Olubadan fòfin de jíjẹ oyè Jagun Olubadan fún ìgbà kan ná, ìdí rèé

Ọba Rashidi Ladoja wọ aṣọ funfun, wọ ilẹ̀kẹ̀ sọ́rùn, ó rẹ́rìn-ín músẹ́

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Olubadan ti ilẹ̀ Ibadan, Ọba Rashidi Ladoja ti fòfin de mímú àgbéga bá oyè Mogaji di Jagun Olubadan fún ìgbà kan ná.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọba náà kò sọ ìdí kan pàtó lórí ìgbésẹ̀ náà, àwọn èèyàn kan ní ààfin gbàgbọ́ pé ìgbésẹ̀ ọ̀hún le jẹ́ ojúnà láti ṣàfọ̀mọ́ oyè jíjẹ ìlú náà kúrò ní irú wá, ògìrì wá.

Ipò Jagun Olubadan jẹ́ àkàsọ̀ kìíní nínú àkàsọ̀ méjìlélógún tàbí mẹ́tàlélógún tí ẹni tó bá máa ipò Olubadan yálà láti igun ẹgbẹ́ àgbà tàbí ti balógun máa kọ́kọ́ gùn lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fi rólé gẹ́gẹ́ bí mọ́gàjí ilé wọn.

Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó bá sì ti wà ní ipò Mogaji ni wọ́n máa ń sa gbogbo ipá wọn láti ri pé wọ́n tètè gun àkàsọ̀ yìí.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ Olubadan, Adeola Oloko fi léde sọ pé Olubadan náà ti buwọ́lu sísún ẹ̀gbọ́n Gómìnà Seyi Makinde, Muyiwa Makinde sípò Gbonka Olubadan láti ipò Aare Onibon.

Ó sọ pé àwọn olóyè mẹ́sàn-án ní igún ẹgbẹ́ àgbà ni wọ́n rí ìgbéga láti ipò Jagun títí dé ipò Ayingun ní ààfin Olubadant ó wà ní Oke- Aremo.

Àwọn míì tó rí ìgbéga ni Dotun Sanusi tó bọ́ sípò Bada Olubadan lati ipò Ajia, tí Akinola Alabi sì bọ́ sípò Ajia Olubadan láti ipò Jagun.

Pẹ̀lú ìgbéga yìí, ipò Jagun Olubadan ní igun ẹgbẹ́ àgbà ló ṣòfo báyìí ṣùgbọ́n tí Olubadan sì ti ṣe ìdádúró yínyan ẹnikẹ́ni sípò náà fún ìgbà kan ná.

Àwọn míì tó tún rí ìgbéga ní igun ẹgbẹ́ àgbà ni:

  • Dauda Kolawole Gbadamosi láti Aare Ago sí Ayingun Olubadan
  • William Oyeleke Akande láti Lagunna sí Aare Ago Olubadan
  • Oluyinka Akande láti Oota sí Lagunna Olubadan
  • Olufemi Taofeek Ogunwale láti Aare-egbe Omo sí Oota Olubadan
  • Wasiu Aderoju Alaadorin láti Gbonka sí Aare-egbe Omo Olubadan
  • Abiola Iyiola Anlamole láti Bada sí Aare Onibon Olubadan.