).
Ni ileeṣẹ ifọpo nla rẹ to wa ni Lekki, niluu Eko, ni Dangote ti fi ẹsun ajẹbanu ati gbigbabọde fun ẹka epo rọbi Naijiria kan Farouk Ahmed.
O ni ọrọ aje Naijiria n bajẹ, araalu n daamu lori epo rọbi, ijọba n fowo nla ra epo ti a ni wọ Naijiria, ẹni kan si n gba ibi epo naa gbabọde fun araalu, o n fi owo ilu gbọ bukaata ara rẹ nikan .
Olori ileeṣẹ Dangote sọ pe owo to to miliọnu marun-un dọla ($5m) ni Ahmed n san fun ileewe girama ti awọn ọmọ rẹ mẹrin n lọ ni Switzerland, o ni eyi to ki awọn oluwadii wadii ọga ileeṣẹ to n ri si ọrọ epo naa wo.
O fi kun un pe afi ki Ahmed foju kan kootu to n ri si ihuwasi ni Naijria, ko si ṣalaye fun gbogbo ọmọ Naijiria, ibi to ti n ri $5m owo ile ẹkọ naa san, bi ko ba jẹ pe owo ilu lo n na.
Ẹ o ranti pe ṣaaju ni NMDPRA ti ni ahesọ ati ibajẹ lasan ni awọn to n fẹsun kan Ahmed n ba ka.
Oṣu Kejẹ ọdun yii ni ẹsun naa kọkọ jade, pe Ahmed n na ju $5.5m lori ile ẹkọ ile okeere ti awọn ọmọ rẹ n lọ.
"Ai si aṣẹ ati abojuto gidi lo n fa eyi, ẹ ni ko waa ṣalaye ara rẹ, to ba si ni irọ ni mo n pa, ma a gbe igbesẹ ti yoo fi owo to n san naa han fun gbogbo eeyan"
Nigba to n fidi rẹ mulẹ pe Ahmed Farouk n na owo ẹka epo rọbi lorilẹede yii ni inakunaa, Dangote sọ pe ai si abojuto to peye lati ẹka to yẹ, ni ko jẹ ki wọn mọ pe ọkunrin naa n da kun iṣoro ọrọ aje Naijiria.
O ni bi awọn to yẹ ko mojuto iwadii yii ba fi i silẹ lai da si, awọn to ba fẹ dokowo pẹlu Naijiria ko ni i ni igbagbọ kan ninu orilẹede yii.
"Ti ẹ ba wo iye to n wọle fun un, ko to iye to fi n sanwo ileẹkọ yii. Koda ko jẹ emi ni mo n san $5m fun ọdun mẹfa lori ọmọ mẹrin, ajọ olowo ori gbọdọ wo owo ori mi ati iye ti mo n san.
"Ẹka to n ri si iwuwasi tabi ajọ miran to ba tun n ṣewadii fun ijọba apapọ gbọdọ wadii ọrọ yii.
"To ba ni irọ ni, mo maa gbe owo ile ẹkọ to n san naa jade, ma a tun gbe igbesẹ ofin lati jẹ ki awọn ile ẹkọ yen sọ iye ti Farouk n san."
Bẹẹ ni Dangote wi.
O ni oun ko ni ki wọn yọ Farouk Ahmed nipo rẹ, ṣugbọn ki wọn wadii rẹ ni kikun, ki wọn le ri i pe Alufa n sanra, ijọ n ru ni ọrọ ọga ajọ NMDPRA naa.
"Ni ipinlẹ Sokoto to ti wa, awọn eeyan n daamu lati san N100,000 owo ile iwe ọmọ wọn.
" Ọpọ ọmọ lo wa nile ti wọn ko le lọ sile iwe nitori ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan naira. Emi o mọ ibi ti ẹni to jẹ pe oṣiṣẹ ijọba ni lati ibẹrẹ aye rẹ yoo ti maa ri $5m fun ẹkọ ọmọ rẹ o."
Bẹẹ ni Aliko Dangote ṣe afikun alaye rẹ.
Dangote ni awọn ọmọ toun gan-an ko lọ sile ẹkọ girama nilẹ okeere, Naijriia yii ni wọn ti kawe.
Ki ni Dangote ri gan-an?
Tẹ o ba gbagbe, ikunsinu wa laaarin awọn NMDPRA ati ileeṣẹ Dangote, lori bi ajọ naa ṣe n sọ pe ileeṣẹ ifọpo Dangote nikan ko le da gbọ gbogbo epo ti Naijiria nilo ati eyi ti yoo ta si oke okun.
Ṣugbọn Dangote n koju wọn, o ni ajọ yii ni ko jẹ ki Naijiria le da duro lẹka ifọpo funra rẹ, ti orilẹede yii ṣe n fi epo aifọ ranṣẹ silẹ okeere, to n fowo ribiribi ra eyi ti wọn ti fọ wale, to si n ṣakoba fun ọrọ aje wa.
Dangote sọ pe niṣe lo yẹ ki Naijiria maa kọ ibudo ifọpo ibilẹ funra rẹ, eyi ti yoo jẹ ki awọn ti ilẹ okeere wa laaye wọn, ti yoo si jẹ ki owo Naijiria gbe ilẹ yii, ti awọn ilẹ ibomi-in paapaa yoo maa wa sibi ra epo.
Dangote tẹnu mọ ọn, pe niṣe lo yẹ ki awọn to n ri si bo ṣe n lọ lẹka epo wa lọtọ, kawọn ti yoo mojuto owo ti won n pa nibẹ si wa lọtọ.
O kilọ pe to ba ti jẹ awon oniṣowo epo naa lo n ṣofin ibẹ, ko si bi ko ṣe ni i ko ba iwa ọmọluabi, nitori owo ti wọn yoo maa ri ni yoo gba ọmọluabi mọ wọn lọwọ.
"Ko yẹ ki imọtare ẹni nikan ba ẹka yii jẹ. Oniṣowo ibẹ naa kọ lo tun yẹ ko jẹ adari ibẹ.
"Wọn fi anfaani iwe aṣẹ mẹtadinlaadọta (47 licences) silẹ fawọn ti yoo lo o, sibẹ, ko si ibudo ifọpo kan ti wọn kọ, nitori ohun to n ṣẹlẹ lẹka yẹn."
Aliko Dangote lo sọ bẹẹ.
Ẹwẹ, titi ti a fi pari akojọpọ iroyin yii, NMDPRA ko fesi si ẹsun ti Dangote fi kan ọga ibẹ, Ahmed Farouk.
BBC kan si agbẹnusọ rẹ, George Ene-Ita, ṣugbọn ko fesi.














